1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa li ọdun kẹwa Sedekiah, ọba Juda, eyiti o jẹ ọdun kejidilogun ti Nebukadnessari.
2 Nigbana ni ogun ọba Babeli ha Jerusalemu mọ: a si se Jeremiah woli mọ agbala ile túbu, ti o wà ni ile ọba Juda.
3 Nitori Sedekiah, ọba Judah, ti se e mọ, wipe, Ẽṣe ti iwọ sọtẹlẹ, ti o si wipe, Bayi li Oluwa wi, wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ ọba Babeli, on o si ko o;
4 Ati Sedekiah, ọba Juda, kì yio bọ́ li ọwọ awọn ara Kaldea, ṣugbọn a o fi i le ọwọ ọba Babeli, Lõtọ, yio si ba a sọ̀rọ li ojukoju, oju rẹ̀ yio si ri oju rẹ̀.
5 On o si mu Sedekiah lọ si Babeli, nibẹ ni yio si wà titi emi o fi bẹ̀ ẹ wò, li Oluwa wi; bi ẹnyin tilẹ ba awọn ará Kaldea jà, ẹnyin kì yio ṣe rere.
6 Jeremiah si wipe, ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe,
7 Wò o, Hanameeli, ọmọ Ṣallumu, ẹ̀gbọn rẹ, yio tọ̀ ọ wá, wipe, Iwọ rà oko mi ti o wà ni Anatoti: nitori titọ́ irasilẹ jẹ tirẹ lati rà a.
8 Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, si tọ̀ mi wá li agbala ile túbu gẹgẹ bi ọ̀rọ Oluwa, o si wi fun mi pe, Jọ̃, ra oko mi, ti o wà ni Anatoti, ti o wà ni ilẹ Benjamini: nitori titọ́ ogun rẹ̀ jẹ tirẹ, ati irasilẹ jẹ tirẹ; rà a fun ara rẹ. Nigbana ni mo mọ̀ pe, eyi li ọ̀rọ Oluwa.
9 Emi si rà oko na lọwọ Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ti o wà ni Anatoti, mo si wọ̀n owo fun u, ṣekeli meje ati ìwọn fadaka mẹwa.
10 Mo si kọ ọ sinu iwe, mo si di i, mo si pè awọn ẹlẹri si i, mo si wọ̀n owo na ninu òṣuwọn.
11 Mo si mu iwe rirà na eyiti a dí nipa aṣẹ ati ilana, ati eyiti a ṣi silẹ.
12 Mo si fi iwe rirà na fun Baruki, ọmọ Neriah, ọmọ Masseiah, li oju Hanameeli, ọmọ ẹ̀gbọn mi, ati niwaju awọn ẹlẹri ti o kọ orukọ wọn si iwe rirà na, niwaju gbogbo ọkunrin Juda ti o joko ni àgbala ile túbu.
13 Mo si paṣẹ fun Baruki li oju wọn wipe,
14 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wipe, Mu iwe wọnyi, iwe rirà yi, ti a dí, ati iwe yi ti a ṣi silẹ; ki o si fi wọn sinu ikoko, ki nwọn ki o le wà li ọjọ pupọ.
15 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wipe, A o tun rà ile ati oko ati ọgba-ajara ni ilẹ yi.
16 Mo si gbadura si Oluwa lẹhin igbati mo ti fi iwe rirà na fun Baruki, ọmọ Neriah, wipe,
17 A! Oluwa Ọlọrun! wò o, iwọ ti o da ọrun on aiye nipa agbara nla rẹ ati ninà apa rẹ: kò si ohun-kohun ti o ṣoro fun ọ.
18 Iwọ ṣe ãnu fun ẹgbẹgbẹrun, o si san aiṣedede awọn baba si aiya awọn ọmọ lẹhin wọn: Ọlọrun titobi, Alagbara! Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.
19 Titobi ni igbimọ, ati alagbara ni iṣe; oju rẹ ṣí si gbogbo ọ̀na awọn ọmọ enia: lati fi fun olukuluku gẹgẹ bi ọ̀na rẹ̀ ati gẹgẹ bi eso iṣe rẹ̀:
20 Ẹniti o gbe àmi ati iṣẹ-iyanu kalẹ ni Egipti, titi di oni yi, ati lara Israeli, ati lara enia miran: ti iwọ si ti ṣe orukọ fun ara rẹ, gẹgẹ bi o ti ri li oni yi.
21 Ti o si fi àmi ati iṣẹ-iyanu, ati ọwọ agbara, ati ninà apa ati ẹ̀ru nla mu Israeli enia rẹ jade ni ilẹ Egipti.
22 Ti iwọ si ti fun wọn ni ilẹ yi, eyiti iwọ bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn, ilẹ ti nṣàn fun wara ati oyin;
23 Nwọn si wá, nwọn si ni i; ṣugbọn nwọn kò gbà ohùn rẹ gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò rìn ninu ofin rẹ, nwọn kò ṣe gbogbo eyiti iwọ paṣẹ fun wọn lati ṣe: iwọ si pè gbogbo ibi yi wá sori wọn:
24 Wo o! odi ọta! nwọn sunmọ ilu lati kó o; a si fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea, ti mba a jà, niwaju idà, ati ìyan, àjakalẹ-àrun: ati ohun ti iwọ ti sọ, ṣẹ; si wò o, iwọ ri i.
25 Ṣugbọn iwọ ti sọ fun mi, Oluwa Ọlọrun! pe, Iwọ fi owo rà oko na fun ara rẹ, ki o si pe awọn ẹlẹri; sibẹ, a o fi ilu le ọwọ awọn ara Kaldea.
26 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá, wipe,
27 Wò o, emi li Oluwa, Ọlọrun gbogbo ẹran-ara: ohun kan ha wà ti o ṣòro fun mi bi?
28 Nitorina, bayi li Oluwa wi, Wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ awọn ara Kaldea, ani le ọwọ Nebukadnessari, ọba Babeli, on o si kó o:
29 Ati awọn ara Kaldea, ti mba ilu yi jà, nwọn o wá, nwọn o si tẹ iná bọ̀ ilu yi, nwọn o si kun u, ati ile, lori orule eyiti nwọn ti nrubọ turari si Baali, ti nwọn si ti ndà ẹbọ ohun mimu fun ọlọrun miran, lati mu mi binu.
30 Nitori awọn ọmọ Israeli ati awọn ọmọ Juda ti ṣe kiki ibi niwaju mi lati igba èwe wọn wá: nitori awọn ọmọ Israeli ti fi kiki iṣẹ ọwọ wọn mu mi binu, li Oluwa wi.
31 Nitori ilu yi ti jẹ ohun ibinu ati irunu fun mi lati ọjọ ti nwọn ti kọ ọ wá titi di oni yi; tobẹ̃ ti emi o mu u kuro niwaju mi.
32 Nitori gbogbo ibi awọn ọmọ Israeli, ati awọn ọmọ Juda, ti nwọn ti ṣe lati mu mi binu, awọn, awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn, ati awọn ọkunrin Juda, ati awọn olugbe Jerusalemu.
33 Nwọn si ti yi ẹhin wọn pada si mi, kì isi ṣe oju: emi kọ́ wọn, mo ndide ni kutukutu lati kọ́ wọn, sibẹ nwọn kò fetisilẹ lati gbà ẹkọ.
34 Nwọn si gbe ohun irira wọn ka inu ile na, ti a fi orukọ mi pè, lati sọ ọ di aimọ́.
35 Nwọn si kọ́ ibi giga Baali, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati fi awọn ọmọkunrin wọn ati awọn ọmọbinrin wọn fun Moleki; ti emi kò paṣẹ fun wọn, bẹ̃ni kò wá si ọkàn mi, pe ki nwọn ki o mã ṣe ohun irira yi, lati mu Juda ṣẹ̀.
36 Njẹ nisisiyi, bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ilu yi, sipa eyiti ẹnyin wipe, A o fi le ọwọ ọba Babeli, nipa idà, ati nipa ìyan, ati nipa ajakalẹ-arun.
37 Wò o, emi o kó wọn jọ lati gbogbo ilẹ jade, nibiti emi ti le wọn si ninu ibinu mi, ati ninu irunu mi, ati ninu ikannu nla; emi o si jẹ ki nwọn ki o mã gbe lailewu:
38 Nwọn o si jẹ enia mi, emi o si jẹ Ọlọrun wọn.
39 Emi o si fun wọn li ọkàn kan, ati ọ̀na kan, ki nwọn ki o le bẹ̀ru mi li ọjọ gbogbo, fun rere wọn, ati ti awọn ọmọ wọn lẹhin wọn:
40 Emi o si ba wọn dá majẹmu aiyeraiye, pe emi kì o yipada lẹhin wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o fi ibẹ̀ru mi si ọkàn wọn, ti nwọn kì o lọ kuro lọdọ mi.
41 Lõtọ, emi o yọ̀ lori wọn lati ṣe wọn ni rere, emi o si gbìn wọn si ilẹ yi li otitọ tinutinu mi ati tọkàntọkàn mi.
42 Nitori bayi li Oluwa wi; Gẹgẹ bi emi ti mu gbogbo ibi nla yi wá sori awọn enia yi, bẹ̃ni emi o mu gbogbo rere ti emi ti sọ nipa ti wọn wá sori wọn.
43 Enia o si rà oko ni ilẹ yi, nipa eyi ti ẹnyin wipe, Ahoro ni laisi enia, laisi ẹran, a fi le ọwọ awọn ara Kaldea.
44 Enia yio fi owo rà oko, nwọn o kọ ọ sinu iwe, nwọn o si dí i, nwọn o si pe awọn ẹlẹri ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda, ati ni ilu ọwọ́-oke na, ati ni ilu afonifoji, ati ni ilu iha gusu; nitori emi o mu igbekun wọn pada wá, li Oluwa wi.