1 BAYI li Oluwa wi, Lọ, rà igo amọ ti amọkoko, si mu ninu awọn àgba enia, ati awọn àgba alufa;
2 Ki o si lọ si afonifoji ọmọ Hinnomu ti o wà niwaju ẹnu-bode Harsiti, nibẹ ni ki o si kede gbogbo ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ.
3 Ki o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda, ati olugbe Jerusalemu; Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi: sa wò o, emi o mu ibi wá sihin yi, eyiti eti gbogbo awọn ti o ba gbọ́ ọ, yio ho.
4 Nitori nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn ti sọ ihín yi di iyapa, nwọn si ti sun turari ninu rẹ̀ fun awọn ọlọrun miran, eyiti awọn, tabi awọn baba wọn kò mọ̀ ri, tabi awọn ọba Juda, nwọn si ti fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ kún ibi yi;
5 Nwọn ti kọ́ ibi giga fun Baali pẹlu, lati fi iná sun ọmọkunrin wọn, bi ẹbọ-ọrẹ sisun fun Baali, eyiti emi kò pa laṣẹ lati ṣe, ti emi kò si sọ, tabi ti kò si ru soke ninu mi:
6 Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, a kì yio pe orukọ ibi yi ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn Afonifoji ipakupa.
7 Emi o sọ igbimọ Juda ati Jerusalemu di asan ni ibi yi; emi o mu ki nwọn ki o ṣubu niwaju ọta wọn, ati lọwọ awọn ti o nwá ẹmi wọn, okú wọn ni a o fi fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati ẹranko ilẹ fun onjẹ.
8 Emi o si sọ ilu yi di ahoro, ati ẹ̀gan, ẹnikẹni ti o ba nkọja lọ nibẹ yio dãmu, yio si poṣe nitori gbogbo ìna rẹ̀.
9 Emi o si mu ki nwọn ki o jẹ ẹran-ara awọn ọmọkunrin wọn, ati ẹran-ara awọn ọmọbinrin wọn, ati ẹnikini wọn yio jẹ ẹran-ara ẹnikẹji ni igba idoti ati ihamọ, ti awọn ọta wọn, ati awọn ti o nwá ẹmi wọn yio ha wọn mọ.
10 Nigbana ni iwọ o fọ igo na li oju awọn ti o ba ọ lọ.
11 Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Bẹ̃ gẹgẹ li emi o fọ enia yi ati ilu yi, bi a ti ifọ ohun-èlo amọkoko, ti ẹnikan kò le tun ṣe mọ, nwọn o si sin wọn ni Tofeti, nitoriti aye kò si lati sinkú.
12 Bayi li emi o ṣe si ibi yi, li Oluwa wi, ati si olugbe inu rẹ̀, emi o tilẹ ṣe ilu yi bi Tofeti:
13 Gbogbo ile Jerusalemu ati ile awọn ọba Juda ni a o sọ di alaimọ́ bi Tofeti, gbogbo ile wọnni, lori orule eyiti a ti sun turari fun ogun ọrun, ti a si ru ẹbọ mimu fun ọlọrun miran.
14 Nigbana ni Jeremiah wá si Tofeti, nibiti Oluwa ti rán a lati sọ asọtẹlẹ; o si duro ni àgbala ile Oluwa; o si wi fun gbogbo awọn enia pe,
15 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu wá sori ilu yi, ati sori ileto rẹ̀ gbogbo ibi ti mo ti sọ si i, nitori ti nwọn ti wà ọrun kì, ki nwọn ki o má bà gbọ́ ọ̀rọ mi.