4 Nwọn o kú ikú àrun; a kì yio ṣọ̀fọ wọn; bẹ̃ni a kì yio si sin wọn; nwọn o si di àtan lori ilẹ: a o fi idà ati ìyan run wọn, ati okú wọn yio di onjẹ fun ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun ẹranko ilẹ.
5 Nitori bayi li Oluwa wi, máṣe wọ inu ile ãwẹ̀, bẹ̃ni ki iwọ máṣe lọ sọ̀fọ, tabi lọ pohùnrere ẹkun wọn; nitori emi ti mu alafia mi kuro lọdọ enia yi, li Oluwa wi, ani ãnu ati iyọ́nu.
6 Ati ẹni-nla ati ẹni-kekere yio kú ni ilẹ yi, a kì yio sin wọn, bẹ̃ni nwọn kì yio fá ori wọn nitori wọn.
7 Bẹ̃ni ẹnikan kì yio bu àkara lati ṣọ̀fọ fun wọn, lati tù wọn ninu nitori okú; bẹ̃ni ẹnikan kì yio fun wọn ni ago itunu mu nitori baba wọn, tabi nitori iya wọn.
8 Iwọ kò gbọdọ lọ sinu ile àse, lati joko pẹlu wọn lati jẹ ati lati mu.
9 Nitori bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ̀, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo dakẹ ni ihinyi loju nyin ati li ọjọ nyin.
10 Yio si ṣe, nigbati iwọ o ba fi gbogbo ọ̀rọ wọnyi han enia yi, nwọn o wi fun ọ pe, Ẽṣe ti Oluwa fi sọ̀rọ gbogbo ohun buburu nla yi si wa, tabi kini aiṣedede wa? tabi ẹ̀ṣẹ kini awa da si Oluwa Ọlọrun wa?