Jer 22 YCE

Iṣẹ́ tí Jeremiah Jẹ́ fún Ìdílé Ọba Juda

1 BAYI li Oluwa wi, Sọkalẹ lọ si ile ọba Juda, ki o si sọ ọ̀rọ yi nibẹ.

2 Si wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ọba Juda, ti o joko ni itẹ Dafidi, iwọ, ati awọn iranṣẹ rẹ, ati awọn enia rẹ ti o wọle ẹnu-bode wọnyi.

3 Bayi li Oluwa wi; Mu idajọ ati ododo ṣẹ, ki o si gbà ẹniti a lọ lọwọ gbà kuro lọwọ aninilara, ki o máṣe fi agbara ati ìka lò alejo, alainibaba ati opó, bẹ̃ni ki o máṣe ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ nihinyi.

4 Nitori bi ẹnyin ba ṣe nkan yi nitõtọ, nigbana ni awọn ọba yio wọle ẹnu-bode ilu yi, ti nwọn o joko lori itẹ Dafidi, ti yio gun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati enia rẹ̀.

5 Ṣugbọn bi ẹnyin kì yio ba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, Emi fi emitikarami bura, li Oluwa wi, pe, ile yi yio di ahoro.

6 Nitori bayi li Oluwa wi fun ile ọba Juda; Gileadi ni iwọ si mi, ori Lebanoni: sibẹ, lõtọ emi o sọ ọ di aginju, ati ilu ti a kò gbe inu wọn.

7 Emi o ya awọn apanirun sọtọ fun ọ, olukuluku pẹlu ihamọra rẹ̀: nwọn o si ke aṣayan igi kedari rẹ lulẹ, nwọn o si sọ wọn sinu iná.

8 Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio rekọja lẹba ilu yi, nwọn o wi, ẹnikan fun ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti Oluwa ṣe bayi si ilu nla yi?

9 Nigbana ni nwọn o dahùn pe, nitoriti nwọn ti kọ̀ majẹmu Oluwa Ọlọrun wọn silẹ; ti nwọn fi ori balẹ fun ọlọrun miran, nwọn si sìn wọn.

Iṣẹ́ tí Jeremiah Jẹ́ Nípa Joahasi

10 Ẹ máṣe sọkun fun okú, bẹ̃ni ki ẹ máṣe pohùnrere rẹ̀, ṣugbọn ẹ sọkun ẹ̀dun fun ẹniti o nlọ, nitori kì yio pada wá mọ, kì yio si ri ilẹ rẹ̀ mọ.

11 Nitori bayi li Oluwa wi fun Ṣallumu, ọmọ Josiah, ọba Juda, ti o jọba ni ipo Josiah, baba rẹ̀, ti o jade kuro nihin pe, On kì yio pada wá mọ.

12 Ṣugbọn yio kú ni ibi ti a mu u ni igbèkun lọ, kì yio si ri ilẹ yi mọ.

Iṣẹ́ Tí Jeremiah Jẹ́ nípa Jehoiakimu

13 Egbe ni fun ẹniti o kọ́ ilẹ rẹ̀, ti kì iṣe nipa ododo, ati iyẹwu rẹ̀, ti kì iṣe nipa ẹ̀tọ́: ti o lò iṣẹ ọwọ aladugbo rẹ̀ lọfẹ, ti kò fi ere iṣẹ rẹ̀ fun u.

14 Ti o wipe, emi o kọ ile ti o ni ibò fun ara mi, ati iyẹwu nla, ti o ke oju ferese fun ara rẹ̀, ti o fi igi kedari bò o, ti o si fi ajẹ̀ kùn u.

15 Iwọ o ha jọba, nitori iwọ fi igi kedari dije? baba rẹ kò ha jẹ, kò ha mu? o si ṣe idajọ ati ododo, nitorina o dara fun u.

16 O dajọ ọ̀ran talaka ati alaini; o dara fun u: bi ãti mọ̀ mi kọ́ eyi? li Oluwa wi.

17 Ṣugbọn oju rẹ̀ ati ọkàn rẹ kì iṣe fun ohunkohun bikoṣe ojukokoro rẹ, ati lati ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, ati lati ṣe ininilara ati agbara.

18 Nitorina bayi li Oluwa wi nitori Jehoiakimu ọmọ Josiah, ọba Juda, nwọn kì yio ṣọ̀fọ fun u, wipe, Oṣe! arakunrin mi! tabi Oṣe! arabinrin mi! nwọn kì o ṣọ̀fọ fun u pe, Oṣe, oluwa! tabi Oṣe, ọlọla!

19 A o sin i ni isinkú kẹtẹkẹtẹ, ti a wọ́ ti a si sọ junù kuro ni ẹnu-bode Jerusalemu.

Iṣẹ́ Tí Jeremiah Jẹ́ nípa Ohun Tí Yóo Ṣẹlẹ̀ sí

20 Goke lọ si Lebanoni, ki o si ke, ki o si gbe ohùn rẹ soke ni Baṣani, ki o kigbe lati Abarimu, nitori a ti ṣẹ́ gbogbo olufẹ rẹ tutu,

21 Emi ti ba ọ sọ̀rọ ni ìgba ire rẹ; iwọ wipe, emi kì yio gbọ́. Eyi ni ìwa rẹ lati igba ewe rẹ wá, ti iwọ kò si gba ohùn mi gbọ.

22 Ẹfũfu yio fẹ gbogbo oluṣọ-agutan rẹ lọ, ati awọn olufẹ rẹ yio lọ si ìgbekun: nitõtọ, ni wakati na ni oju yio tì ọ, iwọ o si dãmu nitori gbogbo buburu rẹ.

23 Iwọ, olugbe Lebanoni, ti o tẹ́ itẹ si ori igi kedari, iwọ o ti jẹ otoṣi to, nigbati irora ba deba ọ, irora bi obinrin ti nrọbi!

Ìdájọ́ Ọlọrun lórí Jehoiakini

24 Bi emi ti wà, li Oluwa wi, bi Koniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, tilẹ jẹ oruka-èdidi lọwọ ọtun mi, sibẹ̀ emi o fà ọ tu kuro nibẹ.

25 Emi o si fi ọ le ọwọ awọn ti o nwá ẹmi rẹ, ati le ọwọ ẹniti iwọ bẹ̀ru rẹ̀, ani le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, ati ọwọ awọn ara Kaldea.

26 Emi o tì ọ sode, ati iya rẹ ti o bi ọ si ilẹ miran, nibiti a kò bi nyin si; nibẹ li ẹnyin o si kú.

27 Ṣugbọn ilẹ na ti ẹnyin fẹ li ọkàn nyin lati pada si, nibẹ ni ẹnyin kì o pada si mọ.

28 Ọkunrin yi, Koniah, ohun-èlo ẹlẹgan, fifọ ha ni bi? o ha dabi ohun-èlo ti kò ni ẹwà lara? ẽṣe ti a tì wọn jade, on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ti a si le wọn jade si ilẹ ti nwọn kò mọ̀?

29 Ilẹ! ilẹ! ilẹ! gbọ́ ọ̀rọ Oluwa!

30 Bayi li Oluwa wi, Ẹ kọwe pe, ọkunrin yi alailọmọ ni, ẹniti kì yio ri rere li ọjọ aiye rẹ̀: nitori ọkan ninu iru-ọmọ rẹ̀ kì yio ri rere, ti yio fi joko lori itẹ Dafidi, ti yio si fi tun jọba lori Juda.