1 Ọ̀RỌ Jeremiah, ọmọ Hilkiah, ọkan ninu awọn alufa ti o wà ni Anatoti, ni ilẹ Benjamini.
2 Ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá ni igba ọjọ Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, li ọdun kẹtala ijọba rẹ̀.
3 O si tọ̀ ọ wá pẹlu ni igba ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, titi de opin ọdun kọkanla Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, ani de igba ti a kó Jerusalemu lọ ni igbekun li oṣu karun.
4 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe:
5 Ki emi ki o to dá ọ ni inu, emi ti mọ̀ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jade wá li emi ti sọ ọ di mimọ́, emi si yà ọ sọtọ lati jẹ́ woli fun awọn orilẹ-ède.