Jer 14 YCE

Ọ̀gbẹlẹ̀ Ńlá

1 EYI li ọ̀rọ Oluwa ti o tọ̀ Jeremiah wá nipa ti ọdá.

2 Juda kãnu ati ẹnu-bode rẹ̀ wọnnì si jõro, nwọn dudu de ilẹ; igbe Jerusalemu si ti goke.

3 Awọn ọlọla wọn si ti rán awọn ọmọ wẹrẹ lọ si odò: nwọn wá si kanga, nwọn kò ri omi; nwọn pada pẹlu agbè wọn lofo, oju tì wọn, idãmu mu wọn, nwọn si bo ori wọn.

4 Nitori ilẹ, ti ndãmu gidigidi, nitoriti òjo kò si ni ilẹ, oju tì awọn àgbẹ, nwọn bo ori wọn.

5 Lõtọ abo-àgbọnrin pẹlu ni papa bimọ, o fi i silẹ nitori ti kò si koriko.

6 Ati awọn kẹtẹkẹtẹ-igbẹ duro lori oke wọnni, nwọn fọn imu si ẹfũfu bi ikõko, oju wọn rẹ̀ nitoriti kò si koriko.

7 Oluwa, bi ẹ̀ṣẹ wa ti jẹri si wa to nì, ṣe atunṣe nitori orukọ rẹ: nitoriti ipẹhinda wa pọ̀; si ọ li awa ti ṣẹ̀.

8 Iwọ, ireti Israeli, olugbala rẹ̀ ni wakati ipọnju! ẽṣe ti iwọ o dabi alejo ni ilẹ, ati bi èro ti o pa agọ lati sùn?

9 Ẽṣe ti iwọ o dabi ẹniti o dãmu, bi ọkunrin akọni ti kò le ràn ni lọwọ? sibẹ iwọ, Oluwa, mbẹ li ãrin wa, a si npè orukọ rẹ mọ wa, má fi wa silẹ.

10 Bayi li Oluwa wi fun awọn enia yi, bayi ni nwọn ti fẹ lati rò kiri, nwọn kò dá ẹsẹ wọn duro; Oluwa kò si ni inu-didun ninu wọn: yio ranti aiṣedẽde wọn nisisiyi, yio si bẹ ẹ̀ṣẹ wọn wò.

11 Nigbana li Oluwa wi fun mi pe, Máṣe gbadura fun awọn enia yi fun rere.

12 Nigbati nwọn ba gbãwẹ, emi kì yio gbọ́ ẹ̀bẹ wọn; nigbati nwọn ba ru ẹbọ-ọrẹ sisun ati ẹbọ-ọrẹ, inu mi kì o dùn si wọn: ṣugbọn emi o fi idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-àrun pa wọn run.

13 Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, sa wò o, awọn woli wi fun wọn pe; Ẹnyin kì yio ri idà, bẹ̃li ìyan kì yio de si nyin; ṣugbọn emi o fun nyin ni alafia otitọ ni ibi yi.

14 Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, awọn woli nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi; emi kò rán wọn, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn, emi kò si sọ̀rọ kan fun wọn, iran eke, afọṣẹ, ati ohun asan, ati ẹ̀tan inu wọn, ni awọn wọnyi sọtẹlẹ fun nyin.

15 Nitorina bayi li Oluwa wi niti awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ li orukọ mi, ti emi kò rán; sibẹ nwọn wipe, Idà ati ìyan kì yio wá sori ilẹ yi; nipa idà, pẹlu ìyan, ni awọn woli wọnyi yio ṣegbe.

16 Ati awọn enia ti nwọn nsọ asọtẹlẹ fun ni a o lù bolẹ ni ita Jerusalemu, nitori ìyan ati idà, nwọn kì yio ri ẹniti o sin wọn, awọn aya wọn, ati ọmọkunrin wọn, ati ọmọbinrin wọn: nitoriti emi o tu ìwa-buburu wọn jade sori wọn.

17 Ki iwọ ki o si sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe: oju mi sun omije li oru ati li ọsan, kì yio si dá, nitoriti a ti ṣa wundia ọmọbinrin enia mi li ọgbẹ nla kikoro gidigidi ni lilù na.

18 Bi emi ba jade lọ si papa, sa wò o, a ri awọn ti a fi idà pa! bi emi ba si wọ inu ilu lọ, sa wò o, awọn ti npa ọ̀kakà ikú nitori iyan! nitori awọn, ati awọn woli, ati awọn alufa nwọ́ lọ si ilẹ ti nwọn kò mọ̀.

Àwọn Eniyan náà Bẹ OLUWA

19 Iwọ ha ti kọ̀ Juda silẹ patapata? ọkàn rẹ ti korira Sioni? ẽṣe ti iwọ ti lù wa, ti imularada kò si fun wa? awa nreti alafia, kò si si rere, ati fun igba imularada, ṣugbọn wò o, idãmu!

20 Awa jẹwọ iwa buburu wa, Oluwa, ati aiṣedede awọn baba wa: nitori awa ti ṣẹ̀ si ọ.

21 Máṣe korira wa, nitori orukọ rẹ, máṣe gan itẹ́ ogo rẹ, ranti, ki o máṣe dà majẹmu ti o ba wa dá.

22 Ẹniti o le mu ojo rọ̀ ha wà lọdọ awọn oriṣa awọn keferi? tabi ọrun le rọ̀ òjo? iwọ ha kọ́, Oluwa Ọlọrun wa? awa si nreti rẹ: nitori iwọ li o da gbogbo nkan wọnyi.