1 SEDEKIAH jẹ ẹni ọdun mọkanlelogun nigbati o bẹrẹ si ijọba, o si jọba, ọdun mọkanla ni Jerusalemu. Orukọ iya rẹ̀ si ni Hamutali, ọmọbinrin Jeremiah, ara Libna.
2 On si ṣe buburu niwaju Oluwa, gẹgẹ bi gbogbo eyiti Jehoiakimu ti ṣe.
3 Nitori ibinu Oluwa, o ri bẹ̃ ni Jerusalemu ati Juda, titi o fi tì wọn jade kuro niwaju rẹ̀. Sedekiah si ṣọtẹ si ọba Babeli.
4 O si ṣe li ọdun kẹsan ijọba rẹ̀, li oṣu kẹwa, li ọjọ kẹwa oṣu, Nebukadnessari, ọba Babeli de, on ati gbogbo ogun rẹ̀ si Jerusalemu, o si dó tì i, o si mọdi tì i yikakiri.
5 A si há ilu na mọ titi di ọdun ikọkanla Sedekiah ọba.
6 Ati li oṣu kẹrin li ọjọ kẹsan oṣu, ìyan mu gidigidi ni ilu, tobẹ̃ ti kò si onjẹ fun awọn enia ilẹ na.
7 Nigbana ni a fọ ilu, gbogbo awọn ologun si sá, nwọn si jade ni ilu li oru, nwọn gba ọ̀na ẹnu ibode ãrin odi meji, ti o wà li ẹba ọgbà ọba, ṣugbọn awọn ara Kaldea yi ilu ka: nwọn si jade lọ li ọ̀na pẹtẹlẹ.
8 Ṣugbọn ogun awọn ara Kaldea lepa ọba, nwọn si ba Sedekiah ni pẹtẹlẹ Jeriko, gbogbo ogun rẹ̀ si tuka kuro lọdọ rẹ̀.
9 Nwọn si mu ọba, nwọn si mu u goke wá si ọdọ ọba Babeli ni Ribla, ni ilẹ Hamati; o si sọ̀rọ idajọ lori rẹ̀.
10 Ọba Babeli si pa awọn ọmọ Sedekiah niwaju rẹ̀: o pa gbogbo awọn ọlọla Juda pẹlu ni Ribla.
11 Pẹlupẹlu ọba Babeli fọ Sedekiah li oju; o si fi ẹ̀wọn dè e, o si mu u lọ si Babeli, o si fi sinu tubu titi di ọjọ ikú rẹ̀.
12 Njẹ li oṣu karun, li ọjọ kẹwa oṣu, ti o jẹ ọdun kọkandilogun Nebukadnessari, ọba Babeli, ni Nebusaradani, balogun iṣọ, ti o nsin ọba Babeli, wá si Jerusalemu.
13 O si kun ile Oluwa, ati ile ọba; ati gbogbo ile Jerusalemu, ati gbogbo ile nla li o fi iná sun.
14 Ati gbogbo ogun awọn ara Kaldea, ti nwọn wà pẹlu balogun iṣọ, wó gbogbo odi Jerusalemu lulẹ yikakiri.
15 Nebusaradani, balogun iṣọ, si kó ninu awọn talaka awọn enia, ati iyokù awọn enia ti o kù ni ilu, ni igbekun lọ si Babeli, pẹlu awọn ti o ya lọ, ti o si ya tọ̀ ọba Babeli lọ, ati iyokù awọn ọ̀pọ enia na.
16 Nebusaradani, balogun iṣọ, si fi ninu awọn talaka ilẹ na silẹ lati mã ṣe alabojuto ajara ati lati ma ṣe alaroko.
17 Ati ọwọ̀n idẹ wọnni ti mbẹ lẹba ile Oluwa, ati ijoko wọnni ati agbada idẹ nla ti o wà ni ile Oluwa ni awọn ara Kaldea fọ tũtu, nwọn si kó gbogbo idẹ wọn lọ si Babeli.
18 Ati ìkoko wọnni, ati ọkọ́ wọnni, ati alumagaji fitila wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ṣibi wọnni, ati gbogbo ohun elo idẹ wọnni ti nwọn fi nṣiṣẹ isin, ni nwọn kó lọ.
19 Ati awo-koto wọnni, ati ohun ifọnna wọnni, ati ọpọ́n wọnni, ati ìkoko wọnni, ati ọpa fitila wọnni, ati ṣibi wọnni, ati ago wọnni, eyiti iṣe ti wura, wura, ati eyiti iṣe ti fadaka, fadaka, ni balogun iṣọ kó lọ.
20 Awọn ọwọ̀n meji, agbada nla kan, ati awọn malu idẹ mejila ti o wà labẹ ijoko, ti Solomoni ọba, ti ṣe fun ile Oluwa: idẹ gbogbo ohun-elo wọnyi alaini iwọ̀n ni.
21 Ati ọwọ̀n mejeji, giga ọwọ̀n kan ni igbọnwọ mejidilogun; okùn igbọnwọ mejila si yi i ka; ninipọn wọn si jẹ ika mẹrin, nwọn ni iho ninu.
22 Ati ọna-ori idẹ wà lori rẹ̀; giga ọna-ori kan si ni igbọnwọ marun, pẹlu iṣẹ wiwun ati pomegranate lara ọna ori wọnni yikakiri, gbogbo rẹ̀ jẹ ti idẹ: gẹgẹ bi wọnyi ni ọwọ̀n ekeji pẹlu, ati pomegranate rẹ̀.
23 Pomegranate mẹrindilọgọrun li o wà ni gbangba: gbogbo pomegranate lori iṣẹ wiwun na jẹ ọgọrun yikakiri.
24 Balogun iṣọ si mu Seraiah, olori ninu awọn alufa, ati Sefaniah, alufa keji, ati awọn oluṣọ iloro mẹta:
25 Ati lati inu ilu o mu iwẹfa kan, ti o ni itọju awọn ologun; ati awọn ọkunrin meje ti nwọn nduro niwaju ọba, ti a ri ni ilu na; ati akọwe olori ogun ẹniti ntò awọn enia ilẹ na; ati ọgọta enia ninu awọn enia ilẹ na, ti a ri li ãrin ilu na.
26 Nebusaradani, balogun iṣọ, si mu wọn, o si mu wọn tọ̀ ọba Babeli wá si Ribla.
27 Ọba Babeli si kọlu wọn, o si pa wọn ni Ribla ni ilẹ Hamati. Bẹ̃li a mu Juda kuro ni ilẹ rẹ̀.
28 Eyi li awọn enia ti Nebukadnessari kó ni ìgbekun lọ: li ọdun keje, ẹgbẹdogun o le mẹtalelogun ara Juda.
29 Li ọdun kejidilogun Nebukadnessari, o kó ẹgbẹrin enia o le mejilelọgbọn ni igbèkun lati Jerusalemu lọ:
30 Li ọdun kẹtalelogun Nebukadnessari, Nebusaradani, balogun iṣọ, kó ọtadilẹgbẹrin enia o di marun awọn ara Juda ni igbekun lọ: gbogbo awọn enia na jẹ ẹgbẹtalelogun.
31 O si ṣe, li ọdun kẹtadilogoji Jehoiakimu, ọba Juda, li oṣu kejila, li ọjọ kẹdọgbọn oṣu, Efil-Merodaki, ọba Babeli, li ọdun ekini ijọba rẹ̀, o gbe ori Jehoiakimu, ọba Juda, soke, o si mu u jade ninu ile túbu.
32 O si sọ̀rọ rere fun u, o si gbe itẹ rẹ̀ ga jù itẹ awọn ọba ti o wà pẹlu rẹ̀ ni Babeli.
33 O si parọ aṣọ túbu rẹ̀: o si njẹun nigbagbogbo niwaju rẹ̀ ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.
34 Ati ipin onjẹ rẹ̀, ipin onjẹ igbagbogbo, ti ọba Babeli nfi fun u lojojumọ ni ipin tirẹ̀, titi di ọjọ ikú rẹ̀, ni gbogbo ọjọ aiye rẹ̀.