Jer 14:13-19 YCE

13 Emi si wipe, Oluwa Ọlọrun, sa wò o, awọn woli wi fun wọn pe; Ẹnyin kì yio ri idà, bẹ̃li ìyan kì yio de si nyin; ṣugbọn emi o fun nyin ni alafia otitọ ni ibi yi.

14 Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, awọn woli nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi; emi kò rán wọn, bẹ̃ni emi kò paṣẹ fun wọn, emi kò si sọ̀rọ kan fun wọn, iran eke, afọṣẹ, ati ohun asan, ati ẹ̀tan inu wọn, ni awọn wọnyi sọtẹlẹ fun nyin.

15 Nitorina bayi li Oluwa wi niti awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ li orukọ mi, ti emi kò rán; sibẹ nwọn wipe, Idà ati ìyan kì yio wá sori ilẹ yi; nipa idà, pẹlu ìyan, ni awọn woli wọnyi yio ṣegbe.

16 Ati awọn enia ti nwọn nsọ asọtẹlẹ fun ni a o lù bolẹ ni ita Jerusalemu, nitori ìyan ati idà, nwọn kì yio ri ẹniti o sin wọn, awọn aya wọn, ati ọmọkunrin wọn, ati ọmọbinrin wọn: nitoriti emi o tu ìwa-buburu wọn jade sori wọn.

17 Ki iwọ ki o si sọ ọ̀rọ yi fun wọn pe: oju mi sun omije li oru ati li ọsan, kì yio si dá, nitoriti a ti ṣa wundia ọmọbinrin enia mi li ọgbẹ nla kikoro gidigidi ni lilù na.

18 Bi emi ba jade lọ si papa, sa wò o, a ri awọn ti a fi idà pa! bi emi ba si wọ inu ilu lọ, sa wò o, awọn ti npa ọ̀kakà ikú nitori iyan! nitori awọn, ati awọn woli, ati awọn alufa nwọ́ lọ si ilẹ ti nwọn kò mọ̀.

19 Iwọ ha ti kọ̀ Juda silẹ patapata? ọkàn rẹ ti korira Sioni? ẽṣe ti iwọ ti lù wa, ti imularada kò si fun wa? awa nreti alafia, kò si si rere, ati fun igba imularada, ṣugbọn wò o, idãmu!