18 Li atetekọṣe, emi o san ẹsan ìwa buburu mejeji wọn, ani, ẹ̀ṣẹ wọn nitoriti nwọn ti bà ilẹ mi jẹ, nwọn ti fi okú ati ohun ẹgbin ati irira wọn kún ilẹ ini mi.
19 Oluwa, agbara mi ati ilu-odi mi! àbo mi li ọjọ ipọnju! awọn orilẹ-ède yio tọ̀ ọ wá, lati ipẹkun aiye, nwọn o si wipe, Lõtọ, awọn baba wa ti jogun eke, ohun asan, iranlọwọ kò si si ninu wọn!
20 Enia lè ma dá ọlọrun fun ara rẹ̀: nitori awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun?
21 Nitorina, sa wò o, emi o mu ki nwọn ki o mọ̀, lẹ̃kan yi, emi o si mu ki nwọn ki o mọ̀ ọwọ mi ati ipa mi; nwọn o si mọ̀ pe, orukọ mi ni JEHOFA.