1 LI akoko na, li Oluwa wi, ni nwọn o hú egungun awọn ọba Juda ati egungun awọn ijoye, egungun awọn alufa ati egungun awọn woli, ati egungun awọn olugbe Jerusalemu kuro ninu isà wọn:
2 Nwọn o si tẹ́ wọn siwaju õrùn ati òṣupa ati gbogbo ogun ọrun, ti nwọn ti fẹ, ti nwọn si ti sìn, awọn ti nwọn si rìn tọ̀ lẹhin, ti nwọn si wá, ti nwọn si foribalẹ fun: a kì yio kó wọn jọ, bẹ̃li a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan li oju ilẹ-aiye.
3 Awon iyokù ti o kù ninu idile buburu yi yio yan kikú jù yiyè lọ: ni ibi gbogbo ti nwọn kù si, ti emi ti tì wọn jade si, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.
4 Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; enia le ṣubu li aidide mọ? tabi enia le pada, ki o má tun yipada mọ?
5 Ẽṣe ti awọn enia Jerusalemu yi sọ ipadasẹhin di ipẹhinda lailai? nwọn di ẹ̀tan mu ṣinṣin, nwọn kọ̀ lati pada.
6 Mo tẹti lélẹ, mo si gbọ́, ṣugbọn nwọn kò sọ̀rọ titọ: kò si ẹnikan ti o ronupiwada buburu rẹ̀ wipe, kili emi ṣe? gbogbo nwọn yipo li ọ̀na wọn, bi akọ-ẹṣin ti nsare gburu sinu ogun.
7 Lõtọ ẹiyẹ àkọ li oju-ọrun mọ̀ akoko rẹ̀, àdaba ati ẹiyẹ lekeleke pẹlu alapandẹ̀dẹ sọ́ igba wiwá wọn; ṣugbọn enia mi kò mọ̀ idajọ Oluwa.
8 Bawo li ẹnyin ṣe wipe, Ọlọgbọ́n ni wa, ati ofin Oluwa mbẹ lọdọ wa? sa wò o nitõtọ! kalamu eke awọn akọwe ti sọ ofin di eke.
9 Oju tì awọn ọlọgbọ́n, idamu ba wọn a si mu wọn: sa wò o, nwọn ti kọ̀ ọ̀rọ Oluwa! ọgbọ́n wo li o wà ninu wọn?
10 Nitorina ni emi o fi aya wọn fun ẹlomiran, ati oko wọn fun awọn ti yio gbà wọn: nitori gbogbo wọn, lati ẹni kekere titi o fi de enia-nla, fi ara wọn fun ojukokoro, lati woli titi de alufa, gbogbo wọn nṣe ẹ̀tan.
11 Nitoripe nwọn ti wo ipalara ọmọbinrin enia mi fẹrẹ̀ wipe, Alafia! Alafia! nigbati alafia kò si.
12 Itiju yio ba wọn nitori nwọn ti ṣe ohun irira, sibẹ nwọn kò tiju, bẹ̃ni õru itiju kò mu wọn, nitorina ni nwọn o ṣe ṣubu lãrin awọn ti o ṣubu; ni igba ibẹ̀wo wọn, a o si wó wọn lulẹ, li Oluwa wi.
13 Ni kiká emi o ká wọn jọ, li Oluwa wi, eso-àjara kì yio si mọ lori ajara, tabi eso-ọ̀pọtọ lori igi ọ̀pọtọ, ewe rẹ̀ yio si rẹ̀; nitorina ni emi o yàn awọn ti yio kọja lọ lori rẹ̀.
14 Ẽṣe ti awa joko jẹ? ẹ ko ara nyin jọ, ki ẹ si jẹ ki a wọ̀ inu ilu olodi, ki a si dakẹ sibẹ: nitori Oluwa Ọlọrun wa, ti mu wa dakẹ, o si fun wa ni omi orõro lati mu, nitori ti awa ṣẹ̀ si Oluwa.
15 Awa reti alafia, ṣugbọn kò si ireti kan, ati ìgba didá ara, si kiye si i, idamu!
16 Lati Dani ni a gbọ́ fifọn imu ẹṣin rẹ̀; gbogbo ilẹ warìri fun iro yiyan akọ-ẹṣin rẹ̀; nwọn si de, nwọn si jẹ ile run, ati eyi ti mbẹ ninu rẹ̀: ilu ati awọn ti ngbe inu rẹ̀,
17 Sa wò o, emi o ran ejo, ejo gunte si ãrin nyin, ti kì yio gbọ́ ituju, nwọn o si bu nyin jẹ, li Oluwa wi.
18 Emi iba le tù ara mi ninu, ninu ikãnu mi? ọkàn mi daku ninu mi!
19 Sa wò o, ohùn ẹkún ọmọbinrin enia mi, lati ilẹ jijina wá, Kò ha si Oluwa ni Sioni bi? ọba rẹ̀ kò ha si ninu rẹ̀? ẽṣe ti nwọn fi ere gbigbẹ ati ohun asan àjeji mu mi binu?
20 Ikore ti kọja, ẹ̀run ti pari, a kò si gba wa la!
21 Nitori ipalara ọmọbinrin enia mi li a ṣe pa mi lara; emi ṣọ̀fọ, iyanu si di mi mu.
22 Kò ha si ojiya ikunra ni Gileadi, oniṣegun kò ha si nibẹ? ẽṣe ti a kò fi ọ̀ja dì ọgbẹ́ ọmọbinrin enia mi.