1 BAYI li Oluwa wi fun mi pe: Lọ, ki o si rà àmure aṣọ ọgbọ̀, ki o si dì i mọ ẹgbẹ rẹ, ki o má si fi i sinu omi.
2 Bẹ̃ li emi si rà àmure na, gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, emi si dì i mọ ẹgbẹ mi.
3 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wa lẹ̃keji wipe:
4 Mu amure ti iwọ ti rà, ti o wà li ẹgbẹ rẹ, ki o si dide, lọ si odò Ferate, ki o si fi i pamọ nibẹ, ninu pàlapála okuta.
5 Bẹ̃ni mo lọ, emi si fi i pamọ leti odò Ferate, gẹgẹ bi Oluwa ti paṣẹ fun mi.
6 O si ṣe lẹhin ọjọ pupọ, Oluwa wi fun mi pe, Dide, lọ si odò Ferate, ki o si mu amure nì jade, ti mo paṣẹ fun ọ lati fi pamọ nibẹ.
7 Mo si lọ si odò Ferate, mo si walẹ̀, mo si mu àmure na jade kuro ni ibi ti emi ti fi i pamọ si, sa wò o, àmure na di hihù, kò si yẹ fun ohunkohun.
8 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,
9 Bayi li Oluwa wi, Gẹgẹ bi eyi na ni emi o bà igberaga Juda jẹ, ati igberaga nla Jerusalemu.
10 Awọn enia buburu yi, ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi, ti nrin ni agidi ọkàn wọn, ti o si nrin tọ̀ awọn ọlọrun miran, lati sìn wọn ati lati foribalẹ fun wọn, yio si dabi àmure yi, ti kò yẹ fun ohunkohun.
11 Nitori bi amure iti lẹ̀ mọ ẹgbẹ enia, bẹ̃ni mo ṣe ki gbogbo ile Israeli ati gbogbo ile Juda ki o lẹ̀ mọ mi lara, li Oluwa wi, ki nwọn ki o le jẹ enia mi, ati orukọ ati ogo, ati iyìn, ṣugbọn nwọn kò fẹ igbọ́.
12 Nitorina ki iwọ ki o sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, Gbogbo igo ni a o fi ọti-waini kún: nwọn o si wi fun ọ pe, A kò ha mọ̀ nitõtọ pe, gbogbo igo ni a o fi ọti-waini kún?
13 Nigbana ni iwọ o sọ fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi imutipara kún gbogbo olugbe ilẹ yi, ani awọn ọba ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn alufa ati awọn woli, pẹlu gbogbo awọn olugbe Jerusalemu.
14 Emi o tì ekini lu ekeji, ani awọn baba ati awọn ọmọkunrin pọ̀, li Oluwa wi: emi kì yio dariji, bẹ̃ni emi kì o ṣãnu, emi kì yio ṣe iyọ́nu, lati má pa wọn run.
15 Ẹ gbọ́, ki ẹ si fi eti silẹ; ẹ má ṣe gberaga: nitori ti Oluwa ti sọ̀rọ.
16 Ẹ fi ogo fun Oluwa Ọlọrun nyin, ki o to mu òkunkun wá, ati ki o to mu ẹsẹ nyin tase lori oke ṣiṣu wọnni, ati nigbati ẹnyin si nreti imọlẹ, on o sọ ọ di ojiji ikú, o si ṣe e bi òkunkun biribiri.
17 Ṣugbọn bi ẹnyin kì o gbọ́, ọkàn mi yio sọkun ni ibi ikọkọ, nitori igberaga na, oju mi yio sọkun kikan, yio sun omije pẹ̀rẹpẹ̀rẹ, nitori ti a kó agbo Oluwa lọ ni igbekun.
18 Sọ fun ọba ati fun ayaba pe, Ẹ rẹ̀ ara nyin silẹ, ẹ joko silẹ, nitori ade ogo nyin bọ́ si ilẹ lati ori nyin.
19 Ilu gusu wọnni ni a o si mọ, kò si ẹnikan ti yio ṣe wọn: a o kó Judah lọ ni igbekun gbogbo rẹ̀, a o kó wọn lọ patapata ni igbekun.
20 Gbe oju nyin soke, ki ẹ si wo awọn ti mbọ̀ lati ariwa! nibo ni agbo-ẹran nì wà, ti a ti fi fun ọ, agbo-ẹran rẹ daradara?
21 Kini iwọ o wi, nigbati on o fi awọn ti iwọ ti kọ́ lati ṣe korikosun rẹ jẹ olori lori rẹ, irora kì yio ha mu ọ bi obinrin ti nrọbi?
22 Bi iwọ ba si wi ninu ọkàn rẹ pe, Ẽṣe ti nkan wọnyi ṣe wá sori mi? Nitori ti ọ̀pọlọpọ ẹ̀ṣẹ rẹ ni a ṣe ká aṣọ rẹ soke, ti a si fi agbara fi gigisẹ rẹ hàn ni ihoho.
23 Ara Etiopia le yi àwọ rẹ̀ pada, tabi ẹkùn le yi ilà ara rẹ̀ pada? bẹ̃ni ẹnyin pẹlu iba le ṣe rere, ẹnyin ti a kọ́ ni ìwa buburu?
24 Nitorina ni emi o tú wọn ka bi iyangbo ti nkọja lọ niwaju afẹfẹ aginju.
25 Eyi ni ipin rẹ, apakan òṣuwọn rẹ lọwọ mi, li Oluwa wi: nitori iwọ ti gbàgbe mi, ti o si gbẹkẹle eke.
26 Nitorina emi o ka aṣọ iṣẹti rẹ loju rẹ, ki itiju rẹ ki o le hàn sode.
27 Emi ti ri panṣaga rẹ, ati yiyan rẹ bi ẹṣin, buburu ìwa-agbere rẹ, ati ìwa irira rẹ lori oke ati ninu oko. Egbe ni fun ọ, iwọ Jerusalemu! iwọ kò le di mimọ́, yio ha ti pẹ to!