Jer 25 YCE

Àwọn Ọ̀tá láti Ìhà Àríwá

1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá nitori gbogbo enia Juda, li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọbà Juda, ti iṣe ọdun ikini Nebukadnessari, ọba Babeli.

2 Eyi ti Jeremiah, woli, sọ fun gbogbo enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe:

3 Lati ọdun kẹtala Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, titi di oni-oloni, eyini ni, ọdun kẹtalelogun, ọ̀rọ Oluwa ti tọ mi wá, emi si ti sọ fun nyin, emi ndide ni kutukutu, emi nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i.

4 Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́.

5 Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai.

6 Ki ẹ má si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma foribalẹ fun wọn, ki ẹ má si ṣe fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, emi kì yio si ṣe nyin ni ibi.

7 Ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ temi, li Oluwa wi, ki ẹnyin le fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu si ibi ara nyin.

8 Nitorina, bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitori ti ẹnyin kò gbọ́ ọ̀rọ mi.

9 Sa wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu gbogbo idile orilẹ-ède ariwa wá, li Oluwa wi, emi o si ranṣẹ si Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi, emi o si mu wọn wá si ilẹ yi, ati olugbe rẹ̀, ati si gbogbo awọn orilẹ-ède yikakiri, emi o si pa wọn patapata, emi o si sọ wọn di iyanu ati iyọṣuti si, ati ahoro ainipẹkun.

10 Pẹlupẹlu emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, iro okuta ọlọ, ati imọlẹ fitila kuro lọdọ wọn.

11 Gbogbo ilẹ yi yio si di iparun ati ahoro: orilẹ-ède wọnyi yio si sìn ọba Babeli li ãdọrin ọdun.

12 Yio si ṣe, nigbati ãdọrin ọdun ba pari tan, li emi o bẹ̀ ọba Babeli, ati orilẹ-ède na, ati ilẹ awọn ara Kaldea wò, nitori ẹ̀ṣẹ wọn; li Oluwa wi, emi o si sọ ọ di ahoro titi lai.

13 Emi o si mu gbogbo ọ̀rọ mi wá sori ilẹ na, ti mo ti sọ si i: ani gbogbo eyiti a ti kọ sinu iwe yi, eyiti Jeremiah ti sọtẹlẹ si gbogbo orilẹ-ède.

14 Nitoriti awọn wọnyi pẹlu yio mu ki orilẹ-ède pupọ, ati awọn ọba nla sìn wọn: emi o san a fun wọn gẹgẹ bi iṣe wọn ati pẹlu gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn.

Ìdájọ́ OLUWA lórí Àwọn Orílẹ̀-èdè náà

15 Nitori bayi ni Oluwa Ọlọrun Israeli wi fun mi: Gba ago ọti-waini ibinu mi yi kuro lọwọ mi, ki o si jẹ ki gbogbo orilẹ-ède ti emi o rán ọ si, mu u.

16 Ki nwọn mu, ki nwọn si ma ta gbọ̀ngbọn, ki nwọn si di aṣiwere, nitori idà ti emi o rán si ãrin wọn.

17 Nigbana ni mo gba ago na li ọwọ Oluwa, emi si jẹ ki gbogbo orilẹ-ède, ti Oluwa rán mi si, mu u.

18 Ani Jerusalemu ati ilu Juda wọnni, ati awọn ọba wọn pẹlu awọn ijoye, lati sọ wọn di ahoro, idãmu, ẹsin, ati egún, gẹgẹ bi o ti ri loni.

19 Farao, ọba Egipti, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀, ati gbogbo enia rẹ̀.

20 Ati gbogbo awọn enia ajeji, ati gbogbo ọba ilẹ Usi, gbogbo ọba ilẹ Filistia, ati Aṣkeloni, ati Gasa, ati Ekroni, ati awọn iyokù Aṣdodi,

21 Edomu, ati Moabu, ati awọn ọmọ Ammoni,

22 Ati gbogbo awọn ọba Tire, ati gbogbo awọn ọba Sidoni, ati awọn ọba erekuṣu wọnni ti mbẹ ni ikọja okun,

23 Dedani, ati Tema, ati Busi, ati gbogbo awọn ti nda òṣu.

24 Ati gbogbo awọn ọba Arabia, pẹlu awọn ọba awọn enia ajeji ti ngbe inu aginju.

25 Ati gbogbo awọn ọba Simri, ati gbogbo awọn ọba Elamu, ati gbogbo awọn ọba Medea.

26 Ati gbogbo awọn ọba ariwa, ti itosi ati ti ọ̀na jijin, ẹnikini pẹlu ẹnikeji rẹ̀, ati gbogbo ijọba aiye, ti mbẹ li oju aiye, ọba Ṣeṣaki yio si mu lẹhin wọn.

27 Iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi, Ẹ mu, ki ẹ si mu amuyo, ki ẹ bì, ki ẹ si ṣubu, ki ẹ má si le dide mọ́, nitori idà ti emi o rán sãrin nyin.

28 Yio si ṣe, bi nwọn ba kọ̀ lati gba ago lọwọ rẹ lati mu, ni iwọ o si wi fun wọn pe: Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, ni mimu ẹnyin o mu!

29 Sa wò o, nitori ti emi bẹrẹ si imu ibi wá sori ilu na ti a pè li orukọ mi, ẹnyin fẹ ijẹ alaijiya? ẹnyin kì yio ṣe alaijiya: nitori emi o pè fun idà sori gbogbo olugbe aiye, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.

30 Njẹ iwọ sọ asọtẹlẹ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun wọn, ki o si wi fun wọn pe, Oluwa yio kọ lati oke wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ lati ibugbe rẹ̀ mimọ́, ni kikọ, yio kọ sori ibugbe rẹ̀, yio pariwo sori gbogbo olugbe aiye, bi awọn ti ntẹ ifunti.

31 Igbe kan yio wá titi de opin ilẹ aiye; nitori Oluwa ni ijà ti yio ba awọn orilẹ-ède ja, yio ba gbogbo ẹran-ara wijọ, yio fi awọn oluṣe-buburu fun idà, li Oluwa wi.

32 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, sa wò o, ibi yio jade lati orilẹ-ède de orilẹ-ède, ìji nlanla yio ru soke lati agbegbe aiye.

33 Awọn ti Oluwa pa yio wà li ọjọ na lati ipẹkun kini aiye titi de ipẹkun keji aiye, a kì yio ṣọ̀fọ wọn, a kì yio ko wọn jọpọ, bẹ̃ni a kì yio sin wọn, nwọn o di àtan lori ilẹ.

34 Ke! ẹnyin oluṣọ-agutan! ki ẹ si sọkun! ẹ fi ara nyin yilẹ ninu ẽru, ẹnyin ọlọla agbo-ẹran! nitori ọjọ a ti pa nyin ati lati tú nyin ka pe, ẹnyin o si ṣubu bi ohun-elo iyebiye.

35 Sisa kì yio si fun awọn oluṣọ-agutan, bẹ̃ni asalà kì yio si fun awọn ọlọla agbo-ẹran.

36 Ohùn ẹkun awọn oluṣọ-agutan, ati igbe awọn ọlọla agbo-ẹran li a o gbọ́: nitori Oluwa bà papa-oko tutu wọn jẹ.

37 Ibùgbe alafia li o di ahoro, niwaju ibinu kikan Oluwa.

38 O ti fi pantiri rẹ̀ silẹ bi kiniun nitori ti ilẹ wọn di ahoro, niwaju ibinu idà aninilara, ati niwaju ibinu kikan rẹ̀.