4 Oluwa si ti rán gbogbo awọn iranṣẹ rẹ̀, awọn woli si nyin, o ndide ni kutukutu lati rán wọn, ṣugbọn ẹnyin kò feti si i, bẹ̃ni ẹnyin kò tẹ eti nyin silẹ lati gbọ́.
5 Wipe, ẹ sa yipada, olukuluku kuro ni ọ̀na buburu rẹ̀, ati kuro ni buburu iṣe nyin, ẹnyin o si gbe ilẹ ti Oluwa ti fi fun nyin, ati fun awọn baba nyin lai ati lailai.
6 Ki ẹ má si tọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma foribalẹ fun wọn, ki ẹ má si ṣe fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu, emi kì yio si ṣe nyin ni ibi.
7 Ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ temi, li Oluwa wi, ki ẹnyin le fi iṣẹ ọwọ nyin mu mi binu si ibi ara nyin.
8 Nitorina, bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: nitori ti ẹnyin kò gbọ́ ọ̀rọ mi.
9 Sa wò o, emi o ranṣẹ, emi o si mu gbogbo idile orilẹ-ède ariwa wá, li Oluwa wi, emi o si ranṣẹ si Nebukadnessari, ọba Babeli, ọmọ-ọdọ mi, emi o si mu wọn wá si ilẹ yi, ati olugbe rẹ̀, ati si gbogbo awọn orilẹ-ède yikakiri, emi o si pa wọn patapata, emi o si sọ wọn di iyanu ati iyọṣuti si, ati ahoro ainipẹkun.
10 Pẹlupẹlu emi o mu ohùn inudidùn, ati ohùn ayọ, ohùn ọkọ-iyawo, ati ohùn iyawo, iro okuta ọlọ, ati imọlẹ fitila kuro lọdọ wọn.