1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa nigbati Sedekiah, ọba, ran Paṣuru, ọmọ Melkiah, ati Sefaniah, ọmọ Maaseah, alufa, wipe,
2 Bère, emi bẹ ọ, lọdọ Oluwa fun wa; nitori Nebukadnessari, ọba Babeli, ṣi ogun tì wa; bọya bi Oluwa yio ba wa lò gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀, ki on ki o le lọ kuro lọdọ wa.
3 Nigbana ni Jeremiah wi fun wọn pe, Bayi li ẹnyin o wi fun Sedekiah.
4 Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: wõ, emi o yi ihamọra ogun ti o wà ni ọwọ nyin pada, eyiti ẹnyin nfi ba ọba Babeli, ati awọn ara Kaldea jà, ti o dotì nyin lẹhin odi, emi o kó wọn jọ si ãrin ilu yi.
5 Emi tikarami yio fi ọwọ ninà ati apa lile ba nyin jà, pẹlupẹlu ni ibinu, ati ni ikannu pẹlu ibinu nla.
6 Emi o si pa awọn olugbe ilu yi, enia pẹlu ẹranko, nwọn o ti ipa àjakalẹ-arun nlanla kú.
7 Lẹhin eyi, li Oluwa wi, emi o fi Sedekiah, ọba Juda, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn enia, ati awọn ti o kù ni ilu yi lọwọ ajakalẹ-àrun ati lọwọ idà, ati lọwọ ìyan; emi o fi wọn le Nebukadnessari, ọba Babeli lọwọ, ati le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: yio si fi oju idà pa wọn; kì yio da wọn si, bẹ̃ni kì yio ni iyọ́nu tabi ãnu.
8 Ati fun enia yi ni ki iwọ ki o wipe, Bayi li Oluwa wi; Sa wò o, emi fi ọ̀na ìye ati ọ̀na ikú lelẹ niwaju nyin.
9 Ẹniti o ba joko ninu ilu yi, yio ti ipa idà kú, ati nipa ìyan ati nipa àjakalẹ-àrun: ṣugbọn ẹniti o ba jade ti o si ṣubu si ọwọ awọn ara Kaldea ti o dó tì nyin, yio yè, ẹmi rẹ̀ yio si dabi ijẹ fun u.
10 Nitori emi ti yi oju mi si ilu yi fun ibi, kì isi iṣe fun rere, li Oluwa wi: a o fi i le ọba Babeli lọwọ, yio fi iná kun u.
11 Ati fun ile ọba Juda; Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa:
12 Ile Dafidi, Bayi li Oluwa wi, Mu idajọ ṣẹ li owurọ, ki o si gba ẹniti a lọ lọwọ gba kuro li ọwọ aninilara, ki ibinu mi ki o má ba jade bi iná, ki o má si jo ti kì o si ẹniti yio pa a, nitori buburu iṣe nyin.
13 Wò o, Emi doju kọ nyin, olugbe afonifoji, ati ti okuta pẹtẹlẹ, li Oluwa wi, ẹnyin ti o wipe, Tani yio kọlu wa? ati tani yio wọ̀ inu ibugbe wa?
14 Ṣugbọn emi o jẹ nyin niya gẹgẹ bi eso iṣe nyin, li Oluwa wi; emi o si da iná ninu igbo rẹ ki o le jo gbogbo agbegbe rẹ.