Jer 41 YCE

1 O si ṣe li oṣu keje Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ọmọ Eliṣama, ninu iru-ọmọ ọba, ati awọn ijoye ọba, ati ọkunrin mẹwa pẹlu rẹ̀, nwọn tọ̀ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, wá ni Mispa: nibẹ ni nwọn jumọ jẹun ni Mispa.

2 Nigbana ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, ati awọn ọkunrin mẹwa ti nwọn wà pẹlu rẹ̀, nwọn fi idà kọlu Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ọmọ Ṣafani, nwọn si pa a, on ẹniti ọba Babeli ti fi jẹ bãlẹ lori ilẹ na.

3 Pẹlupẹlu Iṣmaeli pa gbogbo awọn ara Juda ti o wà pẹlu rẹ̀, ani pẹlu Gedaliah, ni Mispa, ati awọn ara Kaldea, ti a ri nibẹ, awọn ologun.

4 O si ṣe li ọjọ keji lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ti ẹnikan kò si mọ̀.

5 Nigbana ni ọgọrin ọkunrin wá lati Ṣekemu, lati Ṣilo, ati lati Samaria, ti nwọn fá irungbọn wọn, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si ṣá ara wọn lọgbẹ, nwọn mu ọrẹ-ẹbọ ati turari li ọwọ wọn lati mu u wá si ile Oluwa.

6 Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si jade lati Mispa lọ ipade wọn, bi o ti nlọ, o nsọkun: o si ṣe, bi o ti pade wọn, o wi fun wọn pe, jẹ ki a lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu.

7 O si ṣe, nigbati nwọn de ãrin ilu, ni Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, pa wọn, on, ati awọn ọkunrin ti o wà pẹlu rẹ̀ si sọ wọn sinu iho.

8 Ṣugbọn ọkunrin mẹwa wà lãrin wọn ti nwọn sọ fun Iṣmaeli pe, máṣe pa wa: nitori awa ni iṣura li oko, ti alikama, ati ti ọka barli, ati ti ororo, ati oyin. Bẹ̃li o jọwọ wọn, kò si pa wọn pẹlu awọn arakunrin wọn.

9 Ati iho na ninu eyi ti Iṣmaeli ti sọ gbogbo okú ọkunrin wọnyi si, awọn ti o ti pa pẹlu Gedaliah, ni eyiti Asa, ọba, ti ṣe nitori ibẹ̀ru Baaṣa, ọba Israeli: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si fi awọn ti a pa kún u.

10 Iṣmaeli si kó gbogbo iyokù awọn enia ti o wà ni Mispa ni igbekun, awọn ọmọbinrin ọba, ati gbogbo enia ti o kù ni Mispa, awọn ti Nebusaradani, balogun iṣọ, ti fi le Gedaliah, ọmọ Ahikamu lọwọ: Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, si kó wọn ni igbekun, o si kuro nibẹ lati rekọja lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni.

11 Ṣugbọn nigbati Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o pẹlu rẹ̀, gbọ́ ibi ti Iṣmaeli, ọmọ Netaniah ti ṣe,

12 Nigbana ni nwọn kó gbogbo awọn ọkunrin, nwọn si lọ iba Iṣmaeli, ọmọ Netaniah jà, nwọn si ri i li ẹba omi nla ti o wà ni Gibeoni.

13 O si ṣe, nigbati gbogbo awọn enia ti o wà pẹlu Iṣmaeli ri Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o pẹlu rẹ̀, nwọn si yọ̀,

14 Bẹ̃ni gbogbo awọn enia, ti Iṣmaeli ti kó lọ ni igbekun lati Mispa, yi oju wọn, nwọn si yipada, nwọn si lọ sọdọ Johanani, ọmọ Karea.

15 Ṣugbọn Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, bọ́ lọwọ Johanani pẹlu ọkunrin mẹjọ, o si lọ sọdọ awọn ọmọ Ammoni.

16 Johanani, ọmọ Karea, ati gbogbo awọn olori ogun ti o wà pẹlu rẹ̀, si mu gbogbo iyokù awọn enia ti o ti gbà lọwọ Iṣmaeli, ọmọ Netaniah, lati Mispa, lẹhin ti o ti pa Gedaliah, ọmọ Ahikamu ani, akọni ọkunrin ogun, ati awọn obinrin, ati awọn ọmọde, ati awọn iwẹfa, awọn ti o ti tun mu pada lati Gibeoni wá:

17 Nwọn si kuro nibẹ, nwọn si joko ni ibugbe Kinhamu, ti o wà lẹba Betlehemu, lati lọ ide Egipti.

18 Nitoriti ẹ̀ru ba wọn niwaju awọn ara Kaldea, nitoriti Iṣmaeli ọmọ Netaniah, ti pa Gedaliah, ọmọ Ahikamu ẹniti ọba Babeli fi jẹ bãlẹ ni ilẹ na.