1 EGBE ni fun awọn oluṣọ-agutan, ti nmu agbo-ẹran mi ṣìna, ti o si ntú wọn ka, li Oluwa wi.
2 Nitorina bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi si oluṣọ-agutan wọnni, ti nṣọ enia mi; Ẹnyin tú agbo-ẹran mi ká, ẹ le wọn junù, ẹnyin kò si bẹ̀ wọn wò, sa wò o, emi o bẹ̀ nyin wò nitori buburu iṣe nyin, li Oluwa wi.
3 Emi o si kó iyokù agbo-ẹran mi jọ lati inu gbogbo ilẹ, ti mo ti le wọn si, emi o si mu wọn pada wá sinu pápá oko wọn, nwọn o bi si i, nwọn o si rẹ̀ si i.
4 Emi o gbe oluṣọ-agutan dide fun wọn, ti yio bọ́ wọn: nwọn kì yio bẹ̀ru mọ́, tabi nwọn kì yio si dãmu, bẹ̃li ọkan ninu wọn kì yio si sọnu, li Oluwa wi.
5 Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.
6 Li ọjọ rẹ̀ ni a o gba Juda là, Israeli yio si ma gbe li ailewu, ati eyi li orukọ ti a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.
7 Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti nwọn kì yio tun wipe, Oluwa mbẹ, ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti:
8 Ṣugbọn pe, Oluwa mbẹ, ti o mu iru-ọmọ ile Israeli wá, ti o si tọ́ wọn lati ilu ariwa wá, ati lati ilu wọnni nibi ti mo ti lé wọn si, nwọn o si gbe inu ilẹ wọn.
9 Si awọn woli. Ọkàn mi ti bajẹ ninu mi, gbogbo egungun mi mì; emi dabi ọmuti, ati ọkunrin ti ọti-waini ti bori rẹ̀ niwaju Oluwa, ati niwaju ọ̀rọ ìwa-mimọ́ rẹ̀.
10 Nitori ilẹ na kún fun awọn panṣaga; ilẹ na nṣọ̀fọ, nitori egún, pápá oko aginju gbẹ: irìn wọn di buburu, agbara wọn kò si to.
11 Nitori, ati woli ati alufa, nwọn bajẹ; pẹlupẹlu ninu ile mi ni mo ri ìwa-buburu wọn, li Oluwa wi.
12 Nitorina ipa-ọ̀na wọn yio jẹ fun wọn bi ibi yiyọ́ li okunkun: a o tì wọn, nwọn o si ṣubu ninu rẹ̀, nitori emi o mu ibi wá sori wọn, ani ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi.
13 Emi si ti ri were ninu awọn woli Samaria, nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ Baali, nwọn si mu Israeli enia mi ṣina.
14 Emi ti ri irira lara awọn woli Jerusalemu, nwọn ṣe panṣaga, nwọn si rìn ninu eke, nwọn mu ọwọ oluṣe-buburu le tobẹ̃, ti kò si ẹnikan ti o yipada kuro ninu ìwa-buburu rẹ̀; gbogbo wọn dabi Sodomu niwaju mi, ati awọn olugbe rẹ̀ bi Gomorra.
15 Nitorina bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi niti awọn woli; Sa wò o, emi o fi wahala bọ́ wọn, emi o si jẹ ki nwọn ki o mu omi orõro: nitori lati ọdọ awọn woli Jerusalemu ni ibajẹ ti jade lọ si gbogbo ilẹ na.
16 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Ẹ máṣe feti si ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin: nwọn sọ nyin di asan, nwọn sọ̀rọ iran inu ara wọn, kì iṣe lati ẹnu Oluwa.
17 Nwọn wi sibẹ fun awọn ti o ngàn mi pe, Oluwa ti wi pe, Alafia yio wà fun nyin; nwọn si wi fun olukuluku ti o nrìn nipa agidi ọkàn rẹ̀, pe, kò si ibi kan ti yio wá sori nyin.
18 Nitori tali o duro ninu igbimọ Oluwa, ti o woye, ti o si gbọ́ ọ̀rọ rẹ̀? tali o kíyesi ọ̀rọ rẹ̀, ti o si gbà a gbọ́?
19 Sa wò o, afẹfẹ-ìji Oluwa! ibinu ti jade! afẹyika ìji yio ṣubu ni ikanra si ori awọn oluṣe buburu:
20 Ibinu Oluwa kì yio pada, titi yio fi ṣe e, titi yio si fi mu iro inu rẹ̀ ṣẹ, li ọjọ ikẹhin ẹnyin o mọ̀ ọ daju.
21 Emi kò ran awọn woli wọnyi, ṣugbọn nwọn sare: emi kò ba wọn sọ̀rọ, ṣugbọn nwọn sọ asọtẹlẹ.
22 Ibaṣepe nwọn duro ni imọran mi, nwọn iba jẹ ki enia mi ki o gbọ́ ọ̀rọ mi, nigbana ni nwọn iba yipada kuro ni ọ̀na buburu wọn, ati kuro ninu buburu iṣe wọn.
23 Emi ha iṣe Ọlọrun itosi? li Oluwa wi, kì iṣe Ọlọrun lati okere pẹlu?
24 Ẹnikẹni le fi ara rẹ̀ pamọ ni ibi ìkọkọ, ti emi kì yio ri i, li Oluwa wi. Emi kò ha kún ọrun on aiye, li Oluwa wi?
25 Emi ti gbọ́ eyiti awọn woli sọ, ti nwọn sọ asọtẹlẹ li orukọ mi wi pe, Mo lá alá! mo lá alá!
26 Yio ti pẹ to, ti eyi yio wà li ọkàn awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ eke? ani, awọn alasọtẹlẹ ẹ̀tan ọkàn wọn.
27 Ti nwọn rò lati mu ki enia mi ki o gbàgbe orukọ mi nipa alá wọn ti nwọn nrọ́, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀, gẹgẹ bi awọn baba wọn ti gbagbe orukọ mi nitori Baali.
28 Woli na ti o lála, jẹ ki o rọ́ ọ; ati ẹniti o ni ọ̀rọ mi, jẹ ki o fi ododo sọ ọ̀rọ mi. Kini iyangbo ni iṣe ninu ọkà, li Oluwa wi?
29 Ọ̀rọ mi kò ha dabi iná? li Oluwa wi; ati bi òlu irin ti nfọ́ apata tútu?
30 Nitorina sa wò o, emi dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti o nji ọ̀rọ mi, ẹnikini lati ọwọ ẹnikeji rẹ̀.
31 Sa wò o, emi o dojukọ awọn woli, li Oluwa wi, ti nwọn lò ahọn wọn, ti nwọn nsọ jade pe: O wi.
32 Sa wò o, emi dojukọ awọn ti o nsọ asọtẹlẹ alá èke, li Oluwa wi, ti nwọn si nrọ́ wọn, ti nwọn si mu enia mi ṣìna nipa eke wọn, ati nipa iran wọn: ṣugbọn emi kò rán wọn, emi kò si paṣẹ fun wọn: nitorina, nwọn kì yio ràn awọn enia yi lọwọ rara, li Oluwa wi.
33 Ati nigbati awọn enia yi, tabi woli, tabi alufa, yio bi ọ lere wipe, kini Ọ̀rọ-wuwo Oluwa? nigbana ni iwọ o wi fun wọn Ọ̀rọ-wuwo ni eyi pé: Emi o tì nyin jade, li Oluwa wi.
34 Ati woli, ati alufa, ati awọn enia, ti yio wipe, Ọ̀rọ-wuwo Oluwa, emi o jẹ oluwa rẹ̀ ati ile rẹ̀ ni ìya.
35 Bayi li ẹnyin o wi, ẹnikini fun ẹnikeji, ati ẹnikan fun arakunrin rẹ̀, pe Kini idahùn Oluwa? ati kini ọ̀rọ Oluwa?
36 Ẹ kì o si ranti ọ̀rọ-wuwo Oluwa mọ́, nitori ọ̀rọ olukuluku yio di ẹrù-wuwo fun ontikararẹ̀; nitori ti ẹnyin ti yi ọ̀rọ Ọlọrun alãye dà, Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun wa.
37 Bayi ni iwọ o wi fun woli nì pe: Idahùn wo li Oluwa fi fun ọ? ati pẹlu; Kini Oluwa wi?
38 Ṣugbọn bi ẹnyin ba wipe, ọ̀rọ-wuwo Oluwa, nitorina, bayi li Oluwa wi, nitori ẹnyin nsọ ọ̀rọ yi pe, ọ̀rọ-wuwo Oluwa ti emi si ranṣẹ si nyin pe ki ẹ máṣe wipe: ọ̀rọ-wuwọ Oluwa;
39 Nitorina, sa wò o, Emi o gbagbe nyin patapata, emi o si kọ̀ nyin silẹ, emi o si tì nyin jade, ati ilu ti mo fi fun nyin ati fun awọn baba nyin, kuro niwaju mi.
40 Emi o si mu ẹ̀gan ainipẹkun wá sori nyin, ati itiju lailai, ti a kì yio gbagbe.