1 Ọ̀RỌ ti Oluwa sọ si Babeli ati si ilẹ awọn ara Kaldea nipa ẹnu Jeremiah woli.
2 Ẹ sọ ọ lãrin awọn orilẹ-ède, ẹ si kede, ki ẹ si gbe asia soke: ẹ kede, ẹ má si ṣe bò o: wipe, a kó Babeli, oju tì Beli, a fọ Merodaki tutu; oju tì awọn ere rẹ̀, a fọ awọn òriṣa rẹ̀ tutu.
3 Nitori lati ariwa ni orilẹ-ède kan ti wá sori rẹ̀, ti yio sọ ilẹ rẹ̀ di ahoro, ẹnikan kì o gbe inu rẹ̀: nwọn o sa, nwọn o lọ, ati enia ati ẹranko.
4 Li ọjọ wọnni ati li àkoko na, li Oluwa wi, awọn ọmọ Israeli yio jumọ wá, awọn, ati awọn ọmọ Juda, nwọn o ma lọ tẹkúntẹkún: nwọn o lọ, nwọn o si ṣafẹri Oluwa Ọlọrun wọn.
5 Nwọn o ma bère ọ̀na Sioni, oju wọn yio si yi sibẹ, nwọn o wá, nwọn o darapọ mọ Oluwa ni majẹmu aiyeraiye, ti a kì yio gbagbe.
6 Awọn enia mi ti jẹ agbo-agutan ti o sọnu: awọn oluṣọ-agutan wọn ti jẹ ki nwọn ṣina, nwọn ti jẹ ki nwọn rìn kiri lori oke: nwọn ti lọ lati ori oke nla de oke kekere, nwọn ti gbagbe ibusun wọn.
7 Gbogbo awọn ti o ri wọn, ti pa wọn jẹ: awọn ọta wọn si wipe, Awa kò jẹbi, nitoripe nwọn ti ṣẹ̀ si Oluwa ibugbe ododo, ati ireti awọn baba wọn, ani Oluwa.
8 Ẹ salọ kuro li ãrin Babeli, ẹ si jade kuro ni ilẹ awọn ara Kaldea, ki ẹ si jẹ bi obukọ niwaju agbo-ẹran.
9 Nitori, wò o, emi o gbe dide, emi o si mu apejọ awọn orilẹ-ède nla lati ilẹ ariwa wá sori Babeli: nwọn o si tẹgun si i, lati ibẹ wá li a o si ti mu u: ọfa wọn yio dabi ti akọni amoye; ọkan kì yio pada li asan.
10 Kaldea yio si di ikogun: gbogbo awọn ti o fi ṣe ikogun ni a o tẹ́ lọrùn, li Oluwa wi.
11 Nitoripe inu nyin dùn, nitoripe ẹnyin yọ̀, ẹnyin olè ti o ji ini mi, nitori ti ẹnyin fi ayọ̀ fò bi ẹgbọrọ malu si koriko tutu, ẹ si nyán bi akọ-ẹṣin:
12 Oju yio tì iya nyin pupọpupọ; itiju yio bo ẹniti o bi nyin: wò o, ikẹhin awọn orilẹ-ède! aginju, ilẹ gbigbẹ, ati ahoro!
13 Nitori ibinu Oluwa li a kì yio gbe inu rẹ̀, ṣugbọn yio dahoro patapata: olukuluku ẹniti o ba re Babeli kọja yio yanu, yio si ṣe ẹlẹya si gbogbo ipọnju rẹ̀.
14 Ẹ tẹgun si Babeli yikakiri: gbogbo ẹnyin ti nfà ọrun, ẹ tafa si i, ẹ máṣe ṣọ́ ọfa lò, nitoriti o ti ṣẹ̀ si Oluwa.
15 Ẹ ho bo o yikakiri: o ti nà ọwọ rẹ̀: ọwọ̀n ìti rẹ̀ ṣubu, a wó odi rẹ̀ lulẹ: nitori igbẹsan Oluwa ni: ẹ gbẹsan lara rẹ̀; gẹgẹ bi o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i.
16 Ke afunrugbin kuro ni Babeli, ati ẹniti ndi doje mu ni igbà ikore! nitori ẹ̀ru idà ti nṣika, olukuluku wọn o yipada si ọdọ enia rẹ̀, olukuluku yio si salọ si ilẹ rẹ̀.
17 Israeli jẹ́ agutan ti o ṣina kiri, awọn kiniun ti le e lọ: niṣaju ọba Assiria pa a jẹ, ati nikẹhin yi Nebukadnessari, ọba Babeli, sán egungun rẹ̀.
18 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, wò o, emi o jẹ ọba Babeli ati ilẹ rẹ̀ niya, gẹgẹ bi emi ti jẹ ọba Assiria niya.
19 Emi o si tun mu Israeli wá si ibugbe rẹ̀, on o si ma bọ ara rẹ̀ lori Karmeli, ati Baṣani, a o si tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrun li oke Efraimu ati ni Gileadi.
20 Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, li Oluwa wi, a o wá aiṣedẽde Israeli kiri, ṣugbọn kì o si mọ́; ati ẹ̀ṣẹ Juda, a kì o si ri wọn: nitori emi o dariji awọn ti mo mu ṣẹkù.
21 Goke lọ si ilẹ ọlọtẹ li ọ̀na meji, ani sori rẹ̀ ati si awọn olugbe ilu Ibẹwo: sọ ọ di ahoro ki o si parun lẹhin wọn, li Oluwa wi, ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti emi ti paṣẹ fun ọ.
22 Iró ogun ni ilẹ na, ati ti iparun nla!
23 Bawo li a ti fọ, ti a si ṣẹ olú gbogbo ilẹ aiye! Bawo ni Babeli di ahoro lãrin awọn orilẹ-ède!
24 Emi ti kẹ okùn fun ọ, a si mu ọ, iwọ Babeli, iwọ kò si mọ̀: a ri ọ, a si mu ọ pẹlu, nitoripe iwọ ti ba Oluwa ja.
25 Oluwa ti ṣi ile ohun-ijà rẹ̀ silẹ; o si ti mu ohun-elo ikannu rẹ̀ jade: nitori Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ni iṣẹ́ iṣe ni ilẹ awọn ara Kaldea.
26 Ẹ wá sori rẹ̀ lati opin gbogbo, ṣi ile iṣura rẹ̀ silẹ: ẹ kó o jọ bi òkiti, ki ẹ si yà a sọtọ fun iparun, ẹ máṣe fi iyokù silẹ fun u!
27 Pa gbogbo awọn akọ-malu rẹ̀! nwọn o lọ si ibi pipa: ègbe ni fun wọn! nitori ọjọ wọn de, àkoko ibẹwo wọn.
28 Ohùn awọn ti o salọ, ti o si sala lati ilẹ Babeli wá, lati kede igbẹsan Oluwa Ọlọrun wa ni Sioni, igbẹsan tempili rẹ̀!
29 Pè ọ̀pọlọpọ enia, ani gbogbo tafatafa, sori Babeli, ẹ dótì i yikakiri; má jẹ ki ẹnikan sala: san fun u gẹgẹ bi iṣẹ rẹ̀; gẹgẹ bi gbogbo eyi ti o ti ṣe, ẹ ṣe bẹ̃ si i, nitoriti o ti gberaga si Oluwa, si Ẹni-Mimọ Israeli.
30 Nitorina ni awọn ọdọmọdekunrin rẹ̀ yio ṣubu ni ita rẹ̀, ati gbogbo awọn ologun rẹ̀ li a o ke kuro li ọjọ na, li Oluwa wi.
31 Wò o, emi dojukọ ọ! iwọ agberaga, li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, wi: nitori ọjọ rẹ de, àkoko ti emi o bẹ̀ ọ wò.
32 Agberaga yio kọsẹ, yio si ṣubu, ẹnikan kì o si gbe e dide: emi o si da iná ni ilu rẹ̀, yio si jo gbogbo ohun ti o yi i kakiri.
33 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, pe, awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda li a jumọ pọn loju pọ̀: gbogbo awọn ti o kó wọn ni ìgbekun si di wọn mu ṣinṣin; nwọn kọ̀ lati jọ wọn lọwọ lọ.
34 Ṣugbọn Olurapada wọn lagbara; Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀: ni jijà yio gba ijà wọn jà! ki o le mu ilẹ na simi, ki o si mu awọn olugbe Babeli wariri.
35 Ida lori awọn ara Kaldea, li Oluwa wi, ati lori awọn olugbe Babeli, ati lori awọn ijoye rẹ̀, ati lori awọn ọlọgbọn rẹ̀?
36 Idà lori awọn ahalẹ nwọn o si ṣarán: idà lori awọn alagbara rẹ̀; nwọn o si damu.
37 Idà lori awọn ẹṣin rẹ̀, ati lori awọn kẹ̀kẹ ati lori gbogbo awọn àjeji enia ti o wà lãrin rẹ̀; nwọn o si di obinrin: idà lori iṣura rẹ̀; a o si kó wọn lọ.
38 Ọda lori omi odò rẹ̀; nwọn o si gbẹ: nitori ilẹ ere fifin ni, nwọn si nṣogo ninu oriṣa wọn.
39 Nitorina awọn ẹran-iju pẹlu ọ̀wawa ni yio ma gbe ibẹ̀, abo ògongo yio si ma gbe inu rẹ̀, a kì o si gbe inu rẹ̀ mọ lailai; bẹ̃ni a kì o ṣatipo ninu rẹ̀ lati irandiran.
40 Gẹgẹ bi Ọlọrun ti bì Sodomu ati Gomorra ṣubu ati awọn aladugbo rẹ̀, li Oluwa wi; bẹ̃ni enia kan kì o gbe ibẹ, tabi ọmọ enia kan kì o ṣatipo ninu rẹ̀.
41 Wò o, orilẹ-ède kan yio wá lati ariwa, ati orilẹ-ède nla, ọba pupọ li o si dide lati opin ilẹ aiye wá.
42 Nwọn o di ọrun ati ọ̀kọ mu: onroro ni nwọn, nwọn kì o si ṣe ãnu: ohùn wọn yio ho gẹgẹ bi okun, nwọn o si gun ori ẹṣin lẹsẹsẹ, nwọn si mura bi ọkunrin ti yio jà ọ logun, iwọ ọmọbinrin Babeli.
43 Ọba Babeli ti gbọ́ iró wọn, ọwọ rẹ̀ si rọ: ẹ̀dun dì i mu, ati irora gẹgẹ bi obinrin ti nrọbi.
44 Wò o, on o goke wá bi kiniun lati wiwú Jordani si ibugbe okuta; nitori ojiji li emi o le wọn lọ kuro nibẹ; ati tani si li ẹniti a yàn, ti emi o yàn sori rẹ̀? nitori tani dabi emi? tani o si pè mi ṣe ẹlẹri? ati tani oluṣọ-agutan na ti yio le duro niwaju mi?
45 Nitorina gbọ́ ìmọ Oluwa, ti o ti gba si Babeli: ati èro rẹ̀, ti o ti gba si ilẹ awọn ara Kaldea: lõtọ awọn ti o kere julọ ninu agbo-ẹran: yio wọ́ wọn kiri: lõtọ on o sọ ibugbe di ahoro lori wọn.
46 Nitori ohùn igbe nla pe: a kó Babeli, ilẹ-aiye mì, a si gbọ́ ariwo na lãrin awọn orilẹ-ède.