2 Si wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ọba Juda, ti o joko ni itẹ Dafidi, iwọ, ati awọn iranṣẹ rẹ, ati awọn enia rẹ ti o wọle ẹnu-bode wọnyi.
3 Bayi li Oluwa wi; Mu idajọ ati ododo ṣẹ, ki o si gbà ẹniti a lọ lọwọ gbà kuro lọwọ aninilara, ki o máṣe fi agbara ati ìka lò alejo, alainibaba ati opó, bẹ̃ni ki o máṣe ta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ nihinyi.
4 Nitori bi ẹnyin ba ṣe nkan yi nitõtọ, nigbana ni awọn ọba yio wọle ẹnu-bode ilu yi, ti nwọn o joko lori itẹ Dafidi, ti yio gun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati enia rẹ̀.
5 Ṣugbọn bi ẹnyin kì yio ba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, Emi fi emitikarami bura, li Oluwa wi, pe, ile yi yio di ahoro.
6 Nitori bayi li Oluwa wi fun ile ọba Juda; Gileadi ni iwọ si mi, ori Lebanoni: sibẹ, lõtọ emi o sọ ọ di aginju, ati ilu ti a kò gbe inu wọn.
7 Emi o ya awọn apanirun sọtọ fun ọ, olukuluku pẹlu ihamọra rẹ̀: nwọn o si ke aṣayan igi kedari rẹ lulẹ, nwọn o si sọ wọn sinu iná.
8 Ọ̀pọlọpọ orilẹ-ède yio rekọja lẹba ilu yi, nwọn o wi, ẹnikan fun ẹnikeji rẹ̀ pe, Ẽṣe ti Oluwa ṣe bayi si ilu nla yi?