12 Ati pẹlu pe, ẹnyin ti ṣe buburu jù awọn baba nyin lọ: nitorina sa wò o, ẹnyin rìn olukuluku nyin, ni agidi ọkàn buburu rẹ̀, ki ẹnyin ki o má ba gbọ́ temi:
13 Emi o si ta nyin nu kuro ni ilẹ yi, sinu ilẹ ti ẹnyin kò mọ̀, ẹnyin tabi awọn baba nyin, nibẹ li ẹnyin o sin ọlọrun miran, lọsan ati loru nibiti emi kì yio ṣe oju-rere fun nyin.
14 Nitorina, sa wò o, Bayi li Oluwa wi, ọjọ mbọ̀, ti a kì o wi mọ́ pe, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade kuro ni ilẹ Egipti;
15 Ṣugbọn, Oluwa mbẹ ti o mu awọn ọmọ Israeli jade wá kuro ni ilẹ ariwa, ati kuro ni ilẹ nibiti o ti lé wọn si: emi o si tun mu wọn wá si ilẹ wọn, eyiti mo fi fun awọn baba wọn.
16 Sa wò o, emi o ran apẹja pupọ, li Oluwa wi, nwọn o si dẹ wọn: lẹhin eyini, emi o rán ọdẹ pupọ, nwọn o si dẹ wọn lati ori oke-nla gbogbo, ati ori oke kekere gbogbo, ati lati inu palapala okuta jade.
17 Nitoriti oju mi mbẹ lara ọ̀na wọn gbogbo: nwọn kò pamọ kuro niwaju mi, bẹ̃ni ẹ̀ṣẹ wọn kò farasin kuro li oju mi.
18 Li atetekọṣe, emi o san ẹsan ìwa buburu mejeji wọn, ani, ẹ̀ṣẹ wọn nitoriti nwọn ti bà ilẹ mi jẹ, nwọn ti fi okú ati ohun ẹgbin ati irira wọn kún ilẹ ini mi.