Jer 35 YCE

Jeremiah ati Àwọn Ọmọ Rekabu

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, wipe:

2 Lọ si ile awọn ọmọ Rekabu, ki o si ba wọn sọ̀rọ, ki o si mu wọn wá si ile Oluwa, si ọkan ninu iyara wọnni, ki o si fun wọn li ọti-waini mu.

3 Nigbana ni mo mu Jaasaniah, ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah, ati awọn arakunrin rẹ̀, ati gbogbo awọn ọmọ rẹ̀, ati gbogbo ile awọn ọmọ Rekabu;

4 Mo si mu wọn wá si ile Oluwa, sinu iyara awọn ọmọ Hanani, ọmọ Igdaliah, enia Ọlọrun, ti o wà lẹba iyara awọn ijoye, ti o wà li oke iyara Maaseiah, ọmọ Ṣallumu, olutọju ẹnu-ọ̀na,

5 Mo si gbe ìkoko ti o kún fun ọti-waini pẹlu ago, ka iwaju awọn ọmọ ile Rekabu, mo si wi fun wọn pe: Ẹ mu ọti-waini.

6 Ṣugbọn nwọn wipe, Awa kì yio mu ọti-waini, nitori Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa, paṣẹ fun wa pe: Ẹnyin kò gbọdọ mu ọti-waini, ẹnyin ati awọn ọmọ nyin lailai.

7 Bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ kọ́ ile, tabi ki ẹ fun irugbin, tabi ki ẹ gbin ọgba-àjara, bẹ̃ni ẹnyin kò gbọdọ ni; ṣugbọn ni gbogbo ọjọ nyin li ẹnyin o ma gbe inu agọ; ki ẹnyin ki o le wà li ọjọ pupọ ni ilẹ na nibiti ẹnyin nṣe atipo.

8 Bayi li awa gbà ohùn Jonadabu, ọmọ Rekabu, baba wa gbọ́ ninu gbogbo eyiti o palaṣẹ fun wa, ki a má mu ọti-waini ni gbogbo ọjọ wa, awa, awọn aya wa, awọn ọmọkunrin wa, ati awọn ọmọbinrin wa;

9 Ati ki a má kọ ile lati gbe; bẹ̃ni awa kò ni ọgba-ajara, tabi oko, tabi ohùn ọgbin.

10 Ṣugbọn awa ngbe inu agọ, a si gbọran, a si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jonadabu, baba wa, palaṣẹ fun wa.

11 O si ṣe, nigbati Nebukadnessari, ọba Babeli, goke wá si ilẹ na, ni awa wipe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si Jerusalemu, nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Kaldea, ati nitori ibẹ̀ru ogun awọn ara Siria: bẹ̃ni awa ngbe Jerusalemu.

12 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah wá wipe:

13 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Lọ, ki o si sọ fun awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu pe, Ẹnyin kì yio ha gbà ẹkọ lati feti si ọ̀rọ mi? li Oluwa wi.

14 Ọ̀rọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, ti o pa laṣẹ fun awọn ọmọ rẹ̀, pe, ki nwọn ki o má mu ọti-waini, ni a mu ṣẹ; nwọn kò si mu ọti-waini titi di oni yi. Nitoriti nwọn gbọ́ ofin baba wọn, emi si ti nsọ̀rọ fun nyin, emi dide ni kutukutu, emi nsọ: ṣugbọn ẹnyin kò fetisi ti emi.

15 Emi si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ mi, awọn woli, si nyin pẹlu, emi dide ni kutukutu, mo ran wọn wipe, Ẹ yipada nisisiyi, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun iṣe nyin ṣe rere, ki ẹ máṣe tọ̀ awọn ọlọrun miran lẹhin lati sin wọn, ẹnyin o si ma gbe ilẹ na ti mo ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin; ṣugbọn ẹnyin kò tẹ eti nyin, bẹ̃ni ẹnyin kò si gbọ́ temi.

16 Lõtọ awọn ọmọ Jonadabu, ọmọ Rekabu, pa ofin baba wọn mọ, ti o pa laṣẹ fun wọn; ṣugbọn awọn enia yi kò gbọ́ ti emi:

17 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi pe, Wò o, emi o mu wá sori Juda, ati sori gbogbo olugbe Jerusalemu, gbogbo ibi ti emi ti sọ si wọn; nitori ti emi ti ba wọn sọ̀rọ, nwọn kò si gbọ́; mo si ti pè wọn, nwọn kò si dahùn.

18 Jeremiah si wi fun ile awọn ọmọ Rekabu pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitori ti ẹnyin gbà ofin Jonadabu, baba nyin gbọ́, ti ẹnyin si pa gbogbo ilana rẹ̀ mọ, ti ẹ si ṣe gẹgẹ bi eyi ti o ti palaṣẹ fun nyin:

19 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Jonadabu, ọmọ Rekabu kì yio fẹ ọkunrin kan kù lati duro niwaju mi lailai.