1 SI Moabu. Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Egbe ni fun Nebo! nitoriti a fi ṣe ijẹ: oju tì Kiriataimu, a si kó o: oju tì Misgabu, o si wariri.
2 Ogo Moabu kò si mọ: nwọn ti gbero ibi si i ni Heṣboni pe, wá, ki ẹ si jẹ ki a ke e kuro lati jẹ orilẹ-ède. A o ke ọ lulẹ pẹlu iwọ Madmeni; idà yio tẹle ọ.
3 Ohùn igbe lati Horonaimu, iparun ati idahoro nla!
4 A pa Moabu run; awọn ọmọde rẹ̀ mu ki a gbọ́ igbe.
5 Nitori ẹkun tẹle ẹkun ni ọ̀na igoke lọ si Luhiti: nitori ni ọ̀na isọkalẹ Horonaimu a gbọ́ imi-ẹ̀dun, igbe iparun, pe:
6 Ẹ sa, ẹ gbà ẹmi nyin là, ki ẹ si dabi alaini li aginju!
7 Njẹ nitoriti iwọ ti gbẹkẹle iṣẹ ọwọ rẹ ati le iṣura rẹ, a o si kó iwọ pẹlu: Kemoṣi yio si jumọ lọ si ìgbekun, pẹlu awọn alufa rẹ̀, ati awọn ijoye rẹ̀.
8 Awọn oluparun yio wá sori olukuluku ilu, ilu kan kì o si bọ́: afonifoji pẹlu yio ṣegbe, a o si pa pẹtẹlẹ run, gẹgẹ bi Oluwa ti wi.
9 Fi iyẹ fun Moabu, ki o ba le fò ki o si lọ, ilu rẹ̀ yio si di ahoro, laisi ẹnikan lati gbe inu rẹ̀.
10 Ifibu li ẹniti o ṣe iṣẹ Oluwa ni imẹlẹ, ifibu si li ẹniti o dá idà rẹ̀ duro kuro ninu ẹjẹ.
11 Moabu ti wà ni irọra lati igba ewe rẹ̀ wá, o si ti silẹ lori gẹdẹgẹdẹ̀ bi ọtiwaini, a kò si ti dà a lati inu ohun-elo, de ohun-elo bẹ̃ni kò ti ilọ si igbekun: nitorina itọwò rẹ̀ wà ninu rẹ̀, õrun rẹ̀ kò si pada.
12 Nitorina, wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, ti emi o rán awọn atẹni-sapakan si i, ti o si tẹ̀ ẹ sapakan, nwọn o si sọ gbogbo ohun-elo rẹ̀ di ofo, nwọn o si fọ ìgo wọn.
13 Moabu yio si tiju nitori Kemoṣi, gẹgẹ bi ile Israeli ti tiju nitori Beteli, igbẹkẹle wọn.
14 Ẹnyin ha ṣe wipe, akọni ọkunrin ni awa, alagbara fun ogun?
15 A fi Moabu ṣe ijẹ, ẽfin ilu rẹ̀ si goke lọ, awọn àṣayan ọdọmọkunrin rẹ̀ si sure lọ si ibi pipa, li Ọba wi, ẹniti orukọ rẹ̀ ijẹ, Oluwa awọn ọmọ-ogun.
16 Wahala Moabu sunmọ tosi lati de, ipọnju rẹ̀ si nyara kánkan.
17 Gbogbo ẹnyin ti o wà yi i ka, ẹ kedaro rẹ̀; ati gbogbo ẹnyin ti o mọ̀ orukọ rẹ̀, ẹ wipe, bawo li ọpa agbara rẹ fi ṣẹ́, ọpa ogo!
18 Iwọ olugbe ọmọbinrin Diboni, sọkalẹ lati inu ogo, ki o si ma gbe ibi ongbẹ; nitori afiniṣe-ijẹ. Moabu yio goke wá sori rẹ, yio si pa ilu olodi rẹ run.
19 Iwọ olugbe Aroeri! duro lẹba ọ̀na, ki o si wò; bere lọwọ ẹniti nsa, ati ẹniti nsala, wipe, Kili o ṣe?
20 Oju tì Moabu: nitori a wó o lulẹ: ẹ hu, ki ẹ si kigbe; ẹ kede rẹ̀ ni Arnoni pe: a fi Moabu ṣe ijẹ,
21 Idajọ si ti de sori ilẹ pẹtẹlẹ; sori Holoni, ati sori Jahasi, ati sori Mefaati,
22 Ati sori Diboni, ati sori Nebo, ati sori Bet-diblataimu.
23 Ati sori Kiriataimu, ati sori Bet-Gamuli, ati sori Bet-Meoni,
24 Ati sori Kerioti, ati sori Bosra, ati sori gbogbo ilu ilẹ Moabu, lokere ati nitosi.
25 A ke iwo Moabu kuro, a si ṣẹ́ apá rẹ̀, li Oluwa wi.
26 Ẹ mu u yo bi ọmuti: nitori o gberaga si Oluwa: Moabu yio si ma pàfọ ninu ẽbi rẹ̀; on pẹlu yio si di ẹni-ẹ̀gan.
27 Kò ha ri bẹ̃ pe: Israeli jẹ ẹni ẹlẹyà fun ọ bi? bi ẹnipe a ri i lãrin awọn ole? nitori ni igbakũgba ti iwọ ba nsọ̀rọ rẹ̀, iwọ a ma mì ori rẹ.
28 Ẹnyin olugbe Moabu! ẹ fi ilu wọnni silẹ, ki ẹ si mã gbe inu apata, ki ẹ si jẹ gẹgẹ bi oriri ti o kọ́ itẹ rẹ̀ li ẹba ẹnu ihò.
29 Awa ti gbọ́ igberaga Moabu, o gberaga pupọ, iṣefefe rẹ̀, ati afojudi rẹ̀, ati igberaga rẹ̀, ati giga ọkàn rẹ̀.
30 Emi mọ̀ ìwa igberaga rẹ̀; li Oluwa wi: ṣugbọn kò ri bẹ̃; ọ̀rọ asan rẹ̀, ti kò le ṣe nkankan.
31 Nitorina ni emi o hu fun Moabu, emi o si kigbe soke fun gbogbo Moabu, lori awọn ọkunrin Kirheresi li a o ṣọ̀fọ.
32 Emi o sọkun fun àjara Sibma jù ẹkùn Jaseri lọ: ẹka rẹ ti rekọja okun lọ, nwọn de okun Jaseri: afiniṣe-ijẹ yio kọlu ikore eso rẹ ati ikore eso-àjara rẹ.
33 Ati ayọ̀ ati ariwo inu-didùn li a mu kuro li oko, ati kuro ni ilẹ Moabu; emi si ti mu ki ọti-waini tán ninu ifunti: ẹnikan kì o fi ariwo tẹ̀ ọti-waini; ariwo ikore kì yio jẹ ariwo ikore mọ.
34 Lati igbe Heṣboni de Eleale, de Jahasi, ni nwọn fọ ohùn wọn, lati Soari de Horonaimu, ti iṣe ẹgbọrọ malu ọlọdun mẹta, nitori omi Nimrimu pẹlu yio dahoro.
35 Emi o si mu ki o dopin ni Moabu, li Oluwa wi: ẹniti o nrubọ ni ibi giga, ati ẹniti nsun turari fun oriṣa rẹ̀.
36 Nitorina ni ọkàn mi ró fun Moabu bi fère, ọkàn mi yio si ró bi fere fun awọn ọkunrin Kirheresi: nitori iṣura ti o kojọ ṣegbe.
37 Nitori gbogbo ori ni yio pá, ati gbogbo irungbọn li a o ke kù: ọgbẹ yio wà ni gbogbo ọwọ, ati aṣọ-ọ̀fọ ni ẹgbẹ mejeji.
38 Ẹkún nlanla ni yio wà lori gbogbo orule Moabu, ati ni ita rẹ̀: nitori emi ti fọ́ Moabu bi ati ifọ́ ohun-elo, ti kò wù ni, li Oluwa wi.
39 Ẹ hu, pe, bawo li a ti wo o lulẹ! bawo ni Moabu ti fi itiju yi ẹhin pada! bẹ̃ni Moabu yio di ẹ̀gan ati idãmu si gbogbo awọn ti o yi i kakiri.
40 Nitori bayi li Oluwa wi; Wò o, on o fò gẹgẹ bi idi, yio si nà iyẹ rẹ̀ lori Moabu.
41 A kó Kerioti, a si kó awọn ilu olodi, ati ọkàn awọn akọni Moabu li ọjọ na yio dabi ọkàn obinrin ninu irọbi rẹ̀.
42 A o si pa Moabu run lati má jẹ orilẹ-ède, nitoripe o ti gberaga si Oluwa.
43 Ẹ̀ru, ati ọ̀fin, ati okùn-didẹ, yio wà lori rẹ iwọ olugbe Moabu, li Oluwa wi.
44 Ẹniti o ba sa fun ẹ̀ru yio ṣubu sinu ọ̀fin; ati ẹniti o ba jade kuro ninu ọ̀fin ni a o mu ninu okùn-didẹ: nitori emi o mu wá sori rẹ̀, ani sori Moabu, ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi.
45 Awọn ti o sá, duro li aini agbara labẹ ojiji Heṣboni: ṣugbọn iná yio jade wá lati Heṣboni, ati ọwọ-iná lati ãrin Sihoni, yio si jẹ ilẹ Moabu run, ati agbari awọn ọmọ ahoro.
46 Egbe ni fun ọ, iwọ Moabu! orilẹ-ède Kemoṣi ṣegbe: nitori a kó awọn ọkunrin rẹ ni igbekun, ati awọn ọmọbinrin rẹ ni igbekun.
47 Sibẹ emi o tun mu igbekun Moabu pada li ọjọ ikẹhin, li Oluwa wi. Titi de ihin ni idajọ Moabu.