Jer 12 YCE

1 ALARE ni iwọ, Oluwa, nigbati mo mba ọ wijọ: sibẹ, jẹ ki emi ba ọ sọ ti ọ̀ran idajọ: ẽtiṣe ti ãsiki mbẹ ni ọ̀na enia buburu, ti gbogbo awọn ti nṣe ẹ̀tan jẹ alailewu.

2 Iwọ ti gbìn wọn, nwọn si ti ta gbòngbo: nwọn dagba, nwọn si nso eso: iwọ sunmọ ẹnu wọn, o si jìna si ọkàn wọn.

3 Ṣugbọn iwọ, Oluwa, mọ̀ mi: iwọ ri mi, o si dan ọkàn mi wò bi o ti ri si ọ: pa wọn mọ bi agutan fun pipa, ki o si yà wọn sọtọ fun ọjọ pipa.

4 Yio ti pẹ to ti ilẹ yio fi ma ṣọ̀fọ, ati ti ewe igbẹ gbogbo yio rẹ̀ nitori ìwa-buburu awọn ti mbẹ ninu rẹ̀? ẹranko ati ẹiyẹ nṣòfò nitori ti nwọn wipe, on kì o ri ẹ̀hin wa.

5 Bi iwọ ba ba ẹlẹsẹ rìn, ti ãrẹ si mu ọ, iwọ o ha ti ṣe ba ẹlẹṣin dije? ati pẹlu ni ilẹ alafia, bi iwọ ba ni igbẹkẹle, kini iwọ o ṣe ninu ẹkún odò Jordani?

6 Nitori pẹlupẹlu, awọn arakunrin rẹ, ati ile baba rẹ, awọn na ti hùwa ẹ̀tan si ọ, lõtọ, awọn na ti ho le ọ: Má gbẹkẹle wọn, bi nwọn tilẹ ba ọ sọ̀rọ daradara.

OLUWA Káàánú Àwọn Eniyan Rẹ̀

7 Emi ti kọ̀ ile mi silẹ, mo ti fi ogún mi silẹ; mo ti fi olufẹ ọ̀wọn ọkàn mi le ọta rẹ̀ lọwọ.

8 Ogún mi di kiniun ninu igbo fun mi; on kigbe soke si mi; nitorina ni mo ṣe korira rẹ̀.

9 Ogún mi di ẹranko ọ̀wawa fun mi, ẹranko yi i kakiri, ẹ lọ, ẹ ko gbogbo ẹran igbẹ jọ pọ̀, ẹ mu wọn wá jẹ.

10 Ọ̀pọlọpọ oluṣọ-agutan ba ọgba ajara mi jẹ, nwọn tẹ ipin oko mi mọlẹ labẹ ẹsẹ wọn, nwọn ti sọ ipin oko mi ti mo fẹ di aginju ahoro.

11 Nwọn ti sọ ọ di ahoro, o ṣọ̀fọ fun mi bi ahoro: gbogbo ilẹ ti di ahoro, nitori ti kò si ẹnikan ti o rò li ọkàn rẹ̀.

12 Awọn abanijẹ ti gori gbogbo ibi giga wọnni ni ọ̀dan, nitori idà Oluwa yio pa lati ikangun de ikangun ekeji ilẹ na, alafia kò si fun gbogbo alãye.

13 Nwọn ti gbin alikama, ṣugbọn nwọn o ka ẹ́gun, nwọn ti fi irora ẹ̀dun mu ara wọn, ṣugbọn nwọn kì yio ri anfani: ki oju ki o tì nyin nitori ère nyin, nitori ibinu gbigbona Oluwa.

Ìlérí OLUWA fún Àwọn Aládùúgbò Israẹli

14 Bayi li Oluwa wi si gbogbo awọn aladugbo buburu mi ti nwọn fi ọwọ kan ogún mi ti mo ti mu enia mi, Israeli, jogun. Sa wò o, emi o fa wọn tu kuro ni ilẹ wọn, emi o si fà ile Juda tu kuro larin wọn.

15 Yio si ṣe, nigba ti emi o ti fà wọn tu kuro tan, emi o pada, emi o si ni iyọ́nu si wọn, emi o si tun mu wọn wá, olukuluku wọn, si ogún rẹ̀, ati olukuluku si ilẹ rẹ̀.

16 Yio si ṣe, bi nwọn ba ṣe ãpọn lati kọ́ ìwa enia mi, lati fi orukọ mi bura pe, Oluwa mbẹ: gẹgẹ bi nwọn ti kọ́ enia mi lati fi Baali bura; nigbana ni a o gbe wọn ró lãrin enia mi.

17 Ṣugbọn bi nwọn kì o gbọ́, emi o fà orilẹ-ède na tu patapata; emi o si pa wọn run, li Oluwa wi.