1 Ọ̀RỌ Jeremiah, ọmọ Hilkiah, ọkan ninu awọn alufa ti o wà ni Anatoti, ni ilẹ Benjamini.
2 Ẹniti ọ̀rọ Oluwa tọ̀ wá ni igba ọjọ Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, li ọdun kẹtala ijọba rẹ̀.
3 O si tọ̀ ọ wá pẹlu ni igba ọjọ Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, titi de opin ọdun kọkanla Sedekiah, ọmọ Josiah, ọba Juda, ani de igba ti a kó Jerusalemu lọ ni igbekun li oṣu karun.
4 Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ̀ mi wá wipe:
5 Ki emi ki o to dá ọ ni inu, emi ti mọ̀ ọ, ki iwọ ki o si to ti inu jade wá li emi ti sọ ọ di mimọ́, emi si yà ọ sọtọ lati jẹ́ woli fun awọn orilẹ-ède.
6 Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun! sa wò o, emi kò mọ̀ ọ̀rọ isọ nitori ọmọde li emi.
7 Ṣugbọn Oluwa wi fun mi pe, má wipe, ọmọde li emi: ṣugbọn iwọ o lọ sọdọ ẹnikẹni ti emi o ran ọ si, ati ohunkohun ti emi o paṣẹ fun ọ ni iwọ o sọ.
8 Má bẹ̀ru niwaju wọn nitori emi wà pẹlu rẹ lati gbà ọ: li Oluwa wi.
9 Oluwa si nà ọwọ rẹ̀, o fi bà ẹnu mi; Oluwa si wi fun mi pe, sa wò o, emi fi ọ̀rọ mi si ọ li ẹnu.
10 Wò o, li oni yi ni mo fi ọ ṣe olori awọn orilẹ-ède, ati olori ijọba wọnni, lati fàtu, ati lati fà lulẹ; lati parun, ati lati wó lulẹ; lati kọ́, ati lati gbìn.
11 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe, Jeremiah, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ọpa igi almondi.
12 Oluwa si wi fun mi pe, iwọ riran rere, nitori ti emi o kiye si ọ̀rọ mi lati mu u ṣẹ.
13 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá lẹ̃keji pe, kini iwọ ri? emi si wipe, mo ri ìkoko ori iná, oju rẹ̀ si ni lati iha ariwa wá.
14 Nigbana ni Oluwa sọ fun mi pe, ibi yio tú jade lati ariwa wá, sori gbogbo awọn ti ngbe inu ilẹ.
15 Sa wò o, Emi o pè gbogbo idile awọn ijọba ariwa, li Oluwa wi, nwọn o si wá: olukuluku wọn o si tẹ́ itẹ rẹ̀ li ẹnu-bode Jerusalemu, ati lori gbogbo odi rẹ̀ yikakiri, ati lori gbogbo ilu Juda.
16 Emi o si sọ̀rọ idajọ mi si wọn nitori gbogbo buburu wọn; ti nwọn ti kọ̀ mi silẹ, ti nwọn ti sun turari fun ọlọrun miran, ti nwọn si tẹriba fun iṣẹ ọwọ wọn.
17 Ṣugbọn iwọ di ẹ̀gbẹ́ rẹ li amure, ki o si dide, ki o si wi fun wọn gbogbo ohun ti emi o pa laṣẹ fun ọ, má fòya niwaju wọn, ki emi ki o má ba mu ọ dãmu niwaju wọn.
18 Sa wò o, loni ni mo fi ọ ṣe ilu-odi, ati ọwọ̀n irin, ati odi idẹ fun gbogbo ilẹ; fun awọn ọba Juda, awọn ijoye rẹ̀, awọn alufa, ati enia ilẹ na.
19 Ṣugbọn nwọn o ba ọ jà, nwọn kì o si le bori rẹ; nitori emi wà pẹlu rẹ, li Oluwa wi, lati gbà ọ.