Jer 15 YCE

Ìparun Yóo Dé Bá Àwọn Ọmọ Juda

1 OLUWA si wi fun mi pe, Bi Mose ati Samueli duro niwaju mi, sibẹ inu mi kì yio si yipada si awọn enia yi: ṣá wọn tì kuro niwaju mi, ki nwọn o si jade lọ.

2 Yio si ṣe, nigbati nwọn ba wi fun ọ pe, nibo ni awa o jade lọ? ki iwọ ki o sọ fun wọn pe, Bayi li Oluwa wi; awọn ti ikú, si ikú, awọn ti idà, si idà; ati awọn ti ìyan, si ìyan, ati awọn ti igbèkun si igbèkun.

3 Emi si fi iru ijiya mẹrin sori wọn, li Oluwa wi, idà lati pa, ajá lati wọ́ kiri, ẹiyẹ oju-ọrun ati ẹranko ilẹ, lati jẹ, ati lati parun.

4 Emi o si fi wọn fun iwọsi ni gbogbo ijọba aiye, nitori Manasse, ọmọ Hesekiah, ọba Juda, nitori eyiti o ti ṣe ni Jerusalemu.

5 Nitori tani yio ṣãnu fun ọ, iwọ Jerusalemu? tabi ti yio sọkun rẹ? tabi tani yio wá lati bere alafia rẹ.

6 Iwọ ti kọ̀ mi silẹ, li Oluwa wi, iwọ ti pada sẹhin; nitorina emi o ná ọwọ mi si ọ, emi o si pa ọ run; ãrẹ̀ mu mi lati ṣe iyọnu.

7 Emi o fi atẹ fẹ́ wọn si ẹnu-ọ̀na ilẹ na; emi o pa awọn ọmọ wọn, emi o si pa enia mi run, ẹniti kò yipada kuro ninu ọ̀na rẹ̀.

8 Awọn opo rẹ̀ o di pipọ ju iyanrin eti okun: emi o mu arunni wa sori wọn, sori iyá ati ọdọmọkunrin li ọjọkanri; emi o mu ifoya ati ìbẹru nla ṣubu lu wọn li ojiji.

9 Ẹniti o bi meje nṣọ̀fọ o si jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ; õrùn rẹ̀ wọ̀ l'ọsan, oju ntì i, o si ndamu: iyoku ninu wọn l'emi o si fifun idà niwaju awọn ọta wọn, li Oluwa wi.

Jeremiah Ráhùn sí OLUWA

10 Egbe ni fun mi, iyá mi, ti o bi mi ni ọkunrin ija ati ijiyan gbogbo aiye! emi kò win li elé, bẹ̃ni enia kò win mi li elé; sibẹ gbogbo wọn nfi mi ré.

11 Oluwa ni, Emi kì o tú ọ silẹ fun rere! emi o mu ki ọta ki o bẹ̀ ọ ni ìgba ibi ati ni ìgba ipọnju!

12 A ha le ṣẹ irin, irin ariwa, ati idẹ bi?

13 Ohun-ini ati iṣura rẹ li emi o fi fun ijẹ, li aigbowo, nitori gbogbo ẹ̀ṣẹ rẹ ni àgbegbe rẹ.

14 Emi o si mu ki awọn ọta rẹ kó wọn lọ si ilẹ ti iwọ kò mọ̀: nitoriti iná njo ni ibinu mi, ti yio jo lori rẹ.

15 Oluwa, iwọ mọ̀, ranti mi, bẹ̀ mi wò, ki o si gbẹsan mi lara awọn oninunibini mi! máṣe mu mi kuro nitori ipamọra rẹ: mọ̀ pe, mo ti jiya itiju nitori rẹ!

16 Nigbati a ri ọ̀rọ rẹ, emi si jẹ wọn, ọ̀rọ rẹ si jẹ inu didùn mi, nitori orukọ rẹ li a fi npè mi, iwọ Oluwa, Ọlọrun awọn ọmọ-ogun!

17 Emi kò joko ni ajọ awọn ẹlẹgan! ki emi si ni ayọ̀; mo joko emi nikan, nitori ọwọ rẹ: nitori iwọ ti fi ibanujẹ kún mi.

18 Ẽṣe ti irora mi pẹ́ titi, ati ọgbẹ mi jẹ alaiwotan, ti o kọ̀ lati jina? lõtọ iwọ si dabi kanga ẹ̀tan fun mi, bi omi ti kò duro?

19 Nitorina, bayi li Oluwa wi, Bi iwọ ba yipada, nigbana li emi o si tun mu ọ pada wá, iwọ o si duro niwaju mi: bi iwọ ba si yà eyi ti iṣe iyebiye kuro ninu buburu, iwọ o dabi ẹnu mi: nwọn o si yipada si ọ; ṣugbọn iwọ máṣe yipada si wọn.

20 Emi o si ṣe ọ fun awọn enia yi bi odi idẹ ati alagbara: nwọn o si ba ọ jà, ṣugbọn nwọn kì yio le bori rẹ, nitori emi wà pẹlu rẹ, lati gbà ọ là ati lati gbà ọ silẹ, li Oluwa wi.

21 Emi o si gba ọ silẹ kuro lọwọ awọn enia buburu, emi o si rà ọ pada kuro lọwọ awọn ìka.