1 Ọ̀RỌ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah woli wá, si awọn ara Filistia, ki Farao ki o to kọlu Gasa.
2 Bayi li Oluwa wi; Wò o, omi dide lati ariwa, yio si jẹ kikun omi akunya, yio si ya bo ilẹ na, ati gbogbo ẹkún inu rẹ̀; ilu na, ati awọn ti ngbe inu rẹ̀: nigbana ni awọn enia yio kigbe, gbogbo awọn olugbe ilẹ na yio si hu.
3 Nipa ariwo titẹlẹ Patakò ẹsẹ alagbara ẹṣin rẹ̀, nipa iró nla kẹ̀kẹ rẹ̀, ati nipa ariwo nla ayika kẹ̀kẹ rẹ̀; awọn baba kì yio bojuwo ẹhin wò awọn ọmọ wọn nitori ọwọ́ rirọ;
4 Nitori ọjọ na ti mbọ lati pa gbogbo awọn ara Filistia run, ati lati ke gbogbo oluranlọwọ ti o kù kuro lọdọ Tire ati Sidoni: nitori Oluwa yio ṣe ikogun awọn ara Filistia, ani iyokù erekuṣu Kaftori.
5 Ipári de si Gasa, Aṣkeloni ti dahoro, pẹlu iyokù afonifoji wọn: iwọ o ti ṣa ara rẹ lọgbẹ pẹ to?
6 Ye! iwọ idà Oluwa, yio ti pẹ to ki iwọ ki o to gbe jẹ? tẹ ara rẹ bọ inu akọ rẹ, simi! ki o si dakẹ!
7 Ṣugbọn bawo li o ti ṣe le gbe jẹ, nigbati Oluwa ti paṣẹ fun u si Aṣkeloni, ati si ebute okun, nibẹ li o ti ran a lọ!