1 O si ṣe li ọdun kanna li atetekọbẹrẹ ijọba Sedekiah, ọba Juda, li ọdun kẹrin ati oṣù karun, ti Hananiah, ọmọ Asuri woli, ti iṣe ti Gibeoni, wi fun mi ni ile Oluwa, niwaju awọn alufa ati gbogbo enia pe,
2 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, pe, Emi ti ṣẹ àjaga ọba Babeli.
3 Ninu akoko ọdun meji li emi o tun mu gbogbo ohun-èlo ile Oluwa pada wá si ibi yi, ti Nebukadnessari, ọba Babeli, kó kuro ni ibi yi, ti o si mu wọn lọ si Babeli.
4 Emi o si tun mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, pẹlu awọn igbekun Juda, ti o ti lọ si Babeli pada wá si ibi yi, li Oluwa wi, nitori emi o si ṣẹ àjaga ọba Babeli.
5 Jeremiah woli si wi fun Hananiah woli niwaju awọn alufa ati niwaju gbogbo enia, ti o duro ni ile Oluwa pe:
6 Jeremiah woli si wipe, Amin: ki Oluwa ki o ṣe bẹ̃: ki Oluwa ki o mu ọ̀rọ rẹ ti iwọ sọ asọtẹlẹ ṣẹ, lati mu ohun-elo ile Oluwa ati gbogbo igbekun pada, lati Babeli wá si ibi yi.
7 Ṣugbọn nisisiyi, iwọ gbọ́ ọ̀rọ yi ti mo sọ si eti rẹ ati si eti enia gbogbo.
8 Awọn woli ti o ti ṣaju mi, ati ṣaju rẹ ni igbãni sọ asọtẹlẹ pupọ, ati si ijọba nla niti ogun, ati ibi, ati ajakalẹ-arun.
9 Woli nì ti o sọ asọtẹlẹ alafia, bi ọ̀rọ woli na ba ṣẹ, nigbana ni a o mọ̀ woli na pe, Oluwa rán a nitõtọ.
10 Nigbana ni Hananiah woli mu àjaga kuro li ọrùn Jeremiah woli o si ṣẹ́ ẹ.
11 Hananiah si wi niwaju gbogbo enia pe, Bayi li Oluwa wi; Bẹ̃ gẹgẹ li emi o ṣẹ́ ajaga Nebukadnessari, ọba Babeli, kuro li ọrùn orilẹ-ède gbogbo ni igba ọdun meji. Jeremiah woli si ba ọ̀na tirẹ̀ lọ.
12 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ Jeremiah woli wá lẹhin igbati Hananiah woli ti ṣẹ́ ajaga kuro li ọrùn Jeremiah woli, wipe,
13 Lọ isọ fun Hananiah wipe, Bayi li Oluwa wi; Iwọ ti ṣẹ́ àjaga igi; ṣugbọn iwọ o si ṣe àjaga irin ni ipo wọn.
14 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi: emi ti fi ajaga irin si ọrùn gbogbo orilẹ-ède wọnyi, ki nwọn ki o sin Nebukadnessari, ọba Babeli, nwọn o si sin i, emi si fi ẹranko igbẹ fun u pẹlu.
15 Nigbana ni Jeremiah, woli, wi fun Hananiah, woli, pe, Gbọ́ nisisiyi, Hananiah; Oluwa kò rán ọ; ṣugbọn iwọ jẹ ki enia yi ki o gbẹkẹle eke.
16 Nitorina bayi li Oluwa wi; Sa wo o, emi o ta ọ nù kuro loju aiye: li ọdun yi ni iwọ o kú, nitori iwọ ti sọ̀rọ iṣọtẹ si Oluwa.
17 Bẹ̃ni Hananiah woli si kú li ọdun na li oṣu keje.