2 Juda kãnu ati ẹnu-bode rẹ̀ wọnnì si jõro, nwọn dudu de ilẹ; igbe Jerusalemu si ti goke.
3 Awọn ọlọla wọn si ti rán awọn ọmọ wẹrẹ lọ si odò: nwọn wá si kanga, nwọn kò ri omi; nwọn pada pẹlu agbè wọn lofo, oju tì wọn, idãmu mu wọn, nwọn si bo ori wọn.
4 Nitori ilẹ, ti ndãmu gidigidi, nitoriti òjo kò si ni ilẹ, oju tì awọn àgbẹ, nwọn bo ori wọn.
5 Lõtọ abo-àgbọnrin pẹlu ni papa bimọ, o fi i silẹ nitori ti kò si koriko.
6 Ati awọn kẹtẹkẹtẹ-igbẹ duro lori oke wọnni, nwọn fọn imu si ẹfũfu bi ikõko, oju wọn rẹ̀ nitoriti kò si koriko.
7 Oluwa, bi ẹ̀ṣẹ wa ti jẹri si wa to nì, ṣe atunṣe nitori orukọ rẹ: nitoriti ipẹhinda wa pọ̀; si ọ li awa ti ṣẹ̀.
8 Iwọ, ireti Israeli, olugbala rẹ̀ ni wakati ipọnju! ẽṣe ti iwọ o dabi alejo ni ilẹ, ati bi èro ti o pa agọ lati sùn?