4 Si kiyesi i, ogo Ọlọrun Israeli wà nibẹ, gẹgẹ bi iran ti mo ri ni pẹtẹlẹ.
5 Nigbana li o wi fun mi pe, Ọmọ enia, gbe oju rẹ soke nisisiyi si ọ̀na ihà ariwa. Bẹ̃ni mo gbe oju mi soke si ọ̀na ihà ariwa, si kiye si i, ere owu yi niha ariwa li ati-wọle ọ̀na pẹpẹ.
6 Pẹlupẹlu o wi fun mi pe, Ọmọ enia, iwọ ri ohun ti nwọn nṣe? ani irira nla ti ile Israeli nṣe nihinyi, ki emi ba le lọ jina kuro ni ibi mimọ́ mi? ṣugbọn si tun yipada, iwọ o si ri ohun irira ti o jù wọnyi lọ.
7 O si mu mi wá si ẹnu-ọ̀na agbala; nigbati mo si wò, kiye si i iho lara ogiri.
8 Nigbana li o wi fun mi pe, Ọmọ enia, dá ogirí na lu nisisiyi: nigbati mo si ti dá ogiri na lu tan, kiye si i, ilẹkun.
9 O si wi fun mi pe, Wọ ile, ki o si wo ohun irira buburu ti nwọn nṣe nihin.
10 Bẹ̃ni mo wọle, mo si ri; si kiye si i, gbogbo aworan ohun ti nrakò, ati ẹranko irira, ati gbogbo oriṣa ile Israeli li a yá li aworan lara ogiri yika kiri.