5 Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; ibi kan, ibi kanṣoṣo, kiye si i, o de.
6 Opin de, opin de: o jí si ọ; kiye si i, o de.
7 Ilẹ mọ́ ọ, iwọ ẹniti ngbe ilẹ na: akokò na de, ọjọ wahala sunmọ tosí; kì isi ṣe ariwo awọn oke-nla.
8 Nisisiyi li emi o dà ikannu mi si ọ lori, emi o si mu ibinu mi ṣẹ si ọ lori: emi o si dá ọ lẹjọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, emi o si san fun ọ nitori gbogbo irira rẹ.
9 Oju mi kì yio si dasi, bẹ̃li emi kì yio ṣãnu: emi o si san fun ọ gẹgẹ bi ọ̀na rẹ, ati irira rẹ ti mbẹ lãrin rẹ; ẹnyin o si mọ̀ pe emi li Oluwa ti nkọlu.
10 Kiye si i ọjọ na, kiyesi i, o de: ilẹ ti mọ́; ọpá ti tanná, irera ti rudi.
11 Iwa-ipa ti dide di ọpa ìwa buburu: ọkan ninu wọn kì yio kù, tabi ninu ọ̀pọlọpọ wọn, tabi ninu ohun kan wọn, bẹ̃ni kì yio si ipohùnreré ẹkun fun wọn.