5 O si sọ fun awọn iyokù li eti mi, pe, Ẹ tẹ̀ le e la ilu lọ, ẹ si ma kọlù: ẹ má jẹ ki oju nyin dasi, bẹ̃ni ẹ máṣe ṣãnu.
6 Ẹ pa arugbo ati ọmọde patapata, awọn wundia ati ọmọ kekeke ati obinrin; ṣugbọn ẹ máṣe sunmọ ẹnikan lara ẹniti àmi na wà; ẹ si bẹrẹ lati ibi mimọ́ mi. Bẹ̃ni nwọn bẹrẹ lati ọdọ awọn agbà ti o wà niwaju ile.
7 O si wi fun wọn pe, ẹ sọ ile na di aimọ́, ẹ si fi okú kún agbala na: ẹ jade lọ. Nwọn si jade lọ, nwọn si pa enia ni ilu.
8 O si ṣe, nigbati nwọn npa wọn, ti a si fi emi silẹ, mo da oju mi bo ilẹ, mo si kigbe, mo si wipe, Oluwa Ọlọrun, iwọ o ha pa gbogbo awọn iyokù Israeli run, nipa dida irúnu rẹ jade sori Jerusalemu?
9 O si wi fun mi pe, Aiṣedede ile Israeli ati ti Juda pọ̀ gidigidi, ilẹ na si kún fun ẹjẹ, ilu si kún fun iyi-ẹjọ-po, nitori nwọn wipe, Oluwa ti kọ aiye silẹ, Oluwa kò riran.
10 Bi o si ṣe ti emi ni, oju mi kì o dasi, bẹ̃li emi kì o ṣanu, ṣugbọn emi o sán ọ̀na wọn pada si ori wọn.
11 Si kiye si i, ọkunrin ti o wọ aṣọ ọ̀gbọ, ti o ni ìwo-tadawa li ẹgbẹ́ rẹ̀ rohìn, wipe, mo ti ṣe gẹgẹ bi o ti paṣẹ fun mi.