Jer 38 YCE

Wọ́n Ju Jeremiah sinu Kànga Gbígbẹ

1 NIGBANA ni Ṣefatiah, ọmọ Mattani, ati Gedaliah, ọmọ Paṣuri, ati Jukali, ọmọ Ṣelemiah, ati Paṣuri ọmọ Malkiah, gbọ́ gbogbo ọ̀rọ ti Jeremiah ti sọ fun gbogbo enia, wipe,

2 Bayi li Oluwa wi pe, ẹniti o ba joko ni ilu yi yio kú nipa idà, nipa ìyan, ati nipa àjakalẹ-àrun, ẹniti o ba si jade tọ̀ awọn ara Kaldea lọ yio yè; a o si fi ẹmi rẹ́ fun u bi ikogun, yio si yè.

3 Bayi li Oluwa wi pe, lõtọ a o fi ilu yi le ọwọ ogun ọba Babeli, ẹniti yio si kó o.

4 Awọn ijoye si sọ fun ọba pe, Jẹ ki a pa ọkunrin yi: nitori bayi li o mu ọwọ awọn ologun ti o kù ni ilu yi rọ, pẹlu ọwọ gbogbo enia, ni sisọ iru ọ̀rọ bayi fun wọn: nitori ọkunrin yi kò wá alafia awọn enia yi, bikoṣe ibi wọn.

5 Sedekiah ọba, si wipe, Wò o, on wà li ọwọ nyin, nitori ọba kò le iṣe ohun kan lẹhin nyin.

6 Nwọn si mu Jeremiah, nwọn si sọ ọ sinu iho Malkiah ọmọ Hammeleki, ti o wà li agbala ile-túbu: nwọn fi okun sọ Jeremiah kalẹ sisalẹ. Omi kò si si ninu iho na, bikoṣe ẹrẹ̀: Jeremiah si rì sinu ẹrẹ̀ na.

7 Nigbati Ebedmeleki, ara Etiopia, iwẹfa kan, ti o wà ni ile ọba, gbọ́ pe, nwọn fi Jeremiah sinu iho: ọba joko nigbana li ẹnu-bode Benjamini;

8 Ebedmeleki si jade lati ile ọba lọ, o si sọ fun ọba wipe,

9 Oluwa mi, ọba! awọn ọkunrin wọnyi ti ṣe ibi ni gbogbo eyi ti nwọn ti ṣe si Jeremiah woli pe, nwọn ti sọ ọ sinu iho; ebi yio si fẹrẹ pa a kú ni ibi ti o gbe wà: nitori onjẹ kò si mọ ni ilu.

10 Nigbana ni ọba paṣẹ fun Ebedmeleki, ara Etiopia, wipe, Mu ọgbọ̀n enia lọwọ lati ihin lọ, ki o si fà Jeremiah soke lati inu iho, ki o to kú.

11 Ebedmeleki si mu awọn enia na pẹlu rẹ̀, o si lọ si ile ọba labẹ iyara iṣura, o si mu akisa ati oṣuka lati ibẹ wá, o si fi okùn sọ̀ wọn kalẹ si Jeremiah ninu iho.

12 Ebedmeleki, ara Etiopia, si sọ fun Jeremiah pe, Fi akisa ati oṣuka wọnyi si abẹ abia rẹ, lori okùn. Jeremiah si ṣe bẹ̃.

13 Bẹ̃ni nwọn fi okùn fà Jeremiah soke, nwọn si mu u goke lati inu iho wá: Jeremiah si wà ni agbala ile-tubu.

Sedekiah Bèèrè Ìmọ̀ràn lọ́wọ́ Jeremiah

14 Nigbana ni Sedekiah, ọba, ranṣẹ, o mu Jeremiah woli, wá sọdọ rẹ̀ si ẹnu-ọ̀na kẹta ti o wà ni ile Oluwa: ọba si wi fun Jeremiah pe, Emi o bi ọ lere ohun kan: máṣe fi nkankan pamọ fun mi.

15 Jeremiah si wi fun Sedekiah pe, Bi emi ba sọ fun ọ, iwọ kì o ha pa mi nitõtọ? bi mo ba si fi imọran fun ọ, iwọ kì yio fetisi ti emi.

16 Sedekiah, ọba, si bura nikọkọ fun Jeremiah, wipe, Bi Oluwa ti wà, ẹni ti o da ẹmi wa yi, emi kì yio pa ọ, bẹ̃ni emi kì yio fi ọ le ọwọ awọn ọkunrin wọnyi, ti nwá ẹmi rẹ.

17 Nigbana ni Jeremiah sọ fun Sedekiah pe; Bayi li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi pe: Bi iwọ o ba jade nitõtọ tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni ọkàn rẹ yio yè, a ki yio si fi iná kun ilu yi; iwọ o si yè ati ile rẹ.

18 Ṣugbọn bi iwọ kì yio ba jade tọ awọn ijoye ọba Babeli lọ, nigbana ni a o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, nwọn o si fi iná kun u, iwọ kì yio si sala kuro li ọwọ wọn.

19 Sedekiah ọba, si sọ fun Jeremiah pe, Ẹ̀ru awọn ara Juda ti o ya tọ awọn ara Kaldea mbà mi, ki nwọn ki o má ba fi mi le wọn lọwọ; nwọn a si fi mi ṣẹsin.

20 Ṣugbọn Jeremiah wipe, nwọn kì yio si fi ọ le wọn lọwọ, emi bẹ̀ ọ, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa ti mo sọ fun ọ: yio si dara fun ọ, ọkàn rẹ yio si yè.

21 Ṣugbọn bi iwọ ba kọ̀ lati jade lọ, eyi li ohun ti Oluwa ti fi hàn mi:

22 Si wò o, gbogbo awọn obinrin ti o kù ni ile ọba Juda li a o mu tọ̀ awọn ijoye ọba Babeli lọ, awọn obinrin wọnyi yio si wipe, Awọn ọrẹ rẹ ti tàn ọ jẹ, nwọn si ti bori rẹ: ẹsẹ rẹ̀ rì sinu ẹrẹ̀ wayi, nwọn pa ẹhin dà.

23 Nwọn o si mu gbogbo awọn aya rẹ ati awọn ọmọ rẹ jade tọ awọn ara Kaldea lọ: iwọ kì yio si sala kuro li ọwọ wọn, ọwọ ọba Babeli yio si mu ọ: iwọ o si mu ki nwọn ki o fi iná kun ilu yi.

24 Sedekiah si wi fun Jeremiah pe, Máṣe jẹ ki ẹnikan mọ̀ niti ọ̀rọ wọnyi, ki iwọ má ba kú.

25 Ṣugbọn bi awọn ijoye ba gbọ́ pe emi ti ba ọ sọ̀rọ, bi nwọn ba si wá sọdọ rẹ, ti nwọn sọ fun ọ pe, Sọ fun wa nisisiyi eyi ti iwọ ti sọ fun ọba, máṣe fi pamọ fun wa, awa kì o si pa ọ; ati eyi ti ọba sọ fun ọ pẹlu:

26 Nigbana ni ki iwọ ki o wi fun wọn pe, Emi mu ẹ̀bẹ mi wá siwaju ọba, pe ki o má mu mi pada lọ si ile Jonatani, lati kú sibẹ.

27 Gbogbo awọn ijoye si tọ̀ Jeremiah wá, nwọn bi i lere: o si sọ fun wọn gẹgẹ bi gbogbo ọ̀rọ wọnyi ti ọba ti palaṣẹ fun u. Bẹ̃ni nwọn dakẹ nwọn si jọ̃rẹ̀; nitori ẹnikan kò gbọ́ ọ̀ran na.

28 Jeremiah si ngbe agbala ile-túbu titi di ọjọ ti a kó Jerusalemu.