6 Oluwa si wi fun mi ni igba Josiah ọba, pe, Iwọ ri ohun ti Israeli apẹhinda ti ṣe? o ti gun ori oke giga gbogbo, ati labẹ gbogbo igi tutu, nibẹ li o ti ṣe panṣaga.
7 Emi si wipe, lẹhin ti o ti ṣe gbogbo ohun wọnyi tan, yio yipada si mi, ṣugbọn kò yipada, Juda alarekereke arabinrin rẹ̀ si ri i.
8 Emi si wò pe, nitori gbogbo wọnyi ti Israeli apẹhinda ti ṣe agbere, ti mo kọ̀ ọ silẹ ti emi si fun u ni iwe-ikọsilẹ, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò bẹ̀ru, o si nṣe agbere lọ pẹlu.
9 O si ṣe nitori okìki àgbere rẹ̀ li o fi bà ilẹ jẹ, ti o si ṣe àgbere tọ̀ okuta ati igi lọ.
10 Lẹhin gbogbo wọnyi, sibẹ Juda, alarekereke arabinrin rẹ̀, kò yipada si mi tọkàntọkàn ṣugbọn li agabagebe; li Oluwa wi.
11 Oluwa si wi fun mi pe, Israeli apẹhinda, ti dá ara rẹ̀ li are ju Juda alarekereke lọ.
12 Lọ ki o si kede ọ̀rọ wọnyi ni iha ariwa, ki o si wipe, Yipada iwọ Israeli, apẹhinda, li Oluwa wi, emi kì yio jẹ ki oju mi ki o korò si ọ; nitori emi ni ãnu, li Oluwa wi, emi kì o si pa ibinu mi mọ titi lai.