Jer 24 YCE

Apẹ̀rẹ̀ Èso Ọ̀pọ̀tọ́ Meji

1 SI wò o, Oluwa fi agbọn eso-ọ̀pọtọ meji hàn mi, ti a gbe kalẹ niwaju ile Oluwa, lẹhin igbati Nebukadnessari, ọba Babeli, ti mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni ìgbekun pẹlu awọn olori Juda, pẹlu awọn gbẹna-gbẹna, ati awọn alagbẹdẹ, lati Jerusalemu, ti o si mu wọn wá si Babeli.

2 Agbọn ikini ni eso-ọ̀pọtọ daradara jù, gẹgẹ bi eso ọ̀pọtọ ti o tetekọ pọ́n: agbọn ekeji ni eso-ọ̀pọtọ ti o buruju, ti a kò le jẹ, bi nwọn ti buru tó.

3 Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, Kini iwọ ri, Jeremiah? Emi wipe, Eso-ọ̀pọtọ, eyi ti o dara, dara jù, ati eyi ti o buru, buru jù, tobẹ̃ ti a kò le jẹ ẹ, nitori nwọn buru jù.

4 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,

5 Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ daradara wọnyi, bẹ̃li emi o fi oju rere wò awọn ìgbekun Juda, ti emi ran jade kuro ni ibi yi lọ si ilẹ awọn ara Kaldea.

6 Emi o si kọju mi si wọn fun rere, emi o si mu wọn pada wá si ilẹ yi, emi o gbe wọn ró li aitun wó wọn lulẹ, emi o gbìn wọn, li aitun fà wọn tu.

7 Emi o si fun wọn li ọkàn lati mọ̀ mi, pe, Emi li Oluwa, nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn, nitoripe nwọn o fi gbogbo ọkàn wọn yipada si mi.

8 Ati gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ biburujù ti a kò le jẹ, nitoriti nwọn burujù, bayi li Oluwa wi, Bẹ̃ gẹgẹ ni emi o ṣe Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀, ati awọn ti o kù ni Jerusalemu, ati awọn iyokù ni ilẹ yi ati awọn ti ngbe ilẹ Egipti.

9 Emi o fi wọn fun iwọsi ati fun ibi ninu gbogbo ijọba aiye, lati di ìtiju, owe, ẹsin, ati ẹ̀gan ni ibi gbogbo, ti emi o le wọn si.

10 Emi o si rán idà, ìyan, ati ajakalẹ-arun, si ãrin wọn, titi nwọn o fi parun kuro ni ilẹ eyi ti emi fi fun wọn ati fun awọn baba wọn.