1 Ọ̀RỌ ti o ti ọdọ Oluwa wá sọdọ Jeremiah wipe:
2 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ majẹmu yi, ki ẹ si sọ fun awọn enia Juda ati awọn olugbe Jerusalemu,
3 Ki iwọ ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Ifibu ni oluwarẹ̀ ti kò ba gbà ọ̀rọ majẹmu yi gbọ́,
4 Ti mo pa li aṣẹ fun awọn baba nyin, li ọjọ ti mo mu wọn ti ilẹ Egipti jade, lati inu ileru irin wipe, Gbà ohùn mi gbọ́, ki ẹ si ṣe gẹgẹ bi emi ti paṣẹ fun nyin: bẹ̃ni ẹnyin o jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun nyin:
5 Ki emi ki o le mu ileri mi ṣẹ, ti mo ti bura fun awọn baba nyin, lati fun wọn ni ilẹ ti nṣàn fun wara ati fun oyin, gẹgẹ bi o ti ri li oni: mo si dahùn mo si wipe, Amin, Oluwa!
6 Oluwa si wi fun mi pe, Kede gbogbo ọ̀rọ wọnyi ni ilu Juda ati ni ita Jerusalemu wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ majẹmu yi ki ẹ si ṣe wọn.
7 Nitori ni kikilọ mo kilọ fun awọn baba nyin lati ọjọ ti mo ti mu wọn wá lati ilẹ Egipti, titi di oni, emi si nyara kilọ fun wọn, mo si nsọ wipe, Ẹ gbà ohùn mi gbọ́.
8 Sibẹsibẹ nwọn kò gbọ́, nwọn kò tẹti silẹ, nwọn si rìn, olukuluku wọn ni agidi ọkàn buburu wọn: nitorina emi o mu gbogbo ọ̀rọ majẹmu yi wá sori wọn, ti mo paṣẹ fun wọn lati ṣe; nwọn kò si ṣe e.
9 Oluwa si wi fun mi pe, A ri ìditẹ lãrin awọn ọkunrin Juda ati lãrin awọn olugbe Jerusalemu.
10 Nwọn yipada si ẹ̀ṣẹ iṣaju awọn baba wọn ti o kọ̀ lati gbọ́ ọ̀rọ mi; awọn wọnyi si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati sìn wọn: ile Israeli ati ile Juda ti dà majẹmu mi ti mo ba awọn baba wọn dá.
11 Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, Emi o mu ibi wá sori wọn, ti nwọn kì yio le yẹba fun: bi nwọn tilẹ ke pè mi, emi kì yio fetisi igbe wọn.
12 Jẹ ki ilu Juda ati awọn olugbe Jerusalemu ki o lọ, ki nwọn ki o si ke pe awọn ọlọrun ti nwọn ńsun turari fun, ṣugbọn lõtọ nwọn kì yio le gba wọn ni igba ipọnju wọn.
13 Nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃ni iye ọlọrun rẹ, iwọ Juda, ati bi iye ita Jerusalemu, bẹ̃ni iye pẹpẹ ti ẹnyin ti tẹ́ fun ohun itìju nì, pẹpẹ lati sun turari fun Baali.
14 Nitorina máṣe gbadura fun awọn enia yi, bẹ̃ni ki o má si ṣe gbe ohùn ẹkun tabi ti adura soke fun wọn, nitori emi kì yio gbọ́ ni igba ti nwọn ba kigbe pè mi, ni wakati wahala wọn.
15 Kini olufẹ mi ni iṣe ni ile mi? nigbati nwọn nṣe buburu pupọ bayi? adura on ẹran mimọ́ ha le mu ibi kọja kuro lọdọ rẹ? bi o ba ri bayi? nigbana jẹ ki inu rẹ ki o dùn.
16 Oluwa pè orukọ rẹ ni igi Olifi tutu, didara, eleso rere: ṣugbọn nisisiyi o fi ariwo irọkẹkẹ nla dá iná lara rẹ̀, ẹka rẹ̀ li o si faya.
17 Nitori Oluwa awọn ọmọ-ogun, ti o gbìn ọ, ti sọ̀rọ ibi si ọ, nitori buburu ile Israeli, ati ile Juda, ti nwọn ti ṣe si ara wọn lati ru ibinu mi soke ni sisun turari fun Baali.
18 Oluwa si ti mu mi mọ̀, emi si mọ̀: nigbana ni iwọ fi iṣe wọn hàn mi.
19 Ani mo dabi ọdọ-agutan ti o mọ̀ oju ile, ti a mu wá fun pipa: emi kò si mọ̀ pe, nwọn ti pinnu buburu si mi wipe: Jẹ ki a ke igi na pẹlu eso rẹ̀ ki a si ke e kuro ni ilẹ alãye, ki a máṣe ranti orukọ rẹ̀ mọ.
20 Ṣugbọn Oluwa awọn ọmọ-ogun, onidajọ otitọ ti ndan aiya ati inu wò, emi o ri igbẹsan rẹ lori wọn: nitori iwọ ni mo fi ọ̀ran mi le lọwọ.
21 Nitorina bayi li Oluwa wi, niti enia Anatoti ti o nwá ẹmi rẹ, ti nwipe, Máṣe sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa, ki iwọ ki o má ba kú nipa, ọwọ wa.
22 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, wò o, emi o bẹ̀ wọn wo, awọn ọdọmọkunrin o ti ọwọ idà kú, ọmọ wọn ọkunrin ati ọmọ wọn obinrin yio kú nipa iyàn:
23 Ẹnikan kì yio kù ninu wọn: nitori emi o mu ibi wá sori awọn enia Anatoti, ani ọdun ìbẹwo wọn.