1 NIGBANA ni gbogbo awọn olori ogun, ati Johanani, ọmọ Karea, ati Jesaniah, ọmọ Hoṣaiah, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere de ẹni-nla, nwọn wá,
2 Nwọn si sọ fun Jeremiah woli, pe, Awa bẹ ọ, jẹ ki ẹ̀bẹ wa ki o wá siwaju rẹ, ki o si gbadura fun wa si Oluwa Ọlọrun rẹ, ani fun gbogbo iyokù yi; (nitori lati inu ọ̀pọlọpọ, diẹ li awa kù, gẹgẹ bi oju rẹ ti ri wa:)
3 Ki Oluwa Ọlọrun rẹ le fi ọ̀na hàn wa ninu eyi ti awa iba rìn, ati ohun ti awa iba ṣe.
4 Jeremiah, woli, si wi fun wọn pe, emi gbọ́; wò o, emi o gbadura si Oluwa Ọlọrun nyin gẹgẹ bi ọ̀rọ nyin; yio si ṣe, pe ohunkohun ti Oluwa yio fi da nyin lohùn emi o sọ ọ fun nyin; emi kì o ṣẹ nkankan kù fun nyin.
5 Nwọn si wi fun Jeremiah pe, ki Oluwa ki o ṣe ẹlẹri otitọ ati ododo lãrin wa, bi awa kò ba ṣe gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa, Ọlọrun rẹ, yio rán ọ si wa.
6 Iba ṣe rere, iba ṣe ibi, awa o gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́, sọdọ ẹniti awa rán ọ: ki o le dara fun wa, bi awa ba gbà ohùn Oluwa Ọlọrun wa gbọ́.
7 O si ṣe lẹhin ọjọ mẹwa li ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá.
8 Nigbana ni o pè Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn enia lati ẹni-kekere titi de ẹni-nla.
9 O si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, sọdọ ẹniti ẹnyin rán mi, lati mu ẹ̀bẹ nyin wá siwaju rẹ̀;
10 Bi ẹnyin o ba gbe ilẹ yi lõtọ, nigbana ni emi o gbe nyin ro emi kì yio si fà nyin lulẹ, emi o si gbìn nyin, emi kì yio si fà nyin tu: nitori emi yi ọkàn pada niti ibi ti emi ti ṣe si nyin.
11 Ẹ má bẹ̀ru ọba Babeli, ẹniti ẹnyin mbẹ̀ru: ẹ máṣe bẹ̀ru rẹ̀, li Oluwa wi: nitori emi wà pẹlu nyin lati ràn nyin lọwọ, ati lati gbà nyin li ọwọ rẹ̀.
12 Emi o si fi ãnu hàn fun nyin, ki on ki o le ṣãnu fun nyin, ki o si mu ki ẹnyin pada si ilẹ nyin.
13 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wipe, Awa kì yio gbe ilẹ yi, ti ẹnyin kò si gbà ohùn Oluwa Ọlọrun nyin gbọ́.
14 Wipe, bẹ̃kọ̀; ṣugbọn awa fẹ lọ si ilẹ Egipti, nibiti awa kì yio ri ogun-kogun, ti a kì o si gbọ́ iró fère, ti ebi onjẹ kò ni ipa wa, nibẹ li awa o si mã gbe:
15 Njẹ nisisiyi, nitorina, ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin iyokù Juda, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe, Bi ẹ ba gbe oju nyin patapata le ati lọ si Egipti, bi ẹnyin ba lọ lati ṣe atipo nibẹ,
16 Yio si ṣe, idà ti ẹnyin bẹ̀ru, yio si le nyin ba ni ilẹ Egipti; ati ìyan, ti ẹnyin bẹ̀ru, yio tẹle nyin girigiri nibẹ ni Egipti; nibẹ li ẹnyin o si kú.
17 Bẹ̃ni gbogbo awọn ọkunrin ti nwọn gbe oju wọn si ati lọ si Egipti lati ṣatipo nibẹ; nwọn o kú, nipa idà, nipa ìyan, tabi nipa àjakalẹ-arun, ẹnikẹni ninu wọn kì yio kù, tabi kì o sala kuro ninu ibi ti emi o mu wá sori wọn.
18 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Gẹgẹ bi emi ti dà ibinu mi ati irunu mi sori awọn olugbe Jerusalemu; bẹ̃ni emi o dà irunu mi le nyin lori, ẹnyin ti yio lọ si Egipti: ẹnyin o si di ẹni-ègun, ati ẹni-iyanu, ati ẹ̀gan, ati ẹ̀sin; ẹnyin kì yio si tun ri ibi yi mọ.
19 Oluwa ti sọ niti nyin, ẹnyin iyokù Juda, ẹ má lọ si Egipti: ẹ mọ̀ dajudaju pe emi ti jẹri si nyin li oni yi.
20 Nitori ọkàn nyin li ẹnyin tanjẹ, nigbati ẹnyin rán mi si Oluwa, Ọlọrun nyin, wipe, Gbadura fun wa si Oluwa, Ọlọrun wa: ati gẹgẹ bi gbogbo eyi ti Oluwa Ọlọrun wa yio wi, bẹ̃ni ki o sọ fun wa, awa o si ṣe e.
21 Emi si ti sọ fun nyin loni; ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn Oluwa, Ọlọrun nyin, ati gbogbo eyi ti on ti ran mi si nyin.
22 Njẹ nitorina, ẹ mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin o kú nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-arun, ni ibẹ na nibiti ẹnyin fẹ lati lọ iṣe atipo.