Jer 6 YCE

Àwọn Ọ̀tá Yí Jerusalẹmu Ká

1 ẸNYIN ọmọ Benjamini, ẹ ko ẹrù nyin salọ kuro li arin Jerusalemu, ẹ si fun fère ni Tekoa, ki ẹ si gbe àmi soke ni Bet-hakeremu, nitori ibi farahàn lati ariwa wá; ani iparun nlanla.

2 Emi ti pa ọmọbinrin Sioni run, ti o ṣe ẹlẹgẹ ati ẹlẹwà.

3 Awọn oluṣọ-agutan pẹlu agbo wọn yio tọ̀ ọ wá, nwọn o pa agọ wọn yi i ka olukuluku yio ma jẹ ni àgbegbe rẹ̀.

4 Ẹ ya ara nyin si mimọ́ lati ba a jagun; dide, ki ẹ si jẹ ki a goke li ọsan. Egbe ni fun wa! nitori ọjọ nlọ, nitori ojiji ọjọ alẹ nà jade.

5 Dide, ẹ jẹ ki a goke lọ li oru, ki a si pa ãfin rẹ̀ run.

6 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ke igi lulẹ, ki ẹ si wà yàra ka Jerusalemu; eyi ni ilu nla ti a o bẹ̀wo; kìki ininilara li o wà lãrin rẹ̀.

7 Bi isun ti itú omi rẹ̀ jade, bẹ̃ni o ntú ìwa-buburu rẹ̀ jade: ìwa-ipa ati ìka li a gbọ́ niwaju mi nigbagbogbo ninu rẹ̀, ani aisan ati ọgbẹ́.

8 Gbọ́ ẹkọ́, Jerusalemu, ki ẹmi mi ki o má ba lọ kuro lọdọ rẹ; ki emi má ba sọ ọ di ahoro, ilẹ ti a kò gbe inu rẹ̀.

Israẹli Ọlọ̀tẹ̀

9 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, jẹ ki nwọn ki o pẽṣẹ iyokù Israeli bi àjara: yi ọwọ rẹ pada bi aká-eso-ajara sinu agbọ̀n.

10 Tani emi o sọ fun, ti emi o kilọ fun ti nwọn o si gbọ́? sa wò o, eti wọn jẹ alaikọla, nwọn kò si le fi iye si i: sa wò o, ọ̀rọ Oluwa di ẹ̀gan si wọn, nwọn kò ni inu didùn ninu rẹ̀.

11 Nitorina emi kún fun ikannu Oluwa, ãrẹ̀ mu mi lati pa a mọra: tu u jade sori ọmọde ni ita, ati sori ajọ awọn ọmọkunrin pẹlu: nitori a o mu bãle pẹlu aya rẹ̀ ni igbekun, arugbo pẹlu ẹniti o ni ọjọ kikún lori.

12 Ile wọn o di ti ẹlomiran, oko wọn ati aya wọn lakopọ̀: nitori emi o nà ọwọ mi si ori awọn olugbe ilẹ na, li Oluwa wi.

13 Lati kekere wọn titi de nla wọn, gbogbo wọn li o fi ara wọn fun ojukokoro, ati lati woli titi de alufa, gbogbo wọn ni nṣe eke.

14 Nwọn si ti wo ọgbẹ ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀; nwọn wipe, Alafia! Alafia! nigbati kò si alafia.

15 A mu itiju ba wọn, nitoriti nwọn ṣe ohun irira: sibẹ nwọn kò tiju kan pẹlu, pẹlupẹlu õru itiju kò mu wọn: nitorina nwọn o ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu: nigbati emi ba bẹ̀ wọn wo, a o wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.

Israẹli Kọ Ọ̀nà Ọlọrun sílẹ̀

16 Bayi li Oluwa wi, ẹ duro li oju ọ̀na, ki ẹ si wò, ki ẹ si bere oju-ọ̀na igbàni, ewo li ọ̀na didara, ki ẹ si rin nibẹ, ẹnyin o si ri isimi fun ọkàn nyin. Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio rin.

17 Pẹlupẹlu mo fi oluṣọ sọdọ nyin, ti o wipe, Ẹ fi eti si iro fère. Ṣugbọn nwọn wipe, awa kì yio feti si i.

18 Nitorina, gbọ́, ẹnyin orilẹ-ède, ki ẹ si mọ̀, ẹnyin ijọ enia, ohun ti o wà ninu wọn!

19 Gbọ́, iwọ ilẹ! wò o, emi o mu ibi wá si ori enia yi, ani eso iro inu wọn, nitori nwọn kò fi eti si ọ̀rọ mi, ati ofin mi ni nwọn kọ̀ silẹ.

20 Ère wo li o wà fun mi ninu turari lati Ṣeba wá, ati ẽsu daradara lati ilẹ ti o jina wá? ọrẹ sisun nyin kò ṣe inu-didun mi, ẹbọ jijẹ nyin kò wù mi.

21 Nitorina, bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ohun idugbolu siwaju awọn enia yi, ti baba ati awọn ọmọ yio jumọ ṣubu lù wọn, aladugbo ati ọrẹ rẹ̀ yio ṣegbe.

Ogun láti Ìhà Àríwá

22 Bayi li Oluwa wi, sa wò o, enia kan ti ilu ariwa wá, ati orilẹ-ède nla kan yio ti opin ilẹ aiye dide wá.

23 Nwọn di ọrun ati ọ̀kọ mu; onroro ni nwọn, nwọn kò ni ãnu; ohùn wọn yio hó bi okun; nwọn gun ẹṣin; nwọn si mura bi ọkunrin ti yio ja ọ logun, iwọ ọmọbinrin Sioni.

24 Awa ti gbọ́ òkiki eyi na: ọwọ wa di rirọ, ẹ̀dun ti di wa mu, ati irora bi obinrin ti nrọbi.

25 Máṣe lọ si inu oko, bẹ̃ni ki o má si rin oju ọ̀na na, nitori idà ọ̀ta, idagiri wà yikakiri.

26 Iwọ, ọmọbinrin enia mi, di ara rẹ ni amure aṣọ-ọ̀fọ ki o si ku ẽru sara, ṣe ọ̀fọ bi ẹniti nṣọ̀fọ fun ọmọ rẹ̀ nikanṣoṣo, pohùnrere kikoro: nitori afiniṣe-ijẹ yio ṣubu lù wa lojiji.

27 Emi ti fi ọ ṣe ẹniti o ma dán ni wò, odi alagbara lãrin enia mi, ki iwọ ki o le mọ̀ ki o si le dan ọ̀na wọn wò.

28 Gbogbo nwọn ni alagidi ọlọtẹ̀, ti nrin kiri sọ̀rọ̀ ẹni lẹhin, idẹ ati irin ni nwọn; abanijẹ ni gbogbo nwọn iṣe.

29 Ẹwìri joná, iná ti jẹ ojé, ẹniti nyọ ọ, nyọ ọ lasan, a kò si ya enia buburu kuro.

30 Fàdaka bibajẹ ni enia yio ma pè wọn, nitori Oluwa ti kọ̀ wọn silẹ.