12 Emi si wi fun Sedekiah, ọba Juda, gẹgẹ bi ọ̀rọ wọnyi, pe, Ẹ mu ọrùn nyin si abẹ àjaga ọba Babeli, ki ẹ sin i, pẹlu awọn enia rẹ̀, bẹ̃li ẹnyin o yè.
13 Ẽṣe ti ẹnyin o kú, iwọ, ati enia rẹ, nipa idà, ati ìyan, ati ajakalẹ-arun, bi Oluwa ti sọ si orilẹ-ède ti kì yio sin ọba Babeli.
14 Ẹ máṣe gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nwọn nsọ fun nyin wipe, Ẹnyin kì yio sin ọba Babeli, nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.
15 Nitori emi kò rán wọn, li Oluwa wi, ṣugbọn nwọn nsọ asọtẹlẹ eke li orukọ mi: ki emi ki o lè lé nyin jade, ki ẹ ṣegbe, ẹnyin, pẹlu awọn woli ti o sọ asọtẹlẹ fun nyin.
16 Pẹlupẹlu emi sọ fun awọn alufa ati fun gbogbo enia yi wipe, Bayi li Oluwa wi, Ẹ má gbọ́ ọ̀rọ awọn woli ti nsọ asọtẹlẹ fun nyin wipe, Sa wò o, ohun-èlo ile Oluwa li a o mu pada li aipẹ nisisiyi lati Babeli wá: nitori nwọn sọ asọtẹlẹ eke fun nyin.
17 Ẹ máṣe gbọ́ ti wọn; ẹ sin ọba Babeli, ẹ si yè: ẽṣe ti ilu yi yio fi di ahoro?
18 Ṣugbọn bi nwọn ba ṣe woli, ati bi ọ̀rọ Oluwa ba wà pẹlu wọn, jẹ ki nwọn ki o bẹbẹ lọdọ Oluwa awọn ọmọ-ogun, ki ohun-èlo iyokù ni ile Oluwa ati ni ile ọba Judah, ati ni Jerusalemu, ki nwọn ki o máṣe lọ si Babeli.