1 Ọ̀RỌ Oluwa tọ̀ mi wá wipe:
2 Iwọ kò gbọdọ ni aya, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ni ọmọkunrin tabi ọmọbinrin ni ihinyi.
3 Nitori bayi li Oluwa wi niti ọmọkunrin ati ọmọbinrin ti a bi ni ihinyi, ati niti awọn iya wọn ti o bi wọn, ati niti awọn baba wọn ti o bi wọn ni ilẹ yi.
4 Nwọn o kú ikú àrun; a kì yio ṣọ̀fọ wọn; bẹ̃ni a kì yio si sin wọn; nwọn o si di àtan lori ilẹ: a o fi idà ati ìyan run wọn, ati okú wọn yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ.