24 Ati fun Ṣemaiah ara Nehalami, ni iwọ o sọ wipe.
25 Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli wi pe, Nitoripe iwọ ti rán iwe li orukọ rẹ si gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu ati si Sefaniah, ọmọ Maaseiah, alufa, ati si gbogbo awọn alufa, wipe,
26 Oluwa ti fi ọ jẹ oyè alufa ni ipo Jehoiada, alufa, ki ẹnyin ki o lè jẹ olutọju ni ile Oluwa, nitori olukuluku aṣiwere enia, ati ẹnikẹni ti o sọ asọtẹlẹ ki iwọ ki o le fi wọn sinu tubu ati sinu àba.
27 Njẹ nisisiyi, ẽṣe ti iwọ kò ba Jeremiah ti Anatoti wi, ẹniti o nsọ asọtẹlẹ fun nyin!
28 Nitorina li o ṣe ranṣẹ si wa ni Babeli, wipe, Akoko yio pẹ: ẹ kọ́ ile, ki ẹ si ma gbe inu wọn, ẹ si gbìn ọgbà, ki ẹ ma jẹ eso wọn.
29 Sefaniah, alufa, si ka iwe yi li eti Jeremiah woli.
30 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá wipe,