5 Bayi li Oluwa wi: Aiṣedede wo li awọn baba nyin ri lọwọ mi ti nwọn lọ jina kuro lọdọ mi, ti nwọn si tẹle asan, ti nwọn si di enia asan?
6 Bẹ̃ni nwọn kò si wipe, nibo li Oluwa wà? ti o mu wa goke lati ilẹ Egipti wá, ti o mu wa rìn ninu iju, ninu ilẹ pẹtẹlẹ ati ihò, ninu ilẹ gbigbẹ ati ojiji ikú, ninu ilẹ ti enia kò là kọja, ati nibiti enia kò tẹdo si.
7 Emi si mu nyin wá si ilẹ ọgba-eso, lati jẹ eso rẹ̀ ati ire rẹ̀; ṣugbọn ẹnyin wọ inu rẹ̀, ẹ si ba ilẹ mi jẹ, ẹ si sọ ogún mi di ohun irira:
8 Awọn alufa kò wipe, Nibo li Oluwa wà? ati awọn ti o mu ofin lọwọ kò mọ̀ mi: awọn oluṣọ si ṣẹ̀ si mi, ati awọn woli sọ asọtẹlẹ nipa Baali, nwọn si tẹle ohun ti kò lerè.
9 Nitorina, Emi o ba nyin jà, li Oluwa wi, Emi o si ba atọmọde-ọmọ nyin jà.
10 Njẹ, ẹ kọja lọ si erekuṣu awọn ara Kittimu, ki ẹ si wò, si ranṣẹ lọ si Kedari, ki ẹ si ṣe akiyesi gidigidi, ki ẹ wò bi iru nkan yi ba mbẹ nibẹ?
11 Orilẹ-ède kan ha pa ọlọrun rẹ̀ dà? sibẹ awọn wọnyi kì iṣe ọlọrun! ṣugbọn enia mi ti yi ogo wọn pada fun eyiti kò lerè.