1 O si ṣe, li ọdun ẹkẹfa, li oṣù ẹkẹfa, li ọjọ karun oṣù, bi mo ti joko ni ile mi, ti awọn àgbagba Juda si joko niwaju mi, ni ọwọ́ Oluwa Ọlọrun bà le mi nibẹ.
2 Nigbana ni mo wò, si kiye si i, aworán bi irí iná: lati irí ẹgbẹ rẹ̀ ani de isalẹ, iná; ati lati ẹgbẹ́ rẹ de oke, bi irí didan bi àwọ amberi.
3 O si nà àworan ọwọ́ jade, o si mu mi ni ìdi-irun ori mi; ẹmi si gbe mi soke lagbedemeji aiye on ọrun, o si mu mi wá ni iran Ọlọrun si Jerusalemu, si ilẹkun ẹnu-ọ̀na ti inu to kọju si ariwa; nibiti ijoko ere owu wà ti nmu ni jowu.
4 Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wà nibẹ, gẹgẹ bi iran ti mo ri ni pẹtẹlẹ.
5 Nigbana li o wi fun mi pe, Ọmọ enia, gbe oju rẹ soke nisisiyi si ọ̀na ihà ariwa. Bẹ̃ni mo gbe oju mi soke si ọ̀na ihà ariwa, si kiye si i, ere owu yi niha ariwa li ati-wọle ọ̀na pẹpẹ.
6 Pẹlupẹlu o wi fun mi pe, Ọmọ enia, iwọ ri ohun ti nwọn nṣe? ani irira nla ti ile Israeli nṣe nihinyi, ki emi ba le lọ jina kuro ni ibi mimọ́ mi? ṣugbọn si tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o jù wọnyi lọ.
7 O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na agbala; nigbati mo si wò, kiye si i iho lara ogiri.