29 Sefaniah, alufa, si ka iwe yi li eti Jeremiah woli.
30 Ọ̀rọ Oluwa si tọ̀ Jeremiah wá wipe,
31 Ranṣẹ si gbogbo awọn igbekun, wipe, Bayi li Oluwa wi niti Ṣemaiah, ara Nehalami, nitoripe Ṣemaiah ti sọtẹlẹ fun nyin, ṣugbọn emi kò ran a, ti on si mu nyin gbẹkẹle eke:
32 Nitorina, bayi li Oluwa wi: Wò o, emi o bẹ Ṣemaiah, ara Nehalami, wò, ati iru-ọmọ rẹ̀; on kì yio ni ọkunrin kan lati ma gbe ãrin enia yi; bẹ̃ni kì yio ri rere na ti emi o ṣe fun awọn enia mi, li Oluwa wi; nitoripe o ti ṣọ̀tẹ si Oluwa.