1 Ẹrìn kiri la ita Jerusalemu ja, ki ẹ si wò nisisiyi, ki ẹ si mọ̀, ki ẹ si wakiri nibi gbigbòro rẹ̀, bi ẹ ba lè ri ẹnikan, bi ẹnikan wà ti nṣe idajọ, ti o nwá otitọ; emi o si dari ji i.
2 Bi nwọn ba si wipe, Oluwa mbẹ; sibẹ nwọn bura eke.
3 Oluwa, oju rẹ kò ha wà lara otitọ? iwọ ti lù wọn, ṣugbọn kò dùn wọn; iwọ ti run wọn, ṣugbọn nwọn kọ̀ lati gba ẹkọ: nwọn ti mu oju wọn le jù apata lọ; nwọn kọ̀ lati yipada.
4 Emi si wipe, Lõtọ talaka enia ni awọn wọnyi, nwọn kò ni oye, nitori nwọn kò mọ̀ ọ̀na Oluwa, tabi idajọ Ọlọrun wọn.
5 Emi o tọ̀ awọn ẹni-nla lọ, emi o si ba wọn sọrọ; nitori nwọn ti mọ̀ ọ̀na Oluwa, idajọ Ọlọrun wọn. Ṣugbọn awọn wọnyi ti jumọ ṣẹ́ àjaga, nwọn si ti ja ìde.
6 Nitorina kiniun lati inu igbo wa yio pa wọn, ikõko aṣálẹ̀ yio pa wọn run, ẹkùn yio mã ṣọ ilu wọn: ẹnikẹni ti o ba ti ibẹ jade li a o ya pẹrẹpẹrẹ: nitori ẹ̀ṣẹ wọn pọ̀, ati ipẹhinda wọn le.
7 Emi o ha ṣe dari eyi ji ọ? awọn ọmọ rẹ ti kọ̀ mi silẹ, nwọn si fi eyi ti kì iṣe ọlọrun bura: emi ti mu wọn bura, ṣugbọn nwọn ṣe panṣaga, nwọn si kó ara wọn jọ si ile àgbere.
8 Nwọn jẹ akọ ẹṣin ti a bọ́ rere ti nrin kiri, olukuluku nwọn nyán si aya aladugbo rẹ̀.
9 Emi kì yio ha ṣe ibẹwo nitori nkan wọnyi? li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lara iru orilẹ-ède bi eyi?
10 Ẹ goke lọ si ori odi rẹ̀, ki ẹ si parun; ṣugbọn ẹ máṣe pa a run tan: ẹ wó kùrùkúrù rẹ̀ kuro nitori nwọn kì iṣe ti Oluwa.
11 Nitori ile Israeli ati ile Juda ti huwa arekereke gidigidi si mi, li Oluwa wi.
12 Nwọn sẹ Oluwa, wipe, Kì iṣe on, ibi kò ni wá si ori wa, awa kì yio si ri idà tabi ìyan:
13 Awọn woli yio di ẹfufu, ọ̀rọ kò sì si ninu wọn: bayi li a o ṣe si wọn.
14 Nitorina bayi li Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi, nitori ẹnyin sọ ọ̀rọ yi, sa wò o, emi o sọ ọ̀rọ mi li ẹnu rẹ di iná, ati awọn enia yi di igi, yio si jo wọn run.
15 Wò o emi o mu orilẹ-ède kan wá sori nyin lati ọ̀na jijin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa wi, orilẹ-ède alagbara ni, orilẹ-ède lati igbãni wá ni, orilẹ-ède ti iwọ kò mọ̀ ede rẹ̀, bẹ̃ni iwọ kò gbọ́ eyiti o nwi.
16 Apó ọfa rẹ̀ dabi isa-okú ti a ṣi, akọni enia ni gbogbo wọn.
17 On o si jẹ ikore rẹ ati onjẹ rẹ, nwọn o jẹ awọn ọmọkunrin ati awọn ọmọbinrin rẹ, nwọn o si jẹ agbo rẹ ati ọwọ́-ẹran rẹ, nwọn o jẹ àjara rẹ ati igi ọ̀pọtọ rẹ, nwọn o fi idà sọ ilu olodi rẹ ti iwọ gbẹkẹle di ahoro.
18 Ṣugbọn li ọjọ wọnnì, li Oluwa wi, emi kì yio ṣe iparun nyin patapata.
19 Yio si ṣe, nigbati ẹnyin o wipe: Ẽṣe ti Oluwa Ọlọrun wa fi ṣe gbogbo ohun wọnyi si wa? nigbana ni iwọ o da wọn lohùn: Gẹgẹ bi ẹnyin ti kọ̀ mi, ti ẹnyin si nsìn ọlọrun ajeji ni ilẹ nyin, bẹ̃ni ẹnyin o sin alejo ni ilẹ ti kì iṣe ti nyin.
20 Kede eyi ni ile Jakobu, pokiki rẹ̀ ni Juda wipe,
21 Ẹ gbọ́ eyi nisisiyi, ẹnyin aṣiwere enia ati alailọgbọ́n; ti o ni oju, ti kò si riran, ti o ni eti ti kò si gbọ́.
22 Ẹ kò ha bẹ̀ru mi; li Oluwa wi, ẹ kì yio warìri niwaju mi, ẹniti o fi yanrin ṣe ipãla okun, opin lailai ti kò le rekọja: ìgbì rẹ̀ kọlu u, kò si le bori rẹ̀, o pariwo, ṣugbọn kò lè re e kọja?
23 Ṣugbọn enia yi ni aiya isàgun ati iṣọtẹ si, nwọn sọ̀tẹ, nwọn si lọ.
24 Bẹ̃ni nwọn kò wi li ọkàn wọn pe, Ẹ jẹ ki a bẹ̀ru Oluwa Ọlọrun wa wayi, ẹniti o fun wa ni òjo akọrọ ati arọkuro ni igba rẹ̀: ti o fi ọ̀sẹ ikore ti a pinnu pamọ fun wa.
25 Aiṣedede nyin ti yi gbogbo ohun wọnyi pada, ati ẹ̀ṣẹ nyin ti fà ohun rere sẹhin kuro lọdọ nyin.
26 Nitori lãrin enia mi ni a ri enia ìka, nwọn wò kakiri, bi biba ẹniti ndẹ ẹiyẹ, nwọn dẹ okùn nwọn mu enia.
27 Bi àgo ti o kún fun ẹiyẹ, bẹ̃ni ile wọn kún fun ẹ̀tan, nitorina ni nwọn ṣe di nla, nwọn si di ọlọrọ̀.
28 Nwọn sanra, nwọn ndán, pẹlupẹlu nwọn rekọja ni ìwa-buburu, nwọn kò ṣe idajọ, nwọn kò dajọ ọ̀ran alainibaba, ki nwọn le ri rere; nwọn kò si dajọ are awọn talaka.
29 Emi kì yio ha ṣe ibẹwò nitori nkan wọnyi, li Oluwa wi, ẹmi mi kì yio ha gbẹsan lori orilẹ-ède bi eyi?
30 Ohun iyanu ati irira li a ṣe ni ilẹ na.
31 Awọn woli sọ asọtẹlẹ eke, ati awọn alufa ṣe akoso labẹ ọwọ wọn, awọn enia mi si fẹ ki o ri bẹ̃; kini ẹnyin o si ṣe ni igbẹhin rẹ̀?