1 Ọ̀RỌ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá lẹ̃keji, nigbati a si se e mọ ninu agbala ile túbu, wipe,
2 Bayi li Oluwa wi, ẹniti o ṣe e, Oluwa, ti o pinnu rẹ̀, lati fi idi rẹ̀ mulẹ; Oluwa li orukọ rẹ̀;
3 Képe mi, emi o si da ọ lohùn, emi o si fi ohun nla ati alagbara han ọ ti iwọ kò mọ̀.
4 Nitori bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi, niti ile ilu yi, ati niti ile awọn ọba Juda ti a wó lulẹ ati nitori odi ati nitori idà;
5 Nwọn wá lati ba awọn ara Kaldea jà, ṣugbọn lati fi okú enia kún wọn, awọn ẹniti Emi pa ninu ibinu mi ati ninu irunu mi, ati nitori gbogbo buburu wọnni, nitori eyiti emi ti pa oju mi mọ fun ilu yi.
6 Wò o, emi o fi ọjá ati õgùn imularada dì i, emi o si wò wọn san, emi o si fi ọ̀pọlọpọ alafia ati otitọ hàn fun wọn.
7 Emi o si mu igbèkun Juda ati igbèkun Israeli pada wá, emi o si gbe wọn ró gẹgẹ bi ti iṣaju.
8 Emi o si wẹ̀ wọn nù kuro ninu gbogbo aiṣedede wọn, nipa eyiti nwọn ti ṣẹ̀ si mi; emi o si dari gbogbo aiṣedede wọn jì nipa eyiti nwọn ti sẹ̀, ati nipa eyi ti nwọn ti ṣe irekọja si mi.
9 Ilu na yio si jẹ orukọ ayọ̀ fun mi, iyìn ati ọlá niwaju gbogbo orilẹ-ède ilẹ aiye, ti nwọn gbọ́ gbogbo rere ti emi ṣe fun wọn: nwọn o si bẹ̀ru, nwọn o si warìri, nitori gbogbo ore ati nitori gbogbo alafia ti emi ṣe fun u.
10 Bayi li Oluwa wi; A o si tun gbọ́ ni ibi yi ti ẹnyin wipe, O dahoro, laini enia ati laini ẹran, ani ni ilu Juda, ati ni ilu Jerusalemu, ti o dahoro, laini enia, ati laini olugbe, ati laini ẹran.
11 Ohùn ayọ̀, ati ohùn inu-didùn, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, ohùn awọn ti o wipe, Ẹ fi ọpẹ fun Oluwa awọn ọmọ-ogun: nitori ti o ṣeun, nitoriti ãnu rẹ̀ duro lailai: ati ti awọn ti o mu ẹbọ-ọpẹ́ wá si ile Oluwa. Nitoriti emi o mu igbèkun ilẹ na pada wá gẹgẹ bi atetekọṣe, li Oluwa wi.
12 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe; Papa-oko awọn oluṣọ-agutan yio tun wà, ti nwọn mu ẹran-ọsin dubulẹ ni ibi yi, ti o dahoro, laini enia ati laini ẹran, ati ni gbogbo ilu rẹ̀!
13 Ninu ilu oke wọnni, ninu ilu afonifoji, ati ninu ilu iha gusu, ati ni ilẹ Benjamini, ati ni ibi wọnni yi Jerusalemu ka, ati ni ilu Juda ni agbo agutan yio ma kọja labẹ ọwọ ẹniti nkà wọn, li Oluwa wi.
14 Wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o mu ohun rere na, ti emi ti leri fun ilẹ Israeli ati fun ile Juda, ṣẹ.
15 Li ọjọ wọnni, ati li akoko na, emi o jẹ ki Ẹka ododo ki o hu soke fun Dafidi; ẹniti yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.
16 Li ọjọ wọnni li a o gbà Juda la, Jerusalemu yio si ma gbe li ailewu: orukọ yi li a o ma pè e: OLUWA ODODO WA.
17 Nitori bayi li Oluwa wi; A kì o fẹ ọkunrin kan kù lọdọ Dafidi lati joko lori itẹ́ ile Israeli lailai.
18 Bẹ̃ni awọn alufa, awọn ọmọ Lefi, kì yio fẹ ọkunrin kan kù niwaju mi lati ru ẹbọ sisun, ati lati dana ọrẹ ohun jijẹ, ati lati ṣe irubọ lojojumọ.
19 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá, wipe,
20 Bayi li Oluwa wi; Bi ẹnyin ba le bà majẹmu mi ti ọsan jẹ, ati majẹmu mi ti oru, tí ọsan ati oru kò le si li akoko wọn;
21 Nigbana ni majẹmu mi pẹlu Dafidi, iranṣẹ mi le bajẹ, pe ki on ki o má le ni ọmọ lati joko lori itẹ rẹ̀; ati pẹlu awọn ọmọ Lefi, awọn alufa, awọn iranṣẹ mi.
22 Gẹgẹ bi a kò ti le ka iye ogun-ọrun, tabi ki a le wọ̀n iyanrin eti okun: bẹ̃ni emi o sọ iru-ọmọ Dafidi iranṣẹ mi di pupọ, ati awọn ọmọ Lefi, ti nṣe iranṣẹ fun mi.
23 Ọ̀rọ Oluwa si tọ Jeremiah wá, wipe,
24 Iwọ kò ha ro eyi ti awọn enia yi ti sọ wipe, Idile meji ti Oluwa ti yàn, o ti kọ̀ wọn silẹ̀? nitorina ni nwọn ti ṣe kẹgan awọn enia mi, pe nwọn kì o le jẹ orilẹ-ède kan mọ li oju wọn.
25 Bayi li Oluwa wi, Bi emi kò ba paṣẹ majẹmu mi ti ọsan ati ti oru, pẹlu ilana ọrun ati aiye,
26 Nigbana ni emi iba ta iru-ọmọ Jakobu nù, ati Dafidi, iranṣẹ mi, ti emi kì o fi mu ninu iru-ọmọ rẹ̀ lati ṣe alakoso lori iru-ọmọ Abrahamu, Isaaki, ati Jakobu: nitori emi o mu ki igbekun wọn ki o pada bọ̀, emi o si ṣãnu fun wọn.