1 NJẸ Paṣuri, ọmọ Immeri, alufa, ti iṣe olori olutọju ni ile Oluwa, gbọ́ pe, Jeremiah sọ asọtẹlẹ ohun wọnyi.
2 Nigbana ni Paṣuri lù Jeremiah, woli, o si kàn a li àba ti o wà ni ẹnu-ọ̀na Benjamini, ti o wà li òke ti o wà lẹba ile Oluwa.
3 O si ṣe ni ọjọ keji, Paṣuri mu Jeremiah kuro ninu àba. Nigbana ni Jeremiah wi fun u pe, Oluwa kò pe orukọ rẹ ni Paṣuri (ire-yika-kiri), bikoṣe Magori-missa-bibu (idãmu-yika-kiri.)
4 Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ọ le idãmu lọwọ, pẹlu gbogbo awọn ọrẹ rẹ, nwọn o ṣubu nipa idà awọn ọta wọn, oju rẹ yio si ri i, emi o si fi gbogbo Juda le ọwọ ọba Babeli, on o si mu wọn lọ ni igbèkun si Babeli, yio si fi idà pa wọn.
5 Pẹlupẹlu emi o fi ọrọ̀ ilu yi, pẹlu ẽre rẹ̀ ati ohun iyebiye rẹ̀, ati gbogbo iṣura awọn ọba Juda li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ti yio jẹ wọn ti yio si mu wọn lọ si Babeli.
6 Ati iwọ, Paṣuri, ati gbogbo awọn ti o ngbe inu ile rẹ ni yio lọ si igbekun, iwọ o wá si Babeli, ati nibẹ ni iwọ o kú si, a o si sin ọ sibẹ, iwọ ati gbogbo ọrẹ rẹ ti iwọ ti sọ asọtẹlẹ eke fun.
7 Oluwa, iwọ ti fi ọ̀rọ rọ̀ mi, emi si gba rirọ̀! iwọ li agbara jù mi lọ, o si bori mi; emi di ẹni iyọ-ṣuti-si lojojumọ, gbogbo wọn ni ngàn mi!
8 Nitori lati igba ti mo ti sọ̀rọ, emi kigbe, mo ke, Iwa-agbara, ati iparun, nitori a sọ ọ̀rọ Oluwa di ohun ẹ̀gan ati itiju fun mi lojojumọ.
9 Nitorina mo si wipe, emi kì yio mu ni ranti rẹ̀, emi kì yio si sọ ọ̀rọ li orukọ rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn ọ̀rọ rẹ̀ mbẹ bi iná ti njó ninu mi ti a se mọ inu egungun mi, o si rẹ̀ mi lati pa a mọra, emi kò le ṣe e.
10 Nitoriti mo gbọ́ ẹgan ọ̀pọlọpọ, idãmu niha gbogbo, nwọn wipe: fi sùn, awa o si fi sùn. Gbogbo awọn ọrẹ mi, ati gbogbo awọn ẹgbẹ mi wipe: bọya a o tãn jẹ, awa o si ṣẹgun rẹ̀, a o si gbẹsan wa lara rẹ̀.
11 Ṣugbọn Oluwa mbẹ lọdọ mi bi akọni ẹlẹrù, nitorina awọn ti nṣe inunibini si mi yio ṣubu, nwọn kì yio le bori: oju yio tì wọn gidigidi, nitoripe nwọn kì o ṣe rere: a ki yio gbagbe itiju wọn lailai!
12 Oluwa awọn ọmọ-ogun, iwọ ti ndán olododo wò, iwọ si ri inu ati ọkàn, emi o ri ẹsan rẹ lara wọn: nitoriti mo ti fi ọ̀ran mi le ọ lọwọ!
13 Ẹ kọrin si Oluwa, ẹ yìn Oluwa, nitoriti o ti gbà ọkàn talaka kuro lọwọ awọn oluṣe buburu.
14 Egbe ni fun ọjọ na ti a bi mi! ọjọ na ti iya mi bi mi, ki o má ri ibukun!
15 Egbe ni fun ọkunrin na ti o mu ihìn tọ̀ baba mi wá, wipe, Ọmọkunrin li a bi fun ọ; o mu u yọ̀.
16 Ki ọkunrin na ki o si dabi ilu wọnni ti Oluwa ti bì ṣubu, li aiyi ọkàn pada, ki o si gbọ́ ẹkun li owurọ, ati ọ̀fọ li ọsangangan.
17 Nitoriti kò pa mi ni inu iya mi, tobẹ̃ ki iya mi di isà mi, ki o loyun mi lailai.
18 Ẽṣe ti emi fi jade kuro ninu iya mi, lati ri irora ati oṣi, ati lati pari ọjọ mi ni itiju?