Jer 2 YCE

Ìtọ́jú Ọlọrun lórí Israẹli

1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,

2 Lọ, ki o si ke li eti Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, Emi ranti rẹ, iṣeun igbà ọmọde rẹ, ifẹ igbeyawo rẹ, nigbati iwọ tẹle mi ni iju, ni ilẹ ti a kì igbin si.

3 Mimọ́ ni Israeli fun Oluwa, akọso eso oko rẹ̀, ẹnikẹni ti o fi jẹ yio jẹbi; ibi yio si wá si ori wọn, li Oluwa wi.

Ẹ̀ṣẹ̀ Àwọn Baba Ńlá Israẹli

4 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ara-ile Jakobu, ati gbogbo iran ile Israeli:

5 Bayi li Oluwa wi: Aiṣedede wo li awọn baba nyin ri lọwọ mi ti nwọn lọ jina kuro lọdọ mi, ti nwọn si tẹle asan, ti nwọn si di enia asan?

6 Bẹ̃ni nwọn kò si wipe, nibo li Oluwa wà? ti o mu wa goke lati ilẹ Egipti wá, ti o mu wa rìn ninu iju, ninu ilẹ pẹtẹlẹ ati ihò, ninu ilẹ gbigbẹ ati ojiji ikú, ninu ilẹ ti enia kò là kọja, ati nibiti enia kò tẹdo si.

7 Emi si mu nyin wá si ilẹ ọgba-eso, lati jẹ eso rẹ̀ ati ire rẹ̀; ṣugbọn ẹnyin wọ inu rẹ̀, ẹ si ba ilẹ mi jẹ, ẹ si sọ ogún mi di ohun irira:

8 Awọn alufa kò wipe, Nibo li Oluwa wà? ati awọn ti o mu ofin lọwọ kò mọ̀ mi: awọn oluṣọ si ṣẹ̀ si mi, ati awọn woli sọ asọtẹlẹ nipa Baali, nwọn si tẹle ohun ti kò lerè.

OLUWA fi Ẹ̀sùn Kan Àwọn Eniyan Rẹ̀

9 Nitorina, Emi o ba nyin jà, li Oluwa wi, Emi o si ba atọmọde-ọmọ nyin jà.

10 Njẹ, ẹ kọja lọ si erekuṣu awọn ara Kittimu, ki ẹ si wò, si ranṣẹ lọ si Kedari, ki ẹ si ṣe akiyesi gidigidi, ki ẹ wò bi iru nkan yi ba mbẹ nibẹ?

11 Orilẹ-ède kan ha pa ọlọrun rẹ̀ dà? sibẹ awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun! ṣugbọn enia mi ti yi ogo wọn pada fun eyiti kò lerè.

12 Ki ẹnu ki o ya ọrun nitori eyi, ki o si dãmu, ki o si di gbigbẹ, li Oluwa wi!

13 Nitori awọn enia mi ṣe ibi meji: nwọn fi Emi, isun omi-ìye silẹ, nwọn si wà kanga omi fun ara wọn, kanga fifọ́ ti kò le da omi duro.

Èrè Aiṣododo Israẹli

14 Ẹrú ni Israeli iṣe bi? tabi ẹru ibile? ẽṣe ti o fi di ijẹ.

15 Awọn ọmọ kiniun ke ramuramu lori rẹ̀, nwọn si bú, nwọn si sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ilu rẹ̀ li a fi jona li aini olugbe.

16 Awọn ọmọ Nofi ati ti Tafanesi pẹlu ti jẹ agbari rẹ;

17 Fifi Oluwa ọlọrun rẹ silẹ kọ́ ha mu eyi ba ọ, nigbati o tọ́ ọ loju ọ̀na?

18 Njẹ nisisiyi kíni iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Egipti, lati mu omi Sihori? tabi kini iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Assiria lati mu omi odò rẹ̀.

19 Ìwa-buburu rẹ ni yio kọ́ ọ, ipadasẹhin rẹ ni yio si ba ọ wi: mọ̀, ki iwọ si ri i pe, ohun buburu ati kikoro ni, pe, iwọ ti kò Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe ìbẹru mi kò si si niwaju rẹ; li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi.

Israẹli Kọ̀ láti Sin OLUWA

20 Nitori ni igba atijọ iwọ ti ṣẹ́ ajaga ọrun rẹ, iwọ si já idè rẹ; iwọ si wipe, Emi kì o sìn, nitori lori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo ni iwọ nṣe panṣaga.

21 Ṣugbọn emi ti gbin ọ ni ajara ọlọla, irugbin rere patapata: ẽṣe ti iwọ fi yipada di ẹka ajara ajeji si mi?

22 Nitori iwọ iba wẹ ara rẹ ni ẽru, ki o si mu ọṣẹ pupọ, ẽri ni ẹ̀ṣẹ rẹ niwaju mi sibẹsibẹ, li Oluwa Ọlọrun wi.

23 Bawo li o ṣe wipe, emi kò ṣe alaimọ́, emi kò tọpa Baalimu? wò ọ̀na rẹ li afonifoji, mọ̀ ohun ti iwọ ti ṣe, iwọ dabi abo ibakasiẹ ayasẹ̀ ti nrin ọ̀na rẹ̀ ka.

24 Kẹtẹkẹtẹ igbẹ ti ima gbe aginju, ninu ifẹ ọkàn rẹ̀ ti nfa ẹfufu, li akoko rẹ̀, tani le yi i pada? gbogbo awọn ti nwá a kiri kì yio da ara wọn li agara, nwọn o ri i li oṣu rẹ̀.

25 Da ẹsẹ̀ rẹ duro ni aiwọ bàta, ati ọfun rẹ ninu ongbẹ: ṣugbọn iwọ wipe, lasan ni! bẹ̃kọ, nitoriti emi ti fẹ awọn alejo, awọn li emi o tọ̀ lẹhin.

Ó Tọ́ kí Israẹli Jìyà

26 Gẹgẹ bi oju ti itì ole nigbati a ba mu u, bẹ̃li oju tì ile Israeli; awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn pẹlu.

27 Ti nwọn wi fun igi pe, Iwọ ni baba mi; ati fun okuta pe, iwọ li o bi mi. Nitori nwọn ti yi ẹ̀hìn wọn pada si mi kì iṣe iwaju wọn: ṣugbọn ni igba ipọnju wọn, nwọn o wipe, Dide, ki o gbani.

28 Njẹ nibo li awọn ọlọrun rẹ wà, ti iwọ ti da fun ara rẹ? jẹ ki nwọn ki o dide, bi nwọn ba le gba ọ nigba ipọnju rẹ, nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃li ọlọrun rẹ, iwọ Juda.

29 Ẽṣe ti ẹnyin o ba mi jà? gbogbo nyin li o ti rufin mi, li Oluwa wi.

30 Lasan ni mo lù ọmọ nyin, nwọn kò gbà ibawi, idà ẹnyin tikara nyin li o pa awọn woli bi kiniun apanirun.

31 Iran enia yi, ẹ kiyesi ọ̀rọ Oluwa. Emi ha ti di aginju si Israeli bi? tabi ilẹ okunkun biribiri, ẽṣe ti enia mi wipe, awa nrin kakiri, awa kì yio tọ̀ ọ wá mọ.

32 Wundia le gbagbe ohun ọṣọ rẹ̀, tabi iyawo ọjá-ọṣọ rẹ̀? ṣugbọn enia mi ti gbagbe mi li ọjọ ti kò ni iye.

33 Ẽṣe ti iwọ tun ọ̀na rẹ ṣe lati wá ifẹ rẹ? nitorina iwọ ṣe kọ́ awọn obinrin buburu li ọ̀na rẹ.

34 Pẹlupẹlu ẹjẹ ẹmi awọn talaka ati alaiṣẹ mbẹ lara aṣọ rẹ, iwọ kò ri wọn nibi irunlẹ wọle, ṣugbọn lara gbogbo wọnyi.

35 Sibẹ iwọ wipe, alaiṣẹ̀ li emi, ibinu rẹ̀ yio sa yipada lọdọ mi. Sa wò o, emi o ba ọ jà, nitori iwọ wipe, emi kò ṣẹ̀.

36 Ẽṣe ti iwọ ṣe ati yi ọ̀na rẹ pada bẹ̃, oju yio tì ọ pẹlu fun Egipti, gẹgẹ bi oju ti tì ọ fun Assiria.

37 Lõtọ iwọ o kuro lọdọ rẹ̀, iwọ o si ka ọwọ le ori, nitori Oluwa ti kọ̀ awọn onigbẹkẹle rẹ, iwọ kì yio si ṣe rere ninu wọn.