Jer 10 YCE

Ìbọ̀rìṣà ati Ìjọ́sìn Tòótọ́

1 Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ti Oluwa sọ fun nyin, ẹnyin ile Israeli:

2 Bayi li Oluwa wi, Ẹ máṣe kọ́ ìwa awọn keferi, ki àmi ọrun ki o má si dãmu nyin, nitoripe, nwọn ndamu awọn orilẹ-ède.

3 Nitori asan ni ilana awọn orilẹ-ède; nitori igi ti a ke lati igbo ni iṣẹ ọwọ oniṣọna ati ti ãke.

4 Nwọn fi fádaka ati wura ṣe e lọṣọ, nwọn fi iṣo ati olù dì i mu, ki o má le mì.

5 Nwọn nàro bi igi ọpẹ, ṣugbọn nwọn kò fọhùn: gbigbe li a ngbe wọn, nitori nwọn kò le rin. Má bẹ̀ru wọn; nitori nwọn kò le ṣe buburu, bẹ̃li ati ṣe rere, kò si ninu wọn.

6 Kò si ẹnikan ti o dabi Iwọ Oluwa! iwọ tobi, orukọ rẹ si tobi ni agbara!

7 Tani kì ba bẹ̀ru rẹ, Iwọ Ọba orilẹ-ède? nitori tirẹ ni o jasi; kò si ninu awọn ọlọgbọ́n orilẹ-ède, ati gbogbo ijọba wọn, kò si ẹniti o dabi Iwọ!

8 Ṣugbọn nwọn jumọ ṣe ope ati aṣiwere; ìti igi ni ẹkọ́ ohun asan.

9 Fadaka ti a fi ṣe awo ni a mu lati Tarṣiṣi wá, ati wura lati Upasi wá, iṣẹ oniṣọna, ati lọwọ alagbẹdẹ: alaro ati elese aluko ni aṣọ wọn: iṣẹ ọlọgbọ́n ni gbogbo wọn.

10 Ṣugbọn Oluwa, Ọlọrun otitọ ni, on ni Ọlọrun alãye, ati Ọba aiyeraiye! aiye yio warìri nigbati o ba binu, orilẹ-ède kì yio le duro ni ibinu rẹ̀.

11 Bayi li ẹnyin o wi fun wọn pe: Awọn ọlọrun ti kò da ọrun on aiye, awọn na ni yio ṣegbe loju aiye, ati labẹ ọrun wọnyi.

Orin Ìyìn sí Ọlọrun

12 On ti da aiye nipa agbara rẹ̀, on ti pinnu araiye nipa ọgbọ́n rẹ̀, o si nà awọn ọrun nipa oye rẹ̀.

13 Nigbati o ba sán ãrá, ọ̀pọlọpọ omi ni mbẹ loju-ọrun, o si jẹ ki kũku rú soke lati opin aiye; o da mànamana fun òjo, o si mu ẹfũfu jade lati inu iṣura rẹ̀ wá.

14 Aṣiwere ni gbogbo enia nitori oye kò si: oju tì olukuluku alagbẹdẹ niwaju ere rẹ̀, nitori ère didà rẹ̀ eke ni, kò si sí ẹmi ninu rẹ̀.

15 Asan ni nwọn, ati iṣẹ iṣina: nigba ibẹwo wọn nwọn o ṣègbe.

16 Ipin Jakobu kò si dabi wọn nitori on ni iṣe Ẹlẹda ohun gbogbo; Israeli si ni ẹya ijogun rẹ̀: Oluwa awọn ọmọ-ogun li orukọ rẹ̀.

17 Ko ẹrù rẹ kuro ni ilẹ na, Iwọ olugbe ilu ti a dotì.

18 Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o gbọ̀n awọn olugbe ilẹ na nù lẹ̃kan yi, emi o si pọ́n wọn loju, ki nwọn ki o le ri i.

19 Egbe ni fun mi nitori ipalara mi! ọgbẹ mi pọ̀: ṣugbọn mo wipe, nitõtọ ìya mi ni eyi, emi o si rù u.

20 Agọ mi bajẹ, gbogbo okùn mi si ja: awọn ọmọ mi ti fi mi silẹ lọ, nwọn kò sí mọ́, kò si ẹnikan ti yio nà agọ mi mọ, ti yio si ta aṣọ ikele mi.

21 Nitori awọn oluṣọ agutan ti di ope, nwọn kò si wá Oluwa: nitorina nwọn kì yio ri rere, gbogbo agbo wọn yio si tuka.

22 Sa wò o, ariwo igbe ti de, ati irukerudo nla lati ilẹ ariwa wá, lati sọ ilu Judah di ahoro, ati iho ọwawa.

23 Oluwa! emi mọ̀ pe, ọ̀na enia kò si ni ipa ara rẹ̀: kò si ni ipá enia ti nrin, lati tọ́ iṣisẹ rẹ̀.

24 Oluwa kilọ fun mi, ṣugbon ni idajọ ni, ki o máṣe ni ibinu rẹ, ki iwọ ki o má sọ mi di asan.

25 Tu ibinu rẹ si ori awọn orilẹ-ède, ti kò mọ̀ ọ, ati sori awọn idile ti kò ke pè orukọ rẹ, nitoriti nwọn ti jẹ Jakobu run, nwọn si gbe e mì, nwọn si pa a run tan, nwọn si sọ ibugbe rẹ̀ di ahoro.