1 SI wò o, Oluwa fi agbọn eso-ọ̀pọtọ meji hàn mi, ti a gbe kalẹ niwaju ile Oluwa, lẹhin igbati Nebukadnessari, ọba Babeli, ti mu Jekoniah, ọmọ Jehoiakimu, ọba Juda, ni ìgbekun pẹlu awọn olori Juda, pẹlu awọn gbẹna-gbẹna, ati awọn alagbẹdẹ, lati Jerusalemu, ti o si mu wọn wá si Babeli.
2 Agbọn ikini ni eso-ọ̀pọtọ daradara jù, gẹgẹ bi eso ọ̀pọtọ ti o tetekọ pọ́n: agbọn ekeji ni eso-ọ̀pọtọ ti o buruju, ti a kò le jẹ, bi nwọn ti buru tó.
3 Nigbana ni Oluwa wi fun mi pe, Kini iwọ ri, Jeremiah? Emi wipe, Eso-ọ̀pọtọ, eyi ti o dara, dara jù, ati eyi ti o buru, buru jù, tobẹ̃ ti a kò le jẹ ẹ, nitori nwọn buru jù.
4 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ mi wá wipe,
5 Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi; Gẹgẹ bi eso-ọ̀pọtọ daradara wọnyi, bẹ̃li emi o fi oju rere wò awọn ìgbekun Juda, ti emi ran jade kuro ni ibi yi lọ si ilẹ awọn ara Kaldea.