1 NI ibẹrẹ ijọba Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, ni ọ̀rọ yi ti ọdọ Oluwa wá wipe;
2 Bayi li Oluwa wi, Duro ni àgbala ile Oluwa, ki o si sọ fun gbogbo ilu Juda ti o wá lati sìn ni ile Oluwa gbogbo ọ̀rọ ti mo pa laṣẹ fun ọ lati sọ fun wọn: máṣe ke ọ̀rọ kanṣoṣo kù:
3 Bi o ba jẹ pe nwọn o gbọ́, ti olukuluku yio yipada kuro li ọ̀na buburu rẹ̀, ki emi ki o le yi ọkàn pada niti ibi ti emi rò lati ṣe si wọn, nitori iṣe buburu wọn.
4 Iwọ o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi: bi ẹnyin kì yio feti si mi lati rin ninu ofin mi, ti emi ti gbe kalẹ niwaju nyin.
5 Lati gbọ́ ọ̀rọ awọn ọmọ-ọdọ mi, awọn woli, ti emi rán si nyin, ti mo ndide ni kutukutu, ti mo rán wọn; ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́.
6 Emi o si ṣe ile yi bi Ṣilo, emi o si ṣe ilu yi ni ifibu si gbogbo orilẹ-ède aiye.
7 Nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia gbọ́, bi Jeremiah ti nsọ ọ̀rọ wọnyi ni ile Oluwa.
8 O si ṣe nigbati Jeremiah pari gbogbo ọ̀rọ ti Oluwa paṣẹ fun u lati sọ fun gbogbo enia, nigbana ni awọn alufa, ati awọn woli, ati gbogbo enia di i mu wipe, kikú ni iwọ o kú!
9 Ẽṣe ti iwọ sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa wipe, Ile yi yio dabi Ṣilo, ati ilu yi yio di ahoro laini olugbe? Gbogbo enia kojọ pọ̀ tì Jeremiah ni ile Oluwa.
10 Nigbati awọn ijoye Juda gbọ́ nkan wọnyi, nwọn jade lati ile ọba wá si ile Oluwa, nwọn si joko li ẹnu-ọ̀na titun ile Oluwa.
11 Awọn alufa ati awọn woli wi fun awọn ijoye, ati gbogbo enia pe, ọkunrin yi jẹbi ikú nitoriti o sọ asọtẹlẹ si ilu yi, bi ẹnyin ti fi eti nyin gbọ́.
12 Nigbana ni Jeremiah wi fun awọn ijoye ati gbogbo enia pe, Oluwa rán mi lati sọ asọtẹlẹ gbogbo ọ̀rọ ti ẹnyin gbọ́, si ile yi ati si ilu yi.
13 Njẹ nisisiyi, ẹ tun ọ̀na nyin ati iṣe nyin ṣe, ki ẹ si gbọ́ ohùn Oluwa Ọlọrun nyin; Oluwa yio si yi ọkàn rẹ̀ pada niti ibi ti o sọ si nyin.
14 Bi o ṣe ti emi, sa wò o, emi mbẹ li ọwọ nyin: ẹ ṣe si mi, gẹgẹ bi o ti dara ti o si yẹ loju nyin.
15 Sibẹ, ẹ mọ̀ eyi daju pe, bi ẹ ba pa mi, mimu ni ẹnyin o mu ẹ̀jẹ alaiṣẹ wá sori nyin ati sori ilu yi, ati sori awọn olugbe rẹ̀: nitori li otitọ Oluwa li o rán mi si nyin lati sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi li eti nyin.
16 Nigbana ni awọn ijoye ati gbogbo enia sọ fun awọn alufa ati awọn woli pe, ọkunrin yi kò yẹ lati kú; nitoriti o sọ̀rọ fun wa li orukọ Oluwa, Ọlọrun wa.
17 Awọn ọkunrin kan ninu awọn àgba na si dide, nwọn si sọ fun gbogbo ijọ enia wipe:
18 Mikah, ara Moraṣi, ṣe woli li ọjọ Hesekiah, ọba Juda, o si wi fun gbogbo enia Juda pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: a o tulẹ Sioni fun oko, Jerusalemu yio di òkiti alapa, ati oke ile yi gẹgẹ bi ibi giga igbo.
19 Njẹ, Hesekiah, ọba Juda, ati gbogbo Juda ha pa a bi? Ẹ̀ru Oluwa kò ha bà a, kò ha bẹ Oluwa bi? Oluwa si yi ọkàn pada niti ibi ti o ti sọ si wọn; Bayi li awa iba ṣe mu ibi nla wá sori ẹmi wa?
20 Ọkunrin kan si wà ẹ̀wẹ, ti o sọ asọtẹlẹ ni orukọ Oluwa, ani Urijah, ọmọ Ṣemaiah, ara Kirjatjearimu, ti o sọ asọtẹlẹ si ilu yi, ati si ilẹ yi, gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ Jeremiah.
21 Ati nigbati Jehoiakimu, ọba, pẹlu gbogbo ọkunrin alagbara rẹ̀, ati awọn ijoye gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀, ọba nwá a lati pa; ṣugbọn nigbati Urijah gbọ́, o bẹ̀ru, o salọ o si wá si Egipti.
22 Jehoiakimu, ọba, si rán enia lọ si Egipti, ani Elnatani, ọmọ Akbori ati enia miran pẹlu rẹ̀ lọ si Egipti.
23 Nwọn si mu Urijah lati Egipti tọ Jehoiakimu ọba wá; ẹni ti o fi idà pa a, o si sọ okú rẹ̀ sinu isa-okú awọn enia lasan.
24 Bẹ̃ni ọwọ Ahikamu, ọmọ Safani mbẹ pẹlu Jeremiah, ki nwọn ki o má ba fi i le awọn enia lọwọ lati pa.