1 Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá nitori gbogbo enia Juda, li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọbà Juda, ti iṣe ọdun ikini Nebukadnessari, ọba Babeli.
2 Eyi ti Jeremiah, woli, sọ fun gbogbo enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe:
3 Lati ọdun kẹtala Josiah, ọmọ Amoni, ọba Juda, titi di oni-oloni, eyini ni, ọdun kẹtalelogun, ọ̀rọ Oluwa ti tọ mi wá, emi si ti sọ fun nyin, emi ndide ni kutukutu, emi nsọ, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i.
4 Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́.
5 Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai.